ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Látorí Ádámù dórí Nóà (1-32)

        • Ádámù bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin (4)

        • Énọ́kù bá Ọlọ́run rìn (21-24)

Jẹ́nẹ́sísì 5:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:26; Jem 3:9

Jẹ́nẹ́sísì 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ádámù; Aráyé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:27; Mk 10:6
  • +Jẹ 2:23; Ais 45:12; Mt 19:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2020, ojú ìwé 1-2

Jẹ́nẹ́sísì 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 62-63

Jẹ́nẹ́sísì 5:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:17; 3:19; Ro 6:23; 1Kọ 15:22

Jẹ́nẹ́sísì 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:26; Lk 3:23, 38

Jẹ́nẹ́sísì 5:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:23, 37

Jẹ́nẹ́sísì 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:23, 37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2002, ojú ìwé 5-6

Jẹ́nẹ́sísì 5:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jud 14

Jẹ́nẹ́sísì 5:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:23, 37

Jẹ́nẹ́sísì 5:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọlọ́run náà.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2017 ojú ìwé 10-11

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2005, ojú ìwé 15-17

    5/1/2003, ojú ìwé 29

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 64

Jẹ́nẹ́sísì 5:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2017 ojú ìwé 10

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 64

Jẹ́nẹ́sísì 5:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:9; Di 8:6; 13:4; 3Jo 4; Jud 14, 15
  • +Jo 3:13; Heb 11:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2017 ojú ìwé 12-13

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2006, ojú ìwé 19

    9/1/2005, ojú ìwé 15

    1/1/2004, ojú ìwé 29

    9/15/2001, ojú ìwé 31

    6/1/1998, ojú ìwé 9

    1/15/1997, ojú ìwé 30-31

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 65-66

Jẹ́nẹ́sísì 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:23, 36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2017 ojú ìwé 11

Jẹ́nẹ́sísì 5:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ìsinmi; Ìtùnú.”

  • *

    Tàbí “tù wá lára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 7:1; Isk 14:14; Mt 24:37; Heb 11:7; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5
  • +Jẹ 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2017, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2013, ojú ìwé 14

    2/1/2009, ojú ìwé 13

    11/15/2001, ojú ìwé 29

    11/1/1996, ojú ìwé 8

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 22

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 67, 79

Jẹ́nẹ́sísì 5:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 67

Jẹ́nẹ́sísì 5:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:21; 11:10; Lk 3:23, 36
  • +Jẹ 6:10; 10:6
  • +Jẹ 10:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2012, ojú ìwé 23

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 68

Àwọn míì

Jẹ́n. 5:1Jẹ 1:26; Jem 3:9
Jẹ́n. 5:2Jẹ 1:27; Mk 10:6
Jẹ́n. 5:2Jẹ 2:23; Ais 45:12; Mt 19:4
Jẹ́n. 5:3Jẹ 4:25
Jẹ́n. 5:5Jẹ 2:17; 3:19; Ro 6:23; 1Kọ 15:22
Jẹ́n. 5:6Jẹ 4:26; Lk 3:23, 38
Jẹ́n. 5:12Lk 3:23, 37
Jẹ́n. 5:15Lk 3:23, 37
Jẹ́n. 5:18Jud 14
Jẹ́n. 5:21Lk 3:23, 37
Jẹ́n. 5:24Jẹ 6:9; Di 8:6; 13:4; 3Jo 4; Jud 14, 15
Jẹ́n. 5:24Jo 3:13; Heb 11:5
Jẹ́n. 5:25Lk 3:23, 36
Jẹ́n. 5:29Jẹ 7:1; Isk 14:14; Mt 24:37; Heb 11:7; 1Pe 3:20; 2Pe 2:5
Jẹ́n. 5:29Jẹ 3:17
Jẹ́n. 5:32Jẹ 10:21; 11:10; Lk 3:23, 36
Jẹ́n. 5:32Jẹ 6:10; 10:6
Jẹ́n. 5:32Jẹ 10:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 5:1-32

