-
Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ pé: “Jẹ́ ká+ dá èèyàn ní àwòrán wa,+ kí wọ́n jọ wá,+ kí wọ́n sì máa jọba lórí àwọn ẹja inú òkun, àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, àwọn ẹran ọ̀sìn, lórí gbogbo ayé àti lórí gbogbo ẹran tó ń rákò tó sì ń rìn lórí ilẹ̀.”+ 27 Ọlọ́run sì dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run; akọ àti abo ló dá wọn.+
-