Jóṣúà
3 Jóṣúà wá dìde ní àárọ̀ kùtù, òun àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì* kúrò ní Ṣítímù,+ wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì. Wọ́n sun ibẹ̀ mọ́jú kí wọ́n tó sọdá.
2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, àwọn olórí+ lọ káàkiri ibùdó, 3 wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn èèyàn náà pé: “Gbàrà tí ẹ bá rí i tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà+ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ gbéra láti àyè yín, kí ẹ sì tẹ̀ lé e. 4 Àmọ́ kí ẹ fi àyè tí ó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́* sílẹ̀ láàárín ẹ̀yin àti àpótí náà; ẹ má ṣe sún mọ́ ọn rárá, kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ máa gbà, torí pé ẹ ò gba ọ̀nà yìí rí.”
5 Jóṣúà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ sọ ara yín di mímọ́,+ torí Jèhófà máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu láàárín yín lọ́la.”+
6 Jóṣúà sì sọ fún àwọn àlùfáà pé: “Ẹ gbé àpótí+ májẹ̀mú náà, kí ẹ máa nìṣó níwájú àwọn èèyàn náà.” Torí náà, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú, wọ́n sì ń lọ níwájú àwọn èèyàn náà.
7 Jèhófà wá sọ fún Jóṣúà pé: “Òní yìí ni mo máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì,+ kí wọ́n lè mọ̀ pé màá wà pẹ̀lú rẹ+ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mósè.+ 8 Kí o pa àṣẹ yìí fún àwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú náà pé: ‘Tí ẹ bá dé etí odò Jọ́dánì, kí ẹ dúró sínú Jọ́dánì.’”+
9 Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wá gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yín.” 10 Jóṣúà sì sọ pé: “Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè kan wà láàárín yín,+ ó sì dájú pé ó máa lé àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Hífì, àwọn Pérísì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì àti àwọn ará Jébúsì kúrò níwájú yín.+ 11 Ẹ wò ó! Àpótí májẹ̀mú Olúwa gbogbo ayé ń lọ níwájú yín sínú Jọ́dánì. 12 Ẹ mú ọkùnrin méjìlá (12) látinú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan,+ 13 gbàrà tí àtẹ́lẹsẹ̀ àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí Jèhófà, Olúwa gbogbo ayé bá kan* omi Jọ́dánì, omi Jọ́dánì tó ń ṣàn wá látòkè máa dáwọ́ dúró, ó sì máa dúró bí ìsédò.”*+
14 Nígbà tí àwọn èèyàn náà kúrò nínú àgọ́ wọn, kété kí wọ́n tó sọdá Jọ́dánì, àwọn àlùfáà tó gbé àpótí+ májẹ̀mú ń lọ níwájú àwọn èèