35 Tèmi ni ẹ̀san àti ìyà ẹ̀ṣẹ̀,+
Ní àkókò náà tí ẹsẹ̀ wọn máa yọ̀ tẹ̀rẹ́,+
Torí ọjọ́ àjálù wọn sún mọ́lé,
Ohun tó sì ń dúró dè wọ́n máa tètè dé.’
36 Torí Jèhófà máa dá ẹjọ́ àwọn èèyàn+ rẹ̀,
Ó sì máa káàánú àwọn ìránṣẹ́+ rẹ̀,
Tó bá rí i pé okun wọn ti ń tán,
Tó sì rí i pé àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́ àtàwọn tó ti rẹ̀ ló ṣẹ́ kù.