ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé míì tí Sólómọ́nì ṣe (1-11)

      • Ó ṣètò bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì (12-16)

      • Àwọn ọkọ̀ òkun Sólómọ́nì (17, 18)

2 Kíróníkà 8:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:37, 38; 7:1; 9:10

2 Kíróníkà 8:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:1

2 Kíróníkà 8:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó tún Tádímórì ní aginjù kọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:17-19
  • +2Ọb 14:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1999, ojú ìwé 28

2 Kíróníkà 8:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 16:5
  • +Joṣ 16:1, 3; 1Kr 7:24

2 Kíróníkà 8:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:44, 48
  • +1Ọb 4:26

2 Kíróníkà 8:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18-21; Nọ 13:29
  • +1Ọb 9:20-23

2 Kíróníkà 8:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:63; 17:12
  • +Joṣ 16:10; 2Kr 2:17, 18

2 Kíróníkà 8:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:39
  • +1Sa 8:11, 12

2 Kíróníkà 8:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:16; 9:23; 2Kr 2:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

2 Kíróníkà 8:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:1
  • +1Ọb 7:8; 9:24
  • +Ẹk 29:43

2 Kíróníkà 8:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3
  • +2Kr 4:1
  • +1Ọb 6:3

2 Kíróníkà 8:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:9
  • +Nọ 28:11-15
  • +Di 16:16
  • +Le 23:6
  • +Le 23:15, 16
  • +Le 23:34

2 Kíróníkà 8:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 24:1
  • +1Kr 6:31, 32; 15:16; 16:37, 42; 25:1
  • +1Kr 26:1

2 Kíróníkà 8:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lẹ́sẹẹsẹ; parí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:1
  • +1Ọb 7:51

2 Kíróníkà 8:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:1, 35; 1Ọb 22:48
  • +Di 2:8; 2Ọb 14:21, 22; 16:6
  • +1Ọb 9:26-28

2 Kíróníkà 8:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:11
  • +1Ọb 22:48; Sm 45:9
  • +1Ọb 10:22
  • +Onw 2:8

Àwọn míì

2 Kíró. 8:11Ọb 6:37, 38; 7:1; 9:10
2 Kíró. 8:21Ọb 5:1
2 Kíró. 8:41Ọb 9:17-19
2 Kíró. 8:42Ọb 14:28
2 Kíró. 8:5Joṣ 16:5
2 Kíró. 8:5Joṣ 16:1, 3; 1Kr 7:24
2 Kíró. 8:6Joṣ 19:44, 48
2 Kíró. 8:61Ọb 4:26
2 Kíró. 8:7Jẹ 15:18-21; Nọ 13:29
2 Kíró. 8:71Ọb 9:20-23
2 Kíró. 8:8Joṣ 15:63; 17:12
2 Kíró. 8:8Joṣ 16:10; 2Kr 2:17, 18
2 Kíró. 8:9Le 25:39
2 Kíró. 8:91Sa 8:11, 12
2 Kíró. 8:101Ọb 5:16; 9:23; 2Kr 2:18
2 Kíró. 8:111Ọb 3:1
2 Kíró. 8:111Ọb 7:8; 9:24
2 Kíró. 8:11Ẹk 29:43
2 Kíró. 8:12Le 1:3
2 Kíró. 8:122Kr 4:1
2 Kíró. 8:121Ọb 6:3
2 Kíró. 8:13Nọ 28:9
2 Kíró. 8:13Nọ 28:11-15
2 Kíró. 8:13Di 16:16
2 Kíró. 8:13Le 23:6
2 Kíró. 8:13Le 23:15, 16
2 Kíró. 8:13Le 23:34
2 Kíró. 8:141Kr 24:1
2 Kíró. 8:141Kr 6:31, 32; 15:16; 16:37, 42; 25:1
2 Kíró. 8:141Kr 26:1
2 Kíró. 8:161Ọb 6:1
2 Kíró. 8:161Ọb 7:51
2 Kíró. 8:17Nọ 33:1, 35; 1Ọb 22:48
2 Kíró. 8:17Di 2:8; 2Ọb 14:21, 22; 16:6
2 Kíró. 8:171Ọb 9:26-28
2 Kíró. 8:182Sa 5:11
2 Kíró. 8:181Ọb 22:48; Sm 45:9
2 Kíró. 8:181Ọb 10:22
2 Kíró. 8:18Onw 2:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 8:1-18

