ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Ìnilára burú ju ikú lọ (1-3)

      • Ojú tó yẹ ká fi wo iṣẹ́ (4-6)

      • Iyì ọ̀rẹ́ (7-12)

        • Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ (9)

      • Ìgbésí ayé alákòóso lè jẹ́ asán (13-16)

Oníwàásù 4:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 69:20; 142:4

Oníwàásù 4:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 3:17; Onw 2:17

Oníwàásù 4:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 20:18
  • +Onw 1:14

Oníwàásù 4:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣiṣẹ́ kára.”

  • *

    Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 5:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14

    11/1/1999, ojú ìwé 32

    2/15/1997, ojú ìwé 15-16

Oníwàásù 4:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó ń jẹ ẹran ara rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 6:10, 11; 20:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/1999, ojú ìwé 32

Oníwàásù 4:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:16; Owe 15:16; 16:8; 17:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    No. 1 2020 ojú ìwé 10

    2/2014, ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/1999, ojú ìwé 32

Oníwàásù 4:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Oníwàásù 4:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 27:20; Onw 5:10
  • +Sm 39:6; Lk 12:18-20
  • +Onw 2:22, 23

Oníwàásù 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èrè púpọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:18; Owe 27:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 42

Oníwàásù 4:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.

Oníwàásù 4:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kò rọrùn láti.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 111-112

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2009, ojú ìwé 18

    12/15/2008, ojú ìwé 30

Oníwàásù 4:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 19:1; 28:6, 16
  • +1Ọb 22:8; 2Kr 25:15, 16

Oníwàásù 4:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí ọlọ́gbọ́n ọmọ náà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 41:14, 40
  • +2Sa 7:8; Job 5:11

Oníwàásù 4:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14

Oníwàásù 4:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 20:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14

Àwọn míì

Oníw. 4:1Sm 69:20; 142:4
Oníw. 4:2Job 3:17; Onw 2:17
Oníw. 4:3Jer 20:18
Oníw. 4:3Onw 1:14
Oníw. 4:4Ga 5:26
Oníw. 4:5Owe 6:10, 11; 20:4
Oníw. 4:6Sm 37:16; Owe 15:16; 16:8; 17:1
Oníw. 4:8Owe 27:20; Onw 5:10
Oníw. 4:8Sm 39:6; Lk 12:18-20
Oníw. 4:8Onw 2:22, 23
Oníw. 4:9Jẹ 2:18; Owe 27:17
Oníw. 4:13Owe 19:1; 28:6, 16
Oníw. 4:131Ọb 22:8; 2Kr 25:15, 16
Oníw. 4:14Jẹ 41:14, 40
Oníw. 4:142Sa 7:8; Job 5:11
Oníw. 4:162Sa 20:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 4:1-16

Oníwàásù

4 Mo tún fiyè sí gbogbo ìwà ìnilára tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.* Mo rí omijé àwọn tí wọ́n ń ni lára, kò sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú.+ Agbára wà lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára, kò sì sí ẹni tó máa tù wọ́n nínú. 2 Mo bá àwọn tó ti kú yọ̀ dípò àwọn tó ṣì wà láàyè.+ 3 Ẹni tó sàn ju àwọn méjèèjì lọ ni ẹni tí wọn ò tíì bí,+ tí kò tíì rí ohun tó ń kó ìdààmú báni tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+

4 Mo ti rí bí ìdíje+ ṣe ń mú kí àwọn èèyàn máa sapá,* kí wọ́n sì máa fòye ṣiṣẹ́; asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*

5 Òmùgọ̀ ká ọwọ́ gbera, bẹ́ẹ̀ ló ń rù sí i.*+

6 Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílé ohun tó jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.*+

7 Mo fiyè sí àpẹẹrẹ ohun míì tó jẹ́ asán lábẹ́ ọ̀run:* 8 Ọkùnrin kan wà tó dá wà, kò ní ẹnì kejì; kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ará, àmọ́ iṣẹ́ àṣekára tó ń ṣe kò lópin. Ojú rẹ̀ kò kúrò nínú kíkó ọrọ̀ jọ.+ Àmọ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ bi ara rẹ̀ pé, ‘Ta ni mò ń tìtorí rẹ̀ ṣiṣẹ́ kára tí mo sì ń fi àwọn ohun rere du ara mi’?+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ó sì jẹ́ iṣẹ́ tó ń tánni lókun.+

9 Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ,+ nítorí pé wọ́n ní èrè* fún iṣẹ́ àṣekára wọn. 10 Torí tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé e* dìde. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ṣubú tí kò sí ẹni tó máa gbé e dìde?

11 Bákan náà, tí àwọn méjì bá dùbúlẹ̀ pa pọ̀, ara wọn á móoru, àmọ́ báwo ni ẹnì kan ṣoṣo ṣe lè móoru? 12 Ẹnì kan lè borí ẹni tó dá wà, àmọ́ àwọn méjì tó wà pa pọ̀ lè kojú rẹ̀. Okùn onífọ́nrán mẹ́ta kò ṣeé tètè* fà já.

13 Ọmọdé tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n sàn ju àgbàlagbà ọba tó jẹ́ òmùgọ̀,+ tí làákàyè rẹ̀ kò tó láti gba ìkìlọ̀ mọ́.+ 14 Nítorí inú ẹ̀wọ̀n ló* ti jáde lọ di ọba,+ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà tí ẹni yẹn ń ṣàkóso lọ́wọ́ ni wọ́n bí i ní aláìní.+ 15 Mo kíyè sí gbogbo àwọn alààyè tó ń rìn káàkiri lábẹ́ ọ̀run,* mo tún kíyè sí bí nǹkan ṣe rí fún ọmọ tó wá gba ipò ọba náà. 16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó ń tì í lẹ́yìn kò lóǹkà, inú àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn kò ní dùn sí i.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́