ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ìtàn nípa bí Ísírẹ́lì ṣe ṣọ̀tẹ̀ (1-32)

      • Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò dá Ísírẹ́lì pa dà sórí ilẹ̀ wọn (33-44)

      • Sọ tẹ́lẹ̀ nípa gúúsù (45-49)

Ìsíkíẹ́lì 20:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:12, 15; Isk 14:3

Ìsíkíẹ́lì 20:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti kéde ìdájọ́ lé wọn lórí?”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:51; 22:2; Lk 11:47

Ìsíkíẹ́lì 20:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbé ọwọ́ mi sókè.”

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:6
  • +Ẹk 4:31; 6:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 24

Ìsíkíẹ́lì 20:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣe amí rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 24

Ìsíkíẹ́lì 20:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:3; Di 29:16, 17; Joṣ 24:14
  • +Le 20:7

Ìsíkíẹ́lì 20:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:4

Ìsíkíẹ́lì 20:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Ísírẹ́lì.

  • *

    Ìyẹn, Ísírẹ́lì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:13-16; Di 9:27, 28; 1Sa 12:22
  • +Ẹk 32:11, 12; Joṣ 2:9, 10; 9:3, 9; 1Sa 4:7, 8

Ìsíkíẹ́lì 20:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:17, 18; 15:22

Ìsíkíẹ́lì 20:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:8
  • +Di 8:3; 30:16

Ìsíkíẹ́lì 20:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:8-10; Le 23:3, 24; 25:4, 11
  • +Ẹk 31:13; 35:2

Ìsíkíẹ́lì 20:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:8; Nọ 14:22, 23
  • +Nọ 14:11, 12

Ìsíkíẹ́lì 20:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Ísírẹ́lì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 7:9; Isk 36:22

Ìsíkíẹ́lì 20:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ní ọ̀ṣọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:30; Sm 95:11; 106:26, 27
  • +Nọ 13:26, 27

Ìsíkíẹ́lì 20:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:1, 4; Nọ 25:1, 2; Iṣe 7:42

Ìsíkíẹ́lì 20:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ojú mi.”

Ìsíkíẹ́lì 20:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:33
  • +Sm 78:8

Ìsíkíẹ́lì 20:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:1

Ìsíkíẹ́lì 20:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 17:22
  • +Ẹk 31:13

Ìsíkíẹ́lì 20:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:1; Di 9:23
  • +Ais 63:10

Ìsíkíẹ́lì 20:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Ísírẹ́lì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:38
  • +Sm 25:11; 79:9; Jer 14:7; Da 9:19

Ìsíkíẹ́lì 20:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:33; Sm 106:26, 27

Ìsíkíẹ́lì 20:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ojú wọn ò kúrò lára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:15, 16
  • +Jer 2:7

Ìsíkíẹ́lì 20:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 81:12

Ìsíkíẹ́lì 20:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:21; Jer 7:31

Ìsíkíẹ́lì 20:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 23:5
  • +Di 12:2

Ìsíkíẹ́lì 20:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:24, 25

Ìsíkíẹ́lì 20:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:19; 2Kr 21:13; Jer 13:26, 27

Ìsíkíẹ́lì 20:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 18:10, 12; Sm 106:36-38; Jer 7:31
  • +Ais 1:15
  • +Sek 7:13

Ìsíkíẹ́lì 20:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ní ẹ̀mí.”

  • *

    Tàbí “ṣe ìránṣẹ́ fún; sin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 44:17

Ìsíkíẹ́lì 20:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:5; Isk 8:18

Ìsíkíẹ́lì 20:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 27:13; Isk 34:16

Ìsíkíẹ́lì 20:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:9

Ìsíkíẹ́lì 20:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọnú ìdè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 27:32; Isk 34:17

Ìsíkíẹ́lì 20:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 34:20, 21
  • +Isk 13:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 107

Ìsíkíẹ́lì 20:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 10:14; Sm 81:12
  • +Ais 1:13; Isk 23:39

Ìsíkíẹ́lì 20:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 2:2, 3; 66:20
  • +Ais 56:7; Sek 8:22
  • +Mal 3:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 101, 106-107

Ìsíkíẹ́lì 20:41

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 11:11; Jer 23:3
  • +Ais 5:16; Isk 38:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 107-109

Ìsíkíẹ́lì 20:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 36:23
  • +Isk 11:17

Ìsíkíẹ́lì 20:43

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ojú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:40; Isk 6:9; 16:61
  • +Jer 31:18

Ìsíkíẹ́lì 20:44

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 79:9; Isk 36:22, 23

Ìsíkíẹ́lì 20:47

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:22; Jer 21:14
  • +Ais 66:24

Ìsíkíẹ́lì 20:48

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èèyàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 7:20; Ida 2:17

Ìsíkíẹ́lì 20:49

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òwe.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2007, ojú ìwé 14