Jẹ́nẹ́sísì

5 Ìwé ìtàn Ádámù nìyí. Ní ọjọ́ tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó dá a ní àwòrán Ọlọ́run.+ 2 Ó dá wọn ní akọ àti abo.+ Ní ọjọ́ tó dá wọn,+ ó súre fún wọn, ó sì pè wọ́n ní Èèyàn.*

3 Ádámù pé ẹni àádóje (130) ọdún, ó wá bí ọmọkùnrin kan tó jọ ọ́, tó jẹ́ àwòrán rẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì.+ 4 Lẹ́yìn tó bí Sẹ́ẹ̀tì, Ádámù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 5 Gbogbo ọjọ́ ayé Ádámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé ọgbọ̀n (930) ọdún, ó sì kú.+

6 Sẹ́ẹ̀tì pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rùn-ún (105), ó wá bí Énọ́ṣì.+ 7 Lẹ́yìn tó bí Énọ́ṣì, Sẹ́ẹ̀tì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé méje (807). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 8 Gbogbo ọjọ́ ayé Sẹ́ẹ̀tì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé méjìlá (912), ó sì kú.

9 Énọ́ṣì pé ẹni àádọ́rùn-ún (90) ọdún, ó wá bí Kénánù. 10 Lẹ́yìn tó bí Kénánù, Énọ́ṣì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ọdún ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (815). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 11 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́ṣì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé márùn-ún (905), ó sì kú.

12 Kénánù pé ẹni àádọ́rin (70) ọdún, ó wá bí Máhálálélì.+ 13 Lẹ́yìn tó bí Máhálálélì, Kénánù tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ogójì (840) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 14 Gbogbo ọjọ́ ayé Kénánù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó lé mẹ́wàá (910), ó sì kú.

15 Máhálálélì pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Járédì.+ 16 Lẹ́yìn tó bí Járédì, Máhálálélì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé ọgbọ̀n (830) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 17 Gbogbo ọjọ́ ayé Máhálálélì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ọdún ó dín márùn-ún (895), ó sì kú.

18 Járédì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́jọ (162), ó wá bí Énọ́kù.+ 19 Lẹ́yìn tó bí Énọ́kù, Járédì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 20 Gbogbo ọjọ́ ayé Járédì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti méjìlélọ́gọ́ta (962) ọdún, ó sì kú.

21 Énọ́kù pé ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin (65), ó wá bí Mètúsélà.+ 22 Lẹ́yìn tó bí Mètúsélà, Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́* rìn fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 23 Gbogbo ọjọ́ ayé Énọ́kù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin (365) ọdún. 24 Énọ́kù ń bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. Nígbà tó yá, Énọ́kù ò sí mọ́, torí Ọlọ́run mú un lọ.+

25 Mètúsélà pé ẹni ọgọ́sàn-án ọdún ó lé méje (187), ó wá bí Lámékì.+ 26 Lẹ́yìn tó bí Lámékì, Mètúsélà tún lo ọgọ́rùn-ún méje àti méjìlélọ́gọ́rin (782) ọdún. Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 27 Gbogbo ọjọ́ ayé Mètúsélà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti mọ́kàndínláàádọ́rin (969) ọdún, ó sì kú.

28 Lámékì pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́sàn-án (182), ó wá bí ọmọkùnrin kan. 29 Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Nóà,*+ ó sọ pé: “Ọmọ yìí á tù wá nínú* nídìí iṣẹ́ wa àti làálàá tí a ṣe torí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.”+ 30 Lẹ́yìn tó bí Nóà, Lámékì tún lo ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ọdún ó dín márùn-ún (595). Ó sì bí àwọn ọmọ lọ́kùnrin àti lóbìnrin. 31 Gbogbo ọjọ́ ayé Lámékì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (777) ọdún, ó sì kú.

32 Lẹ́yìn tí Nóà pé ẹni ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún, ó bí Ṣémù,+ Hámù+ àti Jáfẹ́tì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́