ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Àwọn àtúnṣe tí Ásà ṣe (1-19)

2 Kíróníkà 15:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 4:8
  • +Ais 55:6
  • +1Kr 28:9; Heb 10:38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 9-10

2 Kíróníkà 15:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:8, 10; 2Kr 17:8, 9; Mal 2:7

2 Kíróníkà 15:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 106:43, 44; Ais 55:7

2 Kíróníkà 15:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kò sí àlàáfíà fún ẹni tó ń jáde lọ tàbí fún ẹni tó ń wọlé bọ̀.”

2 Kíróníkà 15:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 48

2 Kíróníkà 15:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kí ọwọ́ yín wálẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 1:9; 1Kr 28:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2012, ojú ìwé 9

2 Kíróníkà 15:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:24
  • +2Kr 8:12

2 Kíróníkà 15:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 11:16; 30:25

2 Kíróníkà 15:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:29; 2Ọb 23:3; Ne 10:28, 29

2 Kíróníkà 15:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:20

2 Kíróníkà 15:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 15:2
  • +Owe 16:7

2 Kíróníkà 15:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyáàfin.”

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:9, 10
  • +Di 13:6-9
  • +1Ọb 15:13, 14

2 Kíróníkà 15:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn Ásà pé pérépéré.”

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:43
  • +1Ọb 14:22, 23; 2Ọb 14:3, 4; 23:19, 20
  • +1Ọb 8:61

2 Kíróníkà 15:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:51; 15:15; 1Kr 26:26

2 Kíróníkà 15:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 14:1

Àwọn míì

2 Kíró. 15:2Jem 4:8
2 Kíró. 15:2Ais 55:6
2 Kíró. 15:21Kr 28:9; Heb 10:38
2 Kíró. 15:3Di 33:8, 10; 2Kr 17:8, 9; Mal 2:7
2 Kíró. 15:4Sm 106:43, 44; Ais 55:7
2 Kíró. 15:6Di 28:15, 48
2 Kíró. 15:7Joṣ 1:9; 1Kr 28:20
2 Kíró. 15:82Ọb 23:24
2 Kíró. 15:82Kr 8:12
2 Kíró. 15:92Kr 11:16; 30:25
2 Kíró. 15:12Di 4:29; 2Ọb 23:3; Ne 10:28, 29
2 Kíró. 15:13Ẹk 22:20
2 Kíró. 15:152Kr 15:2
2 Kíró. 15:15Owe 16:7
2 Kíró. 15:161Ọb 15:9, 10
2 Kíró. 15:16Di 13:6-9
2 Kíró. 15:161Ọb 15:13, 14
2 Kíró. 15:171Ọb 22:43
2 Kíró. 15:171Ọb 14:22, 23; 2Ọb 14:3, 4; 23:19, 20
2 Kíró. 15:171Ọb 8:61
2 Kíró. 15:181Ọb 7:51; 15:15; 1Kr 26:26
2 Kíró. 15:192Kr 14:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 15:1-19

Kíróníkà Kejì

15 Nígbà náà, ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé Asaráyà ọmọ Ódédì. 2 Nítorí náà, ó lọ bá Ásà, ó sì sọ fún un pé: “Gbọ́ mi, ìwọ Ásà àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì! Jèhófà á máa wà pẹ̀lú yín tí ẹ ò bá ti fi í sílẹ̀;+ tí ẹ bá sì wá a, á jẹ́ kí ẹ rí òun,+ àmọ́ tí ẹ bá fi í sílẹ̀, á fi yín sílẹ̀.+ 3 Ó ti pẹ́ gan-an tí* Ísírẹ́lì ti wà láìní Ọlọ́run tòótọ́, tí wọn ò ní àlùfáà tó ń kọ́ni, tí wọn ò sì ní òfin.+ 4 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì torí pé wọ́n wà nínú wàhálà, tí wọ́n sì wá a, ó jẹ́ kí wọ́n rí òun.+ 5 Ní àkókò yẹn, ewú wà fún àwọn tó ń rìnrìn àjò,* torí pé ọkàn gbogbo àwọn tó ń gbé àwọn ilẹ̀ náà kò balẹ̀ rárá. 6 Orílẹ̀-èdè ń ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè, ìlú kan sì ń ṣẹ́gun ìlú míì, nítorí pé Ọlọ́run fi oríṣiríṣi wàhálà kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+ 7 Àmọ́ ní tiyín, ẹ jẹ́ alágbára, ẹ má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá yín,*+ nítorí pé èrè wà fún iṣẹ́ yín.”

8 Gbàrà tí Ásà gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ódédì, ó mọ́kàn le, ó sì mú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà+ àti Bẹ́ńjámínì àti ní àwọn ìlú tó gbà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó tún pẹpẹ Jèhófà tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà wọ* ilé Jèhófà mọ.+ 9 Ó kó gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ pẹ̀lú àwọn àjèjì tó wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n wá láti Éfúrémù àti Mánásè àti Síméónì,+ torí ọ̀pọ̀ wọn ló sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí i pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 10 Torí náà, wọ́n kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù kẹta ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìjọba Ásà. 11 Lọ́jọ́ yẹn, wọ́n fi ọgọ́rùn-ún méje (700) màlúù àti ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn rúbọ sí Jèhófà látinú ẹrù ogun tí wọ́n kó dé. 12 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n dá májẹ̀mú pé àwọn á fi gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara*+ wọn wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn. 13 Wọ́n á pa ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, ọkùnrin tàbí obìnrin.+ 14 Torí náà, wọ́n búra fún Jèhófà ní ohùn rara pẹ̀lú igbe ìdùnnú àti kàkàkí àti ìwo. 15 Inú gbogbo Júdà dùn sí ìbúra náà, nítorí pé gbogbo ọkàn wọn ni wọ́n fi búra àti pé wọ́n fi ìtara wá a, ó sì jẹ́ kí wọ́n rí òun.+ Jèhófà sì ń fún wọn ní ìsinmi ní ibi gbogbo.+

16 Ọba Ásà tiẹ̀ tún yọ Máákà+ ìyá rẹ̀ àgbà kúrò ní ipò ìyá ọba,* torí pé ó ṣe òrìṣà ẹ̀gbin tí wọ́n fi ń jọ́sìn òpó òrìṣà.*+ Ásà gé òrìṣà ẹ̀gbin rẹ̀ lulẹ̀, ó rún un wómúwómú, ó sì sun ún ní Àfonífojì Kídírónì.+ 17 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò+ ní Ísírẹ́lì. + Síbẹ̀, Ásà fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Ọlọ́run* ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀.+ 18 Ó kó àwọn ohun tí òun àti bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sínú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ìyẹn fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò míì.+ 19 Kò sí ogun títí di ọdún karùndínlógójì ìjọba Ásà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́