3 Ṣebí káfíńtà yẹn nìyí,+ ọmọ Màríà,+ tó tún jẹ́ arákùnrin Jémíìsì,+ Jósẹ́fù, Júdásì àti Símónì,+ àbí òun kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà níbí pẹ̀lú wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọsẹ̀ nítorí rẹ̀.
9 nígbà tí wọ́n rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi,+ Jémíìsì+ àti Kéfà* àti Jòhánù, àwọn tó dà bí òpó nínú ìjọ, bọ èmi àti Bánábà+ lọ́wọ́ láti fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ọn pé* kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwọn sì lọ sọ́dọ̀ àwọn tó dádọ̀dọ́.