Kíróníkà Kejì

8 Ní òpin ogún (20) ọdún tí Sólómọ́nì fi kọ́ ilé Jèhófà àti ilé ara rẹ̀,*+ 2 Sólómọ́nì tún àwọn ìlú tí Hírámù+ fún un kọ́, ó sì ní kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* máa gbé ibẹ̀. 3 Yàtọ̀ síyẹn, Sólómọ́nì lọ sí Hamati-sóbà, ó sì gbà á. 4 Lẹ́yìn náà, ó kọ́ Tádímórì ní aginjù* àti gbogbo àwọn ìlú tí ó ń kó nǹkan pa mọ́ sí,+ èyí tó kọ́ sí Hámátì.+ 5 Ó tún kọ́ Bẹti-hórónì Òkè+ àti Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ àwọn ìlú aláàbò tó ní ògiri àti àwọn ẹnubodè pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú. 6 Bákan náà, ó kọ́ Báálátì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, gbogbo àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí.

7 Ní ti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ tí wọn kì í ṣe ara àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ 8 àwọn àtọmọdọ́mọ wọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà, ìyẹn àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò pa run,+ Sólómọ́nì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ fún òun títí di òní yìí.+ 9 Àmọ́ Sólómọ́nì kò fi ọmọ Ísírẹ́lì kankan ṣe ẹrú fún iṣẹ́ rẹ̀,+ àwọn ló fi ṣe jagunjagun rẹ̀, olórí àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun rẹ̀, olórí àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ti àwọn agẹṣin rẹ̀.+ 10 Olórí àwọn alábòójútó fún Ọba Sólómọ́nì jẹ́ igba ó lé àádọ́ta (250), àwọn ló sì ń darí àwọn èèyàn náà.+

11 Bákan náà, Sólómọ́nì mú ọmọbìnrin Fáráò+ wá láti Ìlú Dáfídì sí ilé tó kọ́ fún un,+ torí ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó mi ni, kò yẹ kó máa gbé inú ilé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, nítorí ibi tí Àpótí Jèhófà bá ti wọ̀ ti di mímọ́.”+

12 Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì rú àwọn ẹbọ sísun+ sí Jèhófà lórí pẹpẹ+ Jèhófà tí ó mọ síwájú ibi àbáwọlé.*+ 13 Ó ń ṣe ohun tí wọ́n máa ń ṣe lójoojúmọ́, ó sì ń mú ọrẹ wá gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Mósè pa ní ti àwọn Sábáàtì,+ àwọn òṣùpá tuntun+ àti àwọn àjọyọ̀ tó máa ń wáyé nígbà mẹ́ta lọ́dún,+ ìyẹn Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà.+ 14 Síwájú sí i, ó yan àwùjọ àwọn àlùfáà+ sí àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí Dáfídì bàbá rẹ̀ fi lélẹ̀, ó yan àwọn ọmọ Léfì sẹ́nu iṣẹ́ wọn, láti máa yin+ Ọlọ́run àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú àwọn àlùfáà bí wọ́n ti ń ṣe lójoojúmọ́, ó tún yan àwùjọ àwọn aṣọ́bodè sí ẹnubodè kọ̀ọ̀kan,+ nítorí ohun tí Dáfídì, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ pa láṣẹ nìyẹn. 15 Wọn ò kúrò nínú àṣẹ tí ọba pa fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tàbí ní ti ilé ìkẹ́rùsí. 16 Nítorí náà, gbogbo iṣẹ́ Sólómọ́nì wà létòlétò,* láti ọjọ́ tí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀+ títí ó fi parí. Bí ilé Jèhófà ṣe parí nìyẹn.+

17 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì lọ sí Esioni-gébérì+ àti sí Élótì+ ní èbúté òkun tó wà ní ilẹ̀ Édómù.+ 18 Hírámù+ fi àwọn ọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́ ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n bá àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) tálẹ́ńtì* wúrà+ láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́