ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóẹ́lì 2:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 “Ẹ fun ìwo ní Síónì!+

      Ẹ kéde ogun ní òkè mímọ́ mi.

      Kí jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,*

      Torí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀!+ Ó sún mọ́lé!

  • Sefanáyà 1:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+

      Jèhófà ti pèsè ẹbọ sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn tí ó pè sí mímọ́.

  • Sefanáyà 1:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé!+

      Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!*+

      Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+

      Akíkanjú ológun máa figbe ta níbẹ̀.+

  • Sefanáyà 2:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  2 Kí àṣẹ náà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́,

      Kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò,*

      Kí ìbínú tó ń jó fòfò látọ̀dọ̀ Jèhófà tó wá sórí yín,+

      Kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó dé bá yín,

  • 2 Pétérù 3:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àmọ́ ọjọ́ Jèhófà*+ máa dé bí olè,+ nígbà yẹn àwọn ọ̀run máa kọjá lọ+ pẹ̀lú ariwo tó rinlẹ̀,* àmọ́ àwọn ohun ìpìlẹ̀ tó gbóná janjan máa yọ́, a sì máa tú ayé àti àwọn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ síta.+

  • Ìfihàn 6:16, 17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Wọ́n sì ń sọ fún àwọn àpáta àti àwọn òkè náà pé: “Ẹ wó lù wá,+ kí ẹ sì fi wá pa mọ́ kúrò lójú Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́+ àti kúrò lọ́wọ́ ìbínú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,+ 17 torí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn ti dé,+ ta ló sì lè dúró?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́