Sáàmù
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin atunilára. Orin.
67 Ọlọ́run yóò ṣojú rere sí wa, yóò sì bù kún wa;
Yóò mú kí ojú rẹ̀ tàn sí wa lára+ (Sélà)
3 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;
Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.
4 Kí inú àwọn orílẹ̀-èdè máa dùn, kí wọ́n sì máa kígbe ayọ̀,+
Nítorí wàá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó tọ́.+
Wàá ṣamọ̀nà àwọn orílẹ̀-èdè ayé. (Sélà)
5 Kí àwọn èèyàn máa yìn ọ́, Ọlọ́run;
Kí gbogbo àwọn èèyàn máa yìn ọ́.