ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Wọ́n ń wọ inú áàkì (1-10)

      • Ìkún Omi tó bo ayé (11-24)

Jẹ́nẹ́sísì 7:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:9; Heb 10:38; 11:7; 1Pe 3:12; 2Pe 2:5, 9

Jẹ́nẹ́sísì 7:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 31

    1/1/2004, ojú ìwé 29

Jẹ́nẹ́sísì 7:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “méjì-méjì lọ́nà méje lára gbogbo ẹran tó mọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:23; 8:19

Jẹ́nẹ́sísì 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:5
  • +Jẹ 7:11, 12
  • +Jẹ 6:7, 17

Jẹ́nẹ́sísì 7:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:13

Jẹ́nẹ́sísì 7:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 17:27; Heb 11:7

Jẹ́nẹ́sísì 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:19, 20

Jẹ́nẹ́sísì 7:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2013, ojú ìwé 14-15

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 22-23

Jẹ́nẹ́sísì 7:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:7; 8:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2004, ojú ìwé 30

Jẹ́nẹ́sísì 7:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 12

Jẹ́nẹ́sísì 7:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 9:18; 1Kr 1:4
  • +Jẹ 6:18; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5

Jẹ́nẹ́sísì 7:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èémí ìyè.”

Jẹ́nẹ́sísì 7:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ń bá a lọ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2013, ojú ìwé 13-14

Jẹ́nẹ́sísì 7:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Pe 3:5, 6

Jẹ́nẹ́sísì 7:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Jẹ́nẹ́sísì 7:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ẹran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:7, 17
  • +Lk 17:27

Jẹ́nẹ́sísì 7:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀mí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:7; 7:15; Onw 3:19; Ais 42:5

Jẹ́nẹ́sísì 7:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:7; 2Pe 3:5, 6
  • +Mt 24:37-39; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5, 9

Jẹ́nẹ́sísì 7:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:3

Àwọn míì

Jẹ́n. 7:1Jẹ 6:9; Heb 10:38; 11:7; 1Pe 3:12; 2Pe 2:5, 9
Jẹ́n. 7:2Jẹ 8:20
Jẹ́n. 7:3Jẹ 7:23; 8:19
Jẹ́n. 7:4Jẹ 2:5
Jẹ́n. 7:4Jẹ 7:11, 12
Jẹ́n. 7:4Jẹ 6:7, 17
Jẹ́n. 7:6Jẹ 8:13
Jẹ́n. 7:7Lk 17:27; Heb 11:7
Jẹ́n. 7:8Jẹ 6:19, 20
Jẹ́n. 7:11Jẹ 1:7; 8:2
Jẹ́n. 7:13Jẹ 9:18; 1Kr 1:4
Jẹ́n. 7:13Jẹ 6:18; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5
Jẹ́n. 7:192Pe 3:5, 6
Jẹ́n. 7:21Jẹ 6:7, 17
Jẹ́n. 7:21Lk 17:27
Jẹ́n. 7:22Jẹ 2:7; 7:15; Onw 3:19; Ais 42:5
Jẹ́n. 7:23Jẹ 6:7; 2Pe 3:5, 6
Jẹ́n. 7:23Mt 24:37-39; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5, 9
Jẹ́n. 7:24Jẹ 8:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 7:1-24

Jẹ́nẹ́sísì

7 Jèhófà wá sọ fún Nóà pé: “Wọ inú áàkì, ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, torí ìwọ ni mo rí pé ó jẹ́ olódodo níwájú mi nínú ìran yìí.+ 2 Kí o mú gbogbo onírúurú ẹran tó mọ́ ní méje-méje,*+ ní akọ àti abo; mú méjì-méjì péré nínú gbogbo ẹran tí kò mọ́, ní akọ àti abo; 3 kí o sì mú àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run ní méje-méje,* ní akọ àti abo, kí ọmọ wọn má bàa pa run ní gbogbo ayé.+ 4 Torí ní ọjọ́ méje òní, èmi yóò rọ òjò+ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru,+ màá sì run gbogbo ohun alààyè tí mo dá kúrò lórí ilẹ̀.”+ 5 Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé kó ṣe.

6 Ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún ni Nóà nígbà tí ìkún omi bo ayé.+ 7 Nóà, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ sì wọnú áàkì kí ìkún omi+ náà tó bẹ̀rẹ̀. 8 Àwọn kan lára gbogbo ẹran tó mọ́ àti gbogbo ẹran tí kò mọ́, lára àwọn ẹ̀dá tó ń fò àti gbogbo ohun tó ń rìn lórí ilẹ̀,+ 9 wọ́n wọnú áàkì lọ bá Nóà ní méjì-méjì, ní akọ àti abo, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún Nóà. 10 Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ìkún omi bo ayé.

11 Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, ní ọdún tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún, ọjọ́ yẹn ni gbogbo orísun omi ya, àwọn ibodè omi ọ̀run sì ṣí.+ 12 Òjò rọ̀ sórí ayé fún ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì (40) òru. 13 Ní ọjọ́ yẹn gan-an, Nóà wọ inú áàkì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì,+ pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àti ìyàwó àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.+ 14 Wọ́n wọlé, pẹ̀lú gbogbo ẹran inú igbó ní irú tiwọn, gbogbo ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn, gbogbo ẹran tó ń rákò ní ayé ní irú tiwọn, gbogbo ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, títí kan gbogbo ẹyẹ àti gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́. 15 Wọ́n ń wọlé lọ bá Nóà nínú áàkì, ní méjì-méjì, lára onírúurú ẹran tó ní ẹ̀mí.* 16 Wọ́n wá wọlé, akọ àti abo nínú onírúurú ẹran, bí Ọlọ́run ṣe pàṣẹ fún un. Lẹ́yìn náà, Jèhófà ti ilẹ̀kùn pa.

17 Ìkún omi náà ò dáwọ́ dúró* lórí ayé fún ogójì (40) ọjọ́, omi náà sì ń pọ̀ sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbé áàkì náà, ó sì léfòó lórí omi tó bo ayé. 18 Omi náà bolẹ̀, ó sì ń pọ̀ gan-an ní ayé, àmọ́ áàkì náà léfòó lórí omi. 19 Omi náà bo ayé débi pé gbogbo òkè tó ga tó wà lábẹ́ ọ̀run ni omi bò mọ́lẹ̀.+ 20 Omi náà fi ìgbọ̀nwọ́* mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ga ju àwọn òkè lọ.

21 Torí náà, gbogbo ohun alààyè* tó wà ní ayé pa run,+ ìyẹn, àwọn ẹ̀dá tó ń fò, àwọn ẹran ọ̀sìn, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn àti gbogbo aráyé.+ 22 Gbogbo ohun tó wà lórí ilẹ̀ tó ní èémí ìyè* ní ihò imú rẹ̀ ló kú.+ 23 Ó run gbogbo ohun alààyè tó wà ní ayé, títí kan èèyàn àti ẹran, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run. Gbogbo wọn pátá ló pa run ní ayé;+ Nóà àti àwọn tí wọ́n jọ wà nínú áàkì nìkan ló yè é.+ 24 Omi náà sì bo ayé fún àádọ́jọ (150) ọjọ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́