Sáàmù 37:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́;+ Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,Wọn ò ní sí níbẹ̀.+ Àìsáyà 13:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 Wò ó! Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀,Ọjọ́ tó lágbára pẹ̀lú ìbínú tó le àti ìbínú tó ń jó fòfò,Láti sọ ilẹ̀ náà di ohun àríbẹ̀rù,+Kó sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà run kúrò lórí rẹ̀. Sefanáyà 1:18 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 18 Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú ńlá Jèhófà;+Torí ìtara rẹ̀ tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run,+Nítorí ó máa pa àwọn èèyàn ayé nípakúpa, àní á pa wọ́n yán-án yán-án.”+ Ìfihàn 6:14 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 14 Ọ̀run sì lọ bí àkájọ ìwé tí wọ́n ká,+ a sì mú kí gbogbo òkè àti gbogbo erékùṣù kúrò ní àyè wọn.+
9 Wò ó! Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀,Ọjọ́ tó lágbára pẹ̀lú ìbínú tó le àti ìbínú tó ń jó fòfò,Láti sọ ilẹ̀ náà di ohun àríbẹ̀rù,+Kó sì pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà run kúrò lórí rẹ̀.
18 Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú ńlá Jèhófà;+Torí ìtara rẹ̀ tó ń jó bí iná máa jó gbogbo ayé run,+Nítorí ó máa pa àwọn èèyàn ayé nípakúpa, àní á pa wọ́n yán-án yán-án.”+