25 Ọlọ́run fi í lélẹ̀ láti jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.+ Kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn, torí Ọlọ́run, nínú ìmúmọ́ra* rẹ̀, ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nígbà àtijọ́ jini.
14 ǹjẹ́ ẹ̀jẹ̀ Kristi,+ ẹni tó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ láti wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́,+ ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run alààyè?+
22 ẹ jẹ́ ká fi ọkàn tòótọ́ àti ìgbàgbọ́ tó kún rẹ́rẹ́ wá, nígbà tí a ti wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn burúkú,+ tí a sì ti fi omi tó mọ́ wẹ ara wa.+