ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 35
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Jékọ́bù mú àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò (1-4)

      • Jékọ́bù pa dà sí Bẹ́tẹ́lì (5-15)

      • Réṣẹ́lì bí Bẹ́ńjámínì; Réṣẹ́lì kú (16-20)

      • Àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (21-26)

      • Ísákì kú (27-29)

Jẹ́nẹ́sísì 35:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:19; 31:13
  • +Jẹ 27:42-44

Jẹ́nẹ́sísì 35:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:19; Di 5:7; Joṣ 23:7; 1Kọ 10:14

Jẹ́nẹ́sísì 35:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ní ọ̀nà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:13, 15; 31:42

Jẹ́nẹ́sísì 35:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi wọ́n pa mọ́.”

Jẹ́nẹ́sísì 35:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:19

Jẹ́nẹ́sísì 35:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Bẹ́tẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:20-22

Jẹ́nẹ́sísì 35:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “igi óákù.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Igi Óákù Tí Wọ́n Ń Sunkún Lábẹ́ Rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 24:59

Jẹ́nẹ́sísì 35:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:26; 27:36
  • +Jẹ 32:28

Jẹ́nẹ́sísì 35:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ti abẹ́nú rẹ jáde.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 17:1; Ẹk 6:3; Ifi 15:3
  • +Jẹ 48:3, 4
  • +Jẹ 17:5, 6; Jo 12:13

Jẹ́nẹ́sísì 35:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18; Di 34:4

Jẹ́nẹ́sísì 35:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:18

Jẹ́nẹ́sísì 35:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 28:19

Jẹ́nẹ́sísì 35:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 30:22-24

Jẹ́nẹ́sísì 35:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Bí ọkàn rẹ̀ ṣe ń jáde lọ.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọmọ Tí Mo Bí Nígbà Ọ̀fọ̀.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọmọ Ọwọ́ Ọ̀tún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 46:21; 49:27; Di 33:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2009, ojú ìwé 14

    7/15/2007, ojú ìwé 5

    4/1/1999, ojú ìwé 16

    Nígbà Tí A Bá Kú, ojú ìwé 22-23

Jẹ́nẹ́sísì 35:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 48:7; Mik 5:2; Mt 2:6

Jẹ́nẹ́sísì 35:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:3, 4; 1Kr 5:1

Jẹ́nẹ́sísì 35:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:3

Jẹ́nẹ́sísì 35:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 31:17, 18
  • +Jẹ 15:13; Heb 11:9

Jẹ́nẹ́sísì 35:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:20, 26

Jẹ́nẹ́sísì 35:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

  • *

    Ní Héb., “ó darúgbó, ó sì lọ́jọ́ lórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:30, 31

Àwọn míì

Jẹ́n. 35:1Jẹ 28:19; 31:13
Jẹ́n. 35:1Jẹ 27:42-44
Jẹ́n. 35:2Jẹ 31:19; Di 5:7; Joṣ 23:7; 1Kọ 10:14
Jẹ́n. 35:3Jẹ 28:13, 15; 31:42
Jẹ́n. 35:6Jẹ 28:19
Jẹ́n. 35:7Jẹ 28:20-22
Jẹ́n. 35:8Jẹ 24:59
Jẹ́n. 35:10Jẹ 25:26; 27:36
Jẹ́n. 35:10Jẹ 32:28
Jẹ́n. 35:11Jẹ 17:1; Ẹk 6:3; Ifi 15:3
Jẹ́n. 35:11Jẹ 48:3, 4
Jẹ́n. 35:11Jẹ 17:5, 6; Jo 12:13
Jẹ́n. 35:12Jẹ 15:18; Di 34:4
Jẹ́n. 35:14Jẹ 28:18
Jẹ́n. 35:15Jẹ 28:19
Jẹ́n. 35:17Jẹ 30:22-24
Jẹ́n. 35:18Jẹ 46:21; 49:27; Di 33:12
Jẹ́n. 35:19Jẹ 48:7; Mik 5:2; Mt 2:6
Jẹ́n. 35:22Jẹ 49:3, 4; 1Kr 5:1
Jẹ́n. 35:23Jẹ 49:3
Jẹ́n. 35:27Jẹ 31:17, 18
Jẹ́n. 35:27Jẹ 15:13; Heb 11:9
Jẹ́n. 35:28Jẹ 25:20, 26
Jẹ́n. 35:29Jẹ 49:30, 31
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 35:1-29

Jẹ́nẹ́sísì

35 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Jékọ́bù pé: “Gbéra, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì,+ ibẹ̀ ni kí o máa gbé, kí o sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó fara hàn ọ́ nígbà tí ò ń sá fún Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n+ rẹ.”

2 Jékọ́bù wá sọ fún agbo ilé rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà láàárín yín+ kúrò, kí ẹ wẹ ara yín mọ́, kí ẹ pààrọ̀ aṣọ yín, 3 kí ẹ jẹ́ ká gbéra, ká sì gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ibẹ̀ ni èmi yóò mọ pẹpẹ kan sí fún Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tó dá mi lóhùn ní ọjọ́ tí mo wà nínú ìṣòro, tó sì wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ibi* tí mo lọ.”+ 4 Torí náà, wọ́n kó gbogbo ọlọ́run àjèjì tí wọ́n ní àti àwọn yẹtí tó wà ní etí wọn fún Jékọ́bù, Jékọ́bù sì rì wọ́n mọ́lẹ̀* sábẹ́ igi ńlá tó wà nítòsí Ṣékémù.

