27 Ó mú ife kan, ó dúpẹ́, ó sì gbé e fún wọn, ó ní: “Gbogbo yín, ẹ mu nínú rẹ̀,+28 torí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’ mi,+ tí a máa dà jáde nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn,+ kí wọ́n lè rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+
25 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+
6 Àmọ́ ní báyìí, Jésù ti gba iṣẹ́ òjíṣẹ́* tó lọ́lá jùyẹn lọ torí òun tún ni alárinà+ májẹ̀mú tó dáa jù,+ tó sì bá a mu rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí tó dáa jù.+
15 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun,+ kí àwọn tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun, torí ẹnì kan ti kú fún wọn, kí wọ́n lè rí ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà+ kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wà lábẹ́ májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀.+