25 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+
15 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun,+ kí àwọn tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun, torí ẹnì kan ti kú fún wọn, kí wọ́n lè rí ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà+ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lábẹ́ májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀.+