5 Bí wọ́n ṣe ń lọ, ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú àwọn ìlú tó yí wọn ká, torí náà, wọn ò lépa àwọn ọmọ Jékọ́bù. 6 Jékọ́bù wá dé Lúsì,+ ìyẹn Bẹ́tẹ́lì, ní ilẹ̀ Kénáánì, òun àti gbogbo èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 7 Ó mọ pẹpẹ kan síbẹ̀, ó sì pe ibẹ̀ ní Eli-bẹ́tẹ́lì,* torí ibẹ̀ ni Ọlọ́run tòótọ́ ti fara hàn án nígbà tó ń sá fún ẹ̀gbọ́n+ rẹ̀. 8 Nígbà tó yá, Dèbórà+ tó jẹ́ olùtọ́jú Rèbékà kú, wọ́n sì sin ín sí ìsàlẹ̀ Bẹ́tẹ́lì lábẹ́ igi ràgàjì* kan. Torí náà, ó pè é ní Aloni-bákútì.*

9 Ọlọ́run fara han Jékọ́bù lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tó ń bọ̀ láti Padani-árámù, ó sì súre fún un. 10 Ọlọ́run sọ fún un pé: “Jékọ́bù+ ni orúkọ rẹ. Àmọ́, o ò ní máa jẹ́ Jékọ́bù mọ́, Ísírẹ́lì ni wàá máa jẹ́.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pè é ní Ísírẹ́lì.+ 11 Ọlọ́run tún sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè.+ Máa bímọ, kí o sì di púpọ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè àti àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè yóò tinú rẹ jáde,+ àwọn ọba yóò sì ti ara rẹ jáde.*+ 12 Màá fún ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ ní ilẹ̀+ tí mo fún Ábúráhámù àti Ísákì.” 13 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tó ti bá a sọ̀rọ̀.

14 Jékọ́bù sì gbé òpó kan dúró níbi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, òpó òkúta ni, ó sì da ọrẹ ohun mímu àti òróró sórí rẹ̀.+ 15 Jékọ́bù sì ń pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.+

16 Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣí kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tí ọ̀nà wọn ṣì jìn díẹ̀ sí Éfúrátì, Réṣẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó sì nira fún un gan-an. 17 Àmọ́ bó ṣe ń tiraka kí ọmọ náà lè jáde, agbẹ̀bí náà sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí wàá bí ọmọ yìí pẹ̀lú.”+ 18 Bí ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ń bọ́ lọ* (torí ó ń kú lọ), ó sọ ọmọ náà ní Bẹni-ónì,* àmọ́ bàbá rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹ́ńjámínì.*+ 19 Réṣẹ́lì wá kú, wọ́n sì sin ín ní ojú ọ̀nà Éfúrátì, ìyẹn Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.+ 20 Jékọ́bù gbé òpó kan dúró sórí sàréè rẹ̀; òun ni òpó sàréè Réṣẹ́lì títí dòní.

21 Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì ṣí kúrò, ó sì pàgọ́ rẹ̀ sí ìkọjá ilé gogoro Édérì. 22 Nígbà kan tí Ísírẹ́lì ń gbé ilẹ̀ yẹn, Rúbẹ́nì lọ bá Bílíhà tó jẹ́ wáhàrì* bàbá rẹ̀ sùn, Ísírẹ́lì sì gbọ́ nípa rẹ̀.+

Àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù jẹ́ méjìlá (12). 23 Àwọn ọmọkùnrin tí Líà bí ni Rúbẹ́nì+ tó jẹ́ àkọ́bí Jékọ́bù, lẹ́yìn náà, ó bí Síméónì, Léfì, Júdà, Ísákà àti Sébúlúnì. 24 Àwọn ọmọkùnrin tí Réṣẹ́lì bí ni Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. 25 Àwọn ọmọkùnrin tí Bílíhà ìránṣẹ́ Réṣẹ́lì bí ni Dánì àti Náfútálì. 26 Àwọn ọmọkùnrin tí Sílípà ìránṣẹ́ Líà bí ni Gádì àti Áṣérì. Àwọn ni ọmọkùnrin Jékọ́bù, tí wọ́n bí fún un ní Padani-árámù.

27 Nígbà tó yá, Jékọ́bù dé ibi tí Ísákì bàbá rẹ̀ wà ní Mámúrè,+ ní Kiriati-ábà, ìyẹn Hébúrónì, níbi tí Ábúráhámù àti Ísákì pẹ̀lú ti gbé rí bí àjèjì.+ 28 Ọjọ́ ayé Ísákì sì jẹ́ ọgọ́sàn-án (180) ọdún.+ 29 Ísákì wá mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀,* lẹ́yìn tó ti pẹ́ láyé, tí ayé rẹ̀ sì dáa;* Ísọ̀ àti Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ sì sin ín.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́