ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóẹ́lì 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì

      • Jèhófà dá gbogbo orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́ (1-17)

        • Àfonífojì Jèhóṣáfátì (2, 12)

        • Àfonífojì ìpinnu (14)

        • Jèhófà jẹ́ odi ààbò Ísírẹ́lì (16)

      • Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ (18-21)

Jóẹ́lì 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:3; Jer 30:3; Isk 39:28; Emọ 9:14; Sef 3:20

Jóẹ́lì 3:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Adájọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 38:22; Joẹ 3:12; Sef 3:8; Sek 14:3; Ifi 16:14, 16
  • +Isk 35:10, 11; Sef 2:8, 9

Jóẹ́lì 3:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ọbd 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 22

Jóẹ́lì 3:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 23:12; Jer 47:4; Isk 25:15-17; Emọ 1:9, 10; Sek 9:1, 2

Jóẹ́lì 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 21:16, 17

Jóẹ́lì 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:32; Isk 27:8, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1700

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 22

Jóẹ́lì 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 11:11, 12; 43:5, 6; 49:12; Jer 23:7, 8; Isk 34:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 22

Jóẹ́lì 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ọbd 19, 20

Jóẹ́lì 3:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ sọ ogun di mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:1, 2
  • +Isk 38:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 168-169

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 22-23

    5/1/1992, ojú ìwé 8-9

Jóẹ́lì 3:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣóró.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 168-169

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 22-23

    5/1/1992, ojú ìwé 9

Jóẹ́lì 3:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn alágbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 38:9; Sef 3:8; Ifi 16:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 23-25

Jóẹ́lì 3:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 76:8, 9; Joẹ 3:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 19-25

Jóẹ́lì 3:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 63:3; Ifi 14:18-20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 283-284

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1992, ojú ìwé 9

Jóẹ́lì 3:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:2; Sef 1:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 13

    5/1/1998, ojú ìwé 19, 24-25

    5/1/1992, ojú ìwé 8-9

Jóẹ́lì 3:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 31-32

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1992, ojú ìwé 10-11

Jóẹ́lì 3:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba,

    7/2013, ojú ìwé 1

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 108, 156

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 25

    5/1/1992, ojú ìwé 10-11

Jóẹ́lì 3:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àlejò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 8:3
  • +Ais 4:3
  • +Ais 60:18; Na 1:15; Sek 14:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 25

Jóẹ́lì 3:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 9:13; Sek 9:17
  • +Isk 47:1; Ifi 22:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 203-204

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 19

    5/1/1998, ojú ìwé 25

Jóẹ́lì 3:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 19:1
  • +Jer 49:17
  • +Isk 25:12, 13
  • +Emọ 1:11; Ọbd 10

Jóẹ́lì 3:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 48:8; Ais 33:20; 60:15; Emọ 9:15

Jóẹ́lì 3:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 4:4; Isk 36:25; Mik 7:18, 19
  • +Ais 24:23; Mik 4:7

Àwọn míì

Jóẹ́lì 3:1Di 30:3; Jer 30:3; Isk 39:28; Emọ 9:14; Sef 3:20
Jóẹ́lì 3:2Isk 38:22; Joẹ 3:12; Sef 3:8; Sek 14:3; Ifi 16:14, 16
Jóẹ́lì 3:2Isk 35:10, 11; Sef 2:8, 9
Jóẹ́lì 3:3Ọbd 11
Jóẹ́lì 3:4Ais 23:12; Jer 47:4; Isk 25:15-17; Emọ 1:9, 10; Sek 9:1, 2
Jóẹ́lì 3:52Kr 21:16, 17
Jóẹ́lì 3:6Di 28:32; Isk 27:8, 13
Jóẹ́lì 3:7Ais 11:11, 12; 43:5, 6; 49:12; Jer 23:7, 8; Isk 34:12
Jóẹ́lì 3:8Ọbd 19, 20
Jóẹ́lì 3:9Ais 34:1, 2
Jóẹ́lì 3:9Isk 38:7
Jóẹ́lì 3:11Isk 38:9; Sef 3:8; Ifi 16:14
Jóẹ́lì 3:12Sm 76:8, 9; Joẹ 3:2
Jóẹ́lì 3:13Ais 63:3; Ifi 14:18-20
Jóẹ́lì 3:14Ais 34:2; Sef 1:14
Jóẹ́lì 3:16Sm 50:15
Jóẹ́lì 3:17Sek 8:3
Jóẹ́lì 3:17Ais 4:3
Jóẹ́lì 3:17Ais 60:18; Na 1:15; Sek 14:21
Jóẹ́lì 3:18Emọ 9:13; Sek 9:17
Jóẹ́lì 3:18Isk 47:1; Ifi 22:1
Jóẹ́lì 3:19Ais 19:1
Jóẹ́lì 3:19Jer 49:17
Jóẹ́lì 3:19Isk 25:12, 13
Jóẹ́lì 3:19Emọ 1:11; Ọbd 10
Jóẹ́lì 3:20Sm 48:8; Ais 33:20; 60:15; Emọ 9:15
Jóẹ́lì 3:21Ais 4:4; Isk 36:25; Mik 7:18, 19
Jóẹ́lì 3:21Ais 24:23; Mik 4:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóẹ́lì 3:1-21

Jóẹ́lì

3 “Wò ó! ní àwọn ọjọ́ náà àti ní àkókò yẹn,

Nígbà tí mo bá dá àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú láti Júdà àti Jerúsálẹ́mù pa dà,+

 2 Èmi yóò tún kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ,

Èmi yóò sì mú wọn sọ̀ kalẹ̀ wá sí Àfonífojì* Jèhóṣáfátì.*

Èmi yóò dá wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀+

Nítorí àwọn èèyàn mi àti torí Ísírẹ́lì ogún mi,

Wọ́n ti tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

Wọ́n sì ti pín ilẹ̀ mi láàárín ara wọn.+

 3 Wọ́n ń ṣẹ́ kèké torí àwọn èèyàn mi;+

Wọ́n ń fi ọmọ wọn ọkùnrin dúró kí wọ́n lè gbé aṣẹ́wó,

Wọ́n sì ń ta àwọn ọmọ wọn obìnrin torí àtimu wáìnì.

 4 Kí ló dé tí ẹ fi ṣe báyìí sí mi,

Tírè, Sídónì àti gbogbo ilẹ̀ Filísíà?

Ṣé mo ṣẹ̀ yín ni tí ẹ fi ń gbẹ̀san?

Tó bá jẹ́ ẹ̀san lẹ̀ ń gbà,

Ṣe ni màá yára dá a pa dà sórí yín láìjáfara.+

 5 Torí ẹ ti kó fàdákà àti wúrà mi,+

Ẹ sì ti kó àwọn ìṣúra mi tó ṣeyebíye gan-an lọ sínú àwọn tẹ́ńpìlì yín;

 6 Ẹ ti ta àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù fún àwọn Gíríìkì,+

Kí ẹ lè lé wọn jìnnà kúrò ní ilẹ̀ wọn;

 7 Màá mú kí wọ́n pa dà láti ibi tí ẹ tà wọ́n sí,+

Màá sì dá ohun tí ẹ ṣe pa dà sórí yín.

 8 Èmi yóò ta àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin fún àwọn ará Júdà,+

Wọn yóò sì tà wọ́n fún àwọn ará Ṣébà, orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré;

Jèhófà fúnra rẹ̀ ti sọ ọ́.

 9 Ẹ kéde láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé:+

‘Ẹ múra ogun!* Ẹ ta àwọn alágbára ọkùnrin jí!

Kí gbogbo ọmọ ogun sún mọ́ tòsí, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ogun!+

10 Ẹ fi àwọn ohun ìtúlẹ̀ yín rọ idà, kí ẹ sì fi àwọn ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn yín rọ ọ̀kọ̀.*

Kí ẹni tí kò lágbára sọ pé: “Alágbára ni mí.”

11 Ẹ wá ṣèrànwọ́, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tó wà yí ká, kí ẹ sì kóra jọ!’”+

Jèhófà, jọ̀ọ́ mú àwọn jagunjagun* rẹ wá síbẹ̀.

12 “Kí àwọn orílẹ̀-èdè dìde, kí wọ́n sì wá sí Àfonífojì* Jèhóṣáfátì;

Torí ibẹ̀ ni èmi yóò jókòó sí láti dá gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà yí ká lẹ́jọ́.+

13 Ẹ ti dòjé bọ̀ ọ́, torí àkókò ìkórè ti tó.

Ẹ sọ̀ kalẹ̀ wá tẹ èso àjàrà, torí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì ti kún.+

Àwọn ẹkù ti kún àkúnwọ́sílẹ̀, torí ìwà búburú kún ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.

14 Èrò, èrò rẹpẹtẹ wà ní àfonífojì* ìpinnu,

Torí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé ní àfonífojì* ìpinnu.+

15 Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,

Àwọn ìràwọ̀ kò sì ní mọ́lẹ̀.

16 Jèhófà yóò sì fi ohùn rara sọ̀rọ̀ láti Síónì,

Yóò gbé ohùn rẹ̀ sókè láti Jerúsálẹ́mù.

Ọ̀run àti ayé yóò sì mì jìgìjìgì;

Àmọ́ Jèhófà yóò jẹ́ ibi ààbò fún àwọn èèyàn rẹ̀,+

Odi ààbò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

17 Ẹ ó sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tó ń gbé ní Síónì, òkè mímọ́ mi.+

Jerúsálẹ́mù yóò di ibi mímọ́,+

Àwọn àjèjì* kò sì ní gbà á kọjá mọ́.+

18 Wáìnì dídùn yóò máa sẹ̀ láti orí àwọn òkè ní ọjọ́ yẹn,+

Wàrà yóò máa ṣàn lórí àwọn òkè kéékèèké,

Gbogbo omi odò Júdà yóò sì máa ṣàn.

Omi yóò sun láti ilé Jèhófà,+

Yóò sì bomi rin Àfonífojì Àwọn Igi Bọn-ọ̀n-ní.

19 Àmọ́ Íjíbítì yóò di ahoro,+

Édómù yóò sì di aginjù tó dá páropáro,+

Torí bí wọ́n ṣe hùwà ipá sí àwọn ará Júdà,+

Ilẹ̀ àwọn tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+

20 Àmọ́ àwọn èèyàn á máa gbé ní Júdà nígbà gbogbo,

Àti ní Jerúsálẹ́mù láti ìran dé ìran.+

21 Èmi yóò mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó ti wà lọ́rùn wọn kúrò;+

Jèhófà yóò sì máa gbé ní Síónì.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́