Àwọn míì

Ìsík. 20:3Ais 1:12, 15; Isk 14:3
Ìsík. 20:4Isk 16:51; 22:2; Lk 11:47
Ìsík. 20:5Di 7:6
Ìsík. 20:5Ẹk 4:31; 6:7, 8
Ìsík. 20:6Ẹk 3:8
Ìsík. 20:7Le 18:3; Di 29:16, 17; Joṣ 24:14
Ìsík. 20:7Le 20:7
Ìsík. 20:8Ẹk 32:4
Ìsík. 20:9Nọ 14:13-16; Di 9:27, 28; 1Sa 12:22
Ìsík. 20:9Ẹk 32:11, 12; Joṣ 2:9, 10; 9:3, 9; 1Sa 4:7, 8
Ìsík. 20:10Ẹk 13:17, 18; 15:22
Ìsík. 20:11Di 4:8
Ìsík. 20:11Di 8:3; 30:16
Ìsík. 20:12Ẹk 20:8-10; Le 23:3, 24; 25:4, 11
Ìsík. 20:12Ẹk 31:13; 35:2
Ìsík. 20:13Ẹk 32:8; Nọ 14:22, 23
Ìsík. 20:13Nọ 14:11, 12
Ìsík. 20:14Joṣ 7:9; Isk 36:22
Ìsík. 20:15Nọ 14:30; Sm 95:11; 106:26, 27
Ìsík. 20:15Nọ 13:26, 27
Ìsík. 20:16Ẹk 32:1, 4; Nọ 25:1, 2; Iṣe 7:42
Ìsík. 20:18Nọ 14:33
Ìsík. 20:18Sm 78:8
Ìsík. 20:19Di 4:1
Ìsík. 20:20Jer 17:22
Ìsík. 20:20Ẹk 31:13
Ìsík. 20:21Nọ 25:1; Di 9:23
Ìsík. 20:21Ais 63:10
Ìsík. 20:22Sm 78:38
Ìsík. 20:22Sm 25:11; 79:9; Jer 14:7; Da 9:19
Ìsík. 20:23Le 26:33; Sm 106:26, 27
Ìsík. 20:24Le 26:15, 16
Ìsík. 20:24Jer 2:7
Ìsík. 20:25Sm 81:12
Ìsík. 20:26Le 18:21; Jer 7:31
Ìsík. 20:28Joṣ 23:5
Ìsík. 20:28Di 12:2
Ìsík. 20:29Isk 16:24, 25
Ìsík. 20:30Ond 2:19; 2Kr 21:13; Jer 13:26, 27
Ìsík. 20:31Di 18:10, 12; Sm 106:36-38; Jer 7:31
Ìsík. 20:31Ais 1:15
Ìsík. 20:31Sek 7:13
Ìsík. 20:32Jer 44:17
Ìsík. 20:33Jer 21:5; Isk 8:18
Ìsík. 20:34Ais 27:13; Isk 34:16
Ìsík. 20:35Jer 2:9
Ìsík. 20:37Le 27:32; Isk 34:17
Ìsík. 20:38Isk 34:20, 21
Ìsík. 20:38Isk 13:9
Ìsík. 20:39Ond 10:14; Sm 81:12
Ìsík. 20:39Ais 1:13; Isk 23:39
Ìsík. 20:40Ais 2:2, 3; 66:20
Ìsík. 20:40Ais 56:7; Sek 8:22
Ìsík. 20:40Mal 3:4
Ìsík. 20:41Ais 11:11; Jer 23:3
Ìsík. 20:41Ais 5:16; Isk 38:23
Ìsík. 20:42Isk 36:23
Ìsík. 20:42Isk 11:17
Ìsík. 20:43Le 26:40; Isk 6:9; 16:61
Ìsík. 20:43Jer 31:18
Ìsík. 20:44Sm 79:9; Isk 36:22, 23
Ìsík. 20:47Di 32:22; Jer 21:14
Ìsík. 20:47Ais 66:24
Ìsík. 20:482Kr 7:20; Ida 2:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 20:1-49

Ìsíkíẹ́lì

20 Ní ọdún keje, ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, àwọn kan lára àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì jókòó síwájú mi kí wọ́n lè wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà. 2 Jèhófà bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Ọmọ èèyàn, bá àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ọ̀dọ̀ mi lẹ ti fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀ ni? ‘Bí mo ti wà láàyè, mi ò ní dá yín lóhùn,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”’

4 “Ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́?* Ọmọ èèyàn, ṣé o ṣe tán láti dá wọn lẹ́jọ́? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun ìríra tí àwọn baba ńlá wọn ṣe.+ 5 Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ní ọjọ́ tí mo yan Ísírẹ́lì,+ mo tún búra* fún ọmọ* ilé Jékọ́bù, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ mí ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Àní, mo búra fún wọn, mo sì sọ pé, ‘Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’ 6 Ní ọjọ́ yẹn, mo búra fún wọn pé màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ tí mo ṣàwárí* fún wọn, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà. 7 Mo wá sọ fún wọn pé, ‘Kí kálukú yín ju ohun ìríra tó wà níwájú rẹ̀ nù; ẹ má fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* Íjíbítì sọ ara yín di ẹlẹ́gbin.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+

8 “‘“Àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, kò sì wù wọ́n láti fetí sí mi. Wọn ò ju ohun ìríra tó wà níwájú wọn nù, wọn ò sì fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin Íjíbítì sílẹ̀.+ Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní ilẹ̀ Íjíbítì. 9 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè, láàárín àwọn tí wọ́n ń gbé.+ Torí nígbà tí mo mú wọn* kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo jẹ́ kí wọ́n* mọ̀ mí níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí.+ 10 Torí náà, mo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mo sì mú wọn wá sí aginjù.+

11 “‘“Mo wá fún wọn ní àwọn àṣẹ mi, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìdájọ́ mi,+ èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè.+ 12 Mo tún fún wọn ní àwọn sábáàtì mi,+ kó lè jẹ́ àmì láàárín èmi àti àwọn,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń sọ wọ́n di mímọ́.

13 “‘“Àmọ́, ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí mi ní aginjù.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì kọ àwọn ìdájọ́ mi, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ pátápátá. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn nínú aginjù kí n lè pa wọ́n run.+ 14 Àmọ́, mo gbé ìgbésẹ̀ torí orúkọ mi, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde.+ 15 Mo tún búra fún wọn nínú aginjù pé mi ò ní mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo fún wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn,+ ibi tó rẹwà* jù ní gbogbo ilẹ̀ náà, 16 torí pé wọ́n kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, wọ́n sì sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́ torí ọkàn wọn ń fà sí àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+

17 “‘“Àmọ́ mo* ṣàánú wọn, mi ò sì pa wọ́n run; mi ò pa wọ́n rẹ́ ní aginjù. 18 Mo sọ fún àwọn ọmọ wọn nínú aginjù pé,+ ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa ìlànà àwọn baba ńlá yín mọ́,+ ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìdájọ́ wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn sọ ara yín di ẹlẹ́gbin. 19 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, kí ẹ rìn nínú àwọn ìdájọ́ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́.+ 20 Ẹ sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́,+ kó sì jẹ́ àmì láàárín èmi àti ẹ̀yin, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’+

21 “‘“Àmọ́ àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí mi.+ Wọn ò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi mọ́, wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì rìn nínú rẹ̀, èyí tó lè mú kí ẹni tó bá ń pa wọ́n mọ́ wà láàyè. Wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́. Torí náà, mo pinnu pé màá bínú sí wọn, inú mi á sì ru sí wọn gidigidi ní aginjù.+ 22 Àmọ́ mi ò ṣe bẹ́ẹ̀,+ mo sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí orúkọ mi,+ kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá a lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó rí i nígbà tí mo mú wọn* jáde. 23 Bákan náà, mo búra fún wọn nínú aginjù pé màá fọ́n wọn ká sí àwọn orílẹ̀-èdè, màá sì tú wọn ká sí àwọn ilẹ̀,+ 24 torí wọn ò pa àwọn ìdájọ́ mi mọ́, wọ́n sì kọ àwọn àṣẹ mi sílẹ̀,+ wọ́n sọ àwọn sábáàtì mi di aláìmọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé* àwọn òrìṣà ẹ̀gbin tí àwọn baba ńlá wọn ń sìn.+ 25 Mo tún gbà wọ́n láyè láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí kò dáa àti àwọn ìdájọ́ tí kò lè mú kí wọ́n wà láàyè.+ 26 Mo jẹ́ kí àwọn ẹbọ tí wọ́n ń rú sọ wọ́n di aláìmọ́, bí wọ́n ṣe ń sun àwọn àkọ́bí ọmọ wọn nínú iná,+ kí n lè sọ wọ́n di ahoro, kí wọ́n lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”’

27 “Torí náà, ọmọ èèyàn, bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí àwọn baba ńlá yín ṣe sọ̀rọ̀ òdì sí mi nìyẹn tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi. 28 Mo mú wọn wá sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún wọn.+ Nígbà tí wọ́n rí gbogbo òkè tó ga àti àwọn igi tí ewé kún orí rẹ̀,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rú àwọn ẹbọ wọn, wọ́n sì ń mú àwọn ọrẹ wọn tó ń múnú bí mi lọ síbẹ̀. Wọ́n ń gbé àwọn ẹbọ wọn tó ní òórùn dídùn* lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń da àwọn ọrẹ ohun mímu wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 29 Mo wá bi wọ́n pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ibi gíga tí ẹ̀ ń lọ yìí? (Wọ́n ṣì ń pè é ní Ibi Gíga títí dòní.)’”’+

30 “Kí o wá sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ṣé ẹ fẹ́ sọ ara yín di ẹlẹ́gbin bíi ti àwọn baba ńlá yín ni, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kí wọ́n lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn?+ 31 Ṣé ẹ ṣì ń sọ ara yín di ẹlẹ́gbin títí dòní olónìí, tí ẹ̀ ń rúbọ sí gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín, tí ẹ̀ ń sun àwọn ọmọ yín nínú iná?+ Ṣé ó wá yẹ kí n dá yín lóhùn pẹ̀lú gbogbo ohun tí ẹ ṣe yìí, ilé Ísírẹ́lì?”’+

“‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘mi ò ní dá yín lóhùn.+ 32 Ohun tí ẹ sì ní lọ́kàn* nígbà tí ẹ̀ ń sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí àwọn ìdílé tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ míì, tí wọ́n ń jọ́sìn* igi àti òkúta,”+ kò ní ṣẹlẹ̀ láé.’”

33 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú ni màá fi ṣàkóso yín.+ 34 Èmi yóò mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, màá sì fi ọwọ́ agbára, apá tí mo nà jáde àti ìbínú kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ ti fọ́n ká sí.+ 35 Èmi yóò mú yín wá sínú aginjù àwọn èèyàn, màá sì dá yín lẹ́jọ́ níbẹ̀ ní ojúkojú.+

36 “‘Bí mo ṣe dá àwọn baba ńlá yín lẹ́jọ́ nínú aginjù ilẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe dá yín lẹ́jọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 37 ‘Màá mú kí ẹ kọjá lábẹ́ ọ̀pá olùṣọ́ àgùntàn,+ màá sì mú kí ẹ tẹ̀ lé* májẹ̀mú náà. 38 Àmọ́ èmi yóò mú àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn tó ń ṣẹ̀ mí kúrò láàárín yín.+ Màá mú wọn kúrò ní ilẹ̀ àjèjì tí wọ́n wà, àmọ́ wọn ò ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’

39 “Ní tìrẹ, ìwọ ilé Ísírẹ́lì, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Kí kálukú yín lọ sin àwọn òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀.+ Àmọ́, tí ẹ kò bá fetí sí mi lẹ́yìn náà, ẹ ò ní lè fi àwọn ẹbọ yín àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi mọ́.’+

40 “‘Torí ní òkè mímọ́ mi, ní òkè gíga Ísírẹ́lì,+ ni gbogbo ilé Ísírẹ́lì yóò ti sìn mí ní ilẹ̀ náà, gbogbo wọn pátá,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.+ ‘Inú mi yóò dùn sí wọn níbẹ̀, èmi yóò sì béèrè ọrẹ yín àti àwọn àkọ́so ẹ̀bùn yín, gbogbo ohun mímọ́ yín.+ 41 Òórùn dídùn* náà yóò mú kí inú mi dùn sí yín, nígbà tí mo bá mú yín jáde láàárín àwọn èèyàn, tí mo sì kó yín jọ láti àwọn ilẹ̀ tí ẹ fọ́n ká sí;+ màá sì fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín níṣojú àwọn orílẹ̀-èdè.’+

42 “‘Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,+ nígbà tí mo bá mú yín wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ sí ilẹ̀ tí mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín. 43 Ibẹ̀ ni ẹ ó sì ti rántí gbogbo ìwà àti ìṣe yín tí ẹ fi sọ ara yín di aláìmọ́,+ ẹ ó sì kórìíra ara* yín nítorí gbogbo ohun búburú tí ẹ ṣe.+ 44 Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà nígbà tí mo bá dojú ìjà kọ yín nítorí orúkọ mi,+ kì í ṣe nítorí ìwà búburú yín tàbí ìwà ìbàjẹ́ yín, ìwọ ilé Ísírẹ́lì,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

45 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 46 “Ọmọ èèyàn, yíjú sí gúúsù, kí o kéde ọ̀rọ̀ fún gúúsù, kí o sì sọ tẹ́lẹ̀ fún igbó tó wà ní oko gúúsù. 47 Sọ fún igbó tó wà ní gúúsù pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò dáná sun ọ́,+ yóò sì jó gbogbo igi tútù àti gbogbo igi gbígbẹ inú rẹ run. Iná tó ń jó náà kò ní kú,+ yóò sì jó gbogbo ojú láti gúúsù dé àríwá. 48 Gbogbo ẹlẹ́ran ara* yóò wá rí i pé èmi Jèhófà, ló dáná sun ún, iná náà kò sì ní kú.”’”+

49 Mo sì sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí wọ́n ń sọ nípa mi ni pé, ‘Ṣebí àlọ́* lásán ló ń pa?’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́