-
Ìfihàn 1:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 ẹnì kan tó dà bí ọmọ èèyàn+ wà láàárín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ó wọ aṣọ tó balẹ̀ dé ọrùn ẹsẹ̀, ó de ọ̀já wúrà mọ́ àyà rẹ̀. 14 Yàtọ̀ síyẹn, orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, bíi yìnyín, ojú rẹ̀ sì dà bí ọwọ́ iná tó ń jó fòfò,+ 15 ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó dáa gan-an+ tó ń tàn yòò nínú iná ìléru, ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi tó pọ̀.
-