Orin Sólómọ́nì
5 “Mo ti wọnú ọgbà mi,+
Ìwọ arábìnrin mi, ìyàwó mi.
Mo ti já òjíá mi àti ewéko olóòórùn dídùn mi.+
Mo ti jẹ afárá oyin mi àti oyin mi;
Mo ti mu wáìnì mi àti wàrà mi.”+
“Ẹ jẹun, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n!
Ẹ mu ìfẹ́,+ kí ẹ sì yó!”
2 “Mo ti sùn lọ, àmọ́ ọkàn mi ò sùn.+
Mo gbọ́ ìró olólùfẹ́ mi tó ń kan ilẹ̀kùn!”
‘Ṣílẹ̀kùn fún mi, arábìnrin mi, olólùfẹ́ mi,
Àdàbà mi, ẹni tí ẹwà rẹ̀ ò lábùlà!
Torí ìrì ti sẹ̀ sí mi lórí,
Ìrì òru+ ti mú kí irun mi tutù.’
3 Mo ti bọ́ aṣọ mi.
Ṣé kí n tún wọ̀ ọ́ pa dà ni?
Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi.
Ṣé kí n tún jẹ́ kó dọ̀tí ni?
4 Olólùfẹ́ mi mú ọwọ́ kúrò lára ihò ilẹ̀kùn,
Ọkàn mi sì túbọ̀ fà sí i.
5 Mo dìde kí n lè ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi;
Òjíá ń kán tótó ní ọwọ́ mi,
Òjíá olómi ń kán ní àwọn ìka mi,
Sára ọwọ́ ilẹ̀kùn.
6 Mo ṣílẹ̀kùn fún olólùfẹ́ mi,
Àmọ́ olólùfẹ́ mi ti pa dà, ó ti lọ.
Àfi bíi pé kò sí ìrètí fún mi* nígbà tó lọ.*
Mo wá a, ṣùgbọ́n mi ò rí i.+
Mo pè é, àmọ́ kò dá mi lóhùn.
7 Àwọn tó ń ṣọ́ ìlú rí mi nígbà tí wọ́n ń lọ yí ká.
Wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe.
Àwọn tó ń ṣọ́ ògiri ṣí ìborùn* mi kúrò lára mi.
8 Mo mú kí ẹ búra, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù:
Tí ẹ bá rí olólùfẹ́ mi,
Kí ẹ sọ fún un pé òjòjò ìfẹ́ ń ṣe mí.”
9 “Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,
Ìwọ tó rẹwà jù nínú àwọn obìnrin?
Kí ló mú kí olólùfẹ́ rẹ dára ju àwọn olólùfẹ́ míì lọ,
Tí o fi mú ká ṣe irú ìbúra yìí?”
10 “Olólùfẹ́ mi rẹwà, ó sì mọ́ra;
Kò sí ẹni tí a lè fi í wé láàárín ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin.
11 Wúrà ni orí rẹ̀, wúrà tó dára jù.
Irun orí rẹ̀ dà bí imọ̀ ọ̀pẹ tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́,*
Ó dúdú bí ẹyẹ ìwò.
12 Ojú rẹ̀ dà bí àwọn àdàbà tó wà létí odò,
Tí wọ́n ń wẹ̀ nínú wàrà,
Tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tó kún.*
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dà bí ebè tí wọ́n gbin ewé tó ń ta sánsán sí,+
Òkìtì ewéko tó ń ta sánsán.
Ètè rẹ̀ dà bí òdòdó lílì, òjíá olómi+ sì ń kán tótó ní ètè rẹ̀.
14 Ọwọ́ rẹ̀ dà bí òpó wúrà, tí wọ́n fi kírísóláítì ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
Ikùn rẹ̀ dà bí eyín erin tó ń dán, tí wọ́n fi òkúta sàfáyà bò.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bí àwọn òpó tí wọ́n fi òkúta mábù ṣe, tó ní ìtẹ́lẹ̀ wúrà tó dára jù.
Ó rí bíi Lẹ́bánónì, kò sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bí àwọn igi kédárì.+
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, olólùfẹ́ mi nìyí, òun lẹni tí mo nífẹ̀ẹ́.”