-
Ẹ́kísódù 20:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “Máa rántí ọjọ́ Sábáàtì, kí o lè yà á sí mímọ́.+ 9 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi ṣiṣẹ́, kí o sì fi ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,+ 10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+
-
-
Léfítíkù 23:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje, kí ẹ sinmi, kí ẹ má ṣiṣẹ́ kankan, kí ẹ fi ìró kàkàkí+ kéde rẹ̀ láti máa rántí, yóò jẹ́ àpéjọ mímọ́.
-
-
Léfítíkù 25:4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àmọ́ kí ọdún keje jẹ́ sábáàtì fún ilẹ̀ náà, tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ kankan níbẹ̀, sábáàtì fún Jèhófà. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí oko yín tàbí kí ẹ rẹ́wọ́ àjàrà yín.
-
-
Léfítíkù 25:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Júbílì ni ọdún àádọ́ta (50) náà yóò jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn tàbí kí ẹ kórè ohun tó hù fúnra rẹ̀ látinú ọkà tó ṣẹ́ kù tàbí kí ẹ kórè èso àjàrà tí ẹ ò tíì rẹ́wọ́ rẹ̀.+
-