ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóẹ́lì 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóẹ́lì

      • Àwọn kòkòrò ṣọṣẹ́ gan-an (1-14)

      • “Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé” (15-20)

        • Wòlíì náà ké pe Jèhófà (19, 20)

Jóẹ́lì 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 12

Jóẹ́lì 1:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 8

Jóẹ́lì 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 8

    5/1/1992, ojú ìwé 11-12

Jóẹ́lì 1:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 10:14, 15
  • +Joẹ 2:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 2-3

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 8-9

    5/1/1992, ojú ìwé 11-12

Jóẹ́lì 1:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 28:1; Emọ 6:6
  • +Di 28:39

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 9

    5/1/1992, ojú ìwé 12

Jóẹ́lì 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:2
  • +Ifi 9:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2020, ojú ìwé 2-3

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 9-10

Jóẹ́lì 1:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọbìnrin.”

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

  • *

    Tàbí “ọkọ.”

  • *

    Ní Héb., “ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.”

Jóẹ́lì 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:1
  • +Ẹk 29:40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:20
  • +Di 28:39, 40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ di ara yín lámùrè.”

  • *

    Tàbí “lu igẹ̀ yín.”

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:19, 20
  • +Le 2:1
  • +Ẹk 29:40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ sọ ààwẹ̀ di mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:15
  • +2Kr 20:3, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 10

Jóẹ́lì 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:1; Sef 1:7, 14; 2:2; 2Pe 3:10; Ifi 6:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 11

Jóẹ́lì 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ.”

Jóẹ́lì 1:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 7:7; Hab 3:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1998, ojú ìwé 11

Àwọn míì

Jóẹ́lì 1:2Joẹ 2:2
Jóẹ́lì 1:4Ẹk 10:14, 15
Jóẹ́lì 1:4Joẹ 2:25
Jóẹ́lì 1:5Ais 28:1; Emọ 6:6
Jóẹ́lì 1:5Di 28:39
Jóẹ́lì 1:6Joẹ 2:2
Jóẹ́lì 1:6Ifi 9:7, 8
Jóẹ́lì 1:9Le 2:1
Jóẹ́lì 1:9Ẹk 29:40
Jóẹ́lì 1:10Di 28:39, 40
Jóẹ́lì 1:10Le 26:20
Jóẹ́lì 1:12Le 26:20
Jóẹ́lì 1:13Ẹk 30:19, 20
Jóẹ́lì 1:13Le 2:1
Jóẹ́lì 1:13Ẹk 29:40
Jóẹ́lì 1:14Joẹ 2:15
Jóẹ́lì 1:142Kr 20:3, 13
Jóẹ́lì 1:15Joẹ 2:1; Sef 1:7, 14; 2:2; 2Pe 3:10; Ifi 6:16, 17
Jóẹ́lì 1:19Mik 7:7; Hab 3:18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóẹ́lì 1:1-20

Jóẹ́lì

1 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jóẹ́lì* ọmọ Pétúélì sọ nìyí:

 2 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin àgbààgbà,

Kí ẹ sì fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ilẹ̀ náà.*

Ǹjẹ́ irú nǹkan báyìí ti ṣẹlẹ̀ rí níṣojú yín,

Tàbí nígbà ayé àwọn baba ńlá yín?+

 3 Ẹ sọ nípa rẹ̀ fún àwọn ọmọ yín,

Kí àwọn ọmọ yín náà sọ fún àwọn ọmọ wọn,

Kí àwọn ọmọ wọn sì sọ fún ìran tó tẹ̀ lé wọn.

 4 Ohun tí eéṣú tó ń jẹ nǹkan run jẹ kù, ni ọ̀wọ́ eéṣú jẹ;+

Ohun tí ọ̀wọ́ eéṣú jẹ kù, ni eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ;

Ohun tí eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́ jẹ kù, ni ọ̀yánnú eéṣú jẹ.+

 5 Ẹ jí, ẹ̀yin ọ̀mùtípara,+ kí ẹ sì sunkún!

Ẹ pohùn réré ẹkún, gbogbo ẹ̀yin tó ń mu wáìnì,

Torí wọ́n ti gba wáìnì dídùn lẹ́nu yín.+

 6 Torí orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi, ó lágbára gan-an, kò sì lóǹkà.+

Eyín kìnnìún ni eyín rẹ̀,+ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ náà sì jẹ́ ti kìnnìún.

 7 Ó ti pa àjàrà mi run, ó sì sọ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi di kùkùté,

Ó bó èèpo wọn kanlẹ̀, ó sì jù wọ́n dà nù,

Ẹ̀ka àwọn igi náà sì di funfun.

 8 Pohùn réré ẹkún bíi ti wúńdíá* tó wọ aṣọ ọ̀fọ̀*

Torí olólùfẹ́* rẹ̀ tó kú.*

 9 Kò sí ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu+ ní ilé Jèhófà mọ́;

Àwọn àlùfáà, àwọn òjíṣẹ́ Jèhófà, ń ṣọ̀fọ̀.

10 Wọ́n ti pa oko run, ilẹ̀ sì ń ṣọ̀fọ̀;+

Wọ́n ti run ọkà, wáìnì tuntun ti gbẹ táútáú, òróró sì ti tán.+

11 Inú àwọn àgbẹ̀ bà jẹ́, àwọn tó ń rẹ́wọ́ àjàrà pohùn réré ẹkún,

Torí àlìkámà* àti ọkà bálì;

Ìkórè oko sì ti pa run.

12 Àjàrà ti gbẹ,

Igi ọ̀pọ̀tọ́ sì ti kú.

Bẹ́ẹ̀ náà ni igi pómégíránétì, igi ọ̀pẹ àti igi ápù,

Gbogbo igi oko ti gbẹ dà nù;+

Ìdùnnú àwọn èèyàn ti di ìtìjú.

13 Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀,* ẹ̀yin àlùfáà, kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀;*

Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ níwájú pẹpẹ.+

Ẹ wọlé, kí ẹ sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́jú, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi;

Torí àwọn èèyàn ò mú ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu+ wá sílé Ọlọ́run yín.

14 Ẹ kéde* ààwẹ̀; ẹ pe àpéjọ ọlọ́wọ̀.+

Ẹ kó àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jọ,

Sí ilé Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ sì ké pe Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́.

15 Ó mà ṣe o! Torí ọjọ́ náà,

Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé,+

Ó sì máa jẹ́ ọjọ́ ìparun látọ̀dọ̀ Olódùmarè!

16 Wọ́n ti gbé oúnjẹ kúrò níwájú wa,

Kò sì sí ayọ̀ àti ìdùnnú nílé Ọlọ́run wa mọ́.

17 Àwọn èso* ti bà jẹ́ kí wọ́n tó fi ṣọ́bìrì kó o.

Àwọn ilé ìkẹ́rùsí ti di ahoro.

Wọ́n ti ya àwọn ibi tí wọ́n ń tọ́jú ọkà sí lulẹ̀, torí ọkà ti gbẹ dà nù.

18 Kódà, àwọn ẹran ọ̀sìn ń kérora!

Ìdààmú bá àwọn agbo màlúù, wọ́n sì ń rìn gbéregbère torí wọn ò rí ewéko jẹ.

Àwọn agbo àgùntàn sì jẹ nínú ìyà náà.

19 Jèhófà, ìwọ ni màá ké pè;+

Torí iná ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù,

Ọwọ́ iná sì ti jẹ gbogbo igi oko run.

20 Kódà, àwọn ẹran inú igbó ń wá ọ,

Torí àwọn odò tó ń ṣàn ti gbẹ,

Iná sì ti run àwọn ibi ìjẹko nínú aginjù.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́