-
1 Àwọn Ọba 17:22-24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+ 23 Èlíjà gbé ọmọ náà, ó gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti yàrá orí òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà wá sọ pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.”+ 24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”
-
-
2 Àwọn Ọba 4:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Nígbà tí Èlíṣà wọnú ilé náà, òkú ọmọ náà wà lórí ibùsùn rẹ̀.+
-
-
2 Àwọn Ọba 4:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Ó gorí ibùsùn, ó nà lé ọmọ náà, ó sì gbé ẹnu rẹ̀ lé ẹnu ọmọ náà àti ojú rẹ̀ lé ojú ọmọ náà, ó tún gbé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ ọmọ náà, ó sì nà lé e lórí síbẹ̀, ara ọmọ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í móoru.+
-