Míkà
1 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Míkà*+ ará Móréṣétì, nínú ìran tó rí nípa Samáríà àti Jerúsálẹ́mù láyé ìgbà Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ tí wọ́n jẹ́ ọba Júdà:+
2 “Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin èèyàn!
Fetí sílẹ̀, ìwọ ayé àti ohun tó wà nínú rẹ,
Kí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́rìí ta kò yín,+
Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ láti inú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.
3 Wò ó! Jèhófà ń jáde lọ láti àyè rẹ̀;
Ó máa sọ̀ kalẹ̀ wá, á sì tẹ àwọn ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
4 Àwọn òkè yóò yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,+
Àwọn àfonífojì* yóò sì pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,
Bí ìgbà tí iná yọ́ ìda,
Bí omi tó ṣàn wálẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.
Ta ló fa ọ̀tẹ̀ Jékọ́bù?
Ṣebí àwọn ará Samáríà ni?+
Ta ló sì kọ́ àwọn ibi gíga tó wà ní Júdà?+
Ṣebí àwọn ará Jerúsálẹ́mù ni?
6 Màá sọ Samáríà di àwókù ilé inú oko,
Yóò di ibi tí wọ́n ń gbin àjàrà sí;
Màá ju* àwọn òkúta rẹ̀ sínú àfonífojì,
Èmi yóò sì hú àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ síta.
7 Gbogbo ère gbígbẹ́ rẹ̀ máa fọ́ sí wẹ́wẹ́,+
Gbogbo ẹ̀bùn tó sì gbà nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* ni wọ́n máa finá sun.+
Gbogbo òrìṣà rẹ̀ ni màá pa run.
Torí èrè tó rí nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó ló fi kó wọn jọ,
Wọ́n á sì pa dà di èrè fún àwọn aṣẹ́wó.”
Màá pohùn réré ẹkún bí ajáko,*
Èmi yóò sì ṣọ̀fọ̀ bí ògòǹgò.
Egbò náà ti ràn dé ẹnubodè àwọn èèyàn mi, dé Jerúsálẹ́mù.+
10 “Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní Gátì;
Ẹ kò gbọ́dọ̀ sunkún rárá.
Ẹ gbé ara yín yílẹ̀ ní Bẹti-áfírà.*
11 Ẹ sọdá ní ìhòòhò pẹ̀lú ìtìjú, ẹ̀yin* tó ń gbé ní Ṣáfírì.
Àwọn* tó ń gbé ní Sáánánì kò tíì jáde.
Àwọn ará Bẹti-ésélì máa pohùn réré ẹkún, wọn ò sì ní tì yín lẹ́yìn mọ́.
12 Torí, ohun rere ni àwọn* tó ń gbé ní Márótì ń retí,
Àmọ́ Jèhófà ti mú ohun tó burú wá sí ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.
13 Ẹ̀yin* tó ń gbé ní Lákíṣì, ẹ de kẹ̀kẹ́ mọ́ àwọn ẹṣin.+
Ẹ̀yin lẹ mú kí ọmọbìnrin Síónì dẹ́ṣẹ̀,
Ẹ̀yin lẹ sì mú kí Ísírẹ́lì dìtẹ̀.+
14 Torí náà, wàá fún Moreṣeti-gátì ní ẹ̀bùn ìdágbére.
Ẹ̀tàn ni ilé Ákísíbù+ jẹ́ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì.
15 Ẹ̀yin* tó ń gbé ní Máréṣà,+ màá mú ẹni tí yóò ṣẹ́gun* yín wá.+
Ògo Ísírẹ́lì yóò dé Ádúlámù.+
16 Ẹ mú orí yín pá, kí ẹ sì fá irun yín torí àwọn ọmọ yín ọ̀wọ́n.
Ẹ mú orí yín pá bíi ti ẹyẹ idì,
Torí wọ́n ti kó wọn kúrò lọ́dọ̀ yín lọ sí ìgbèkùn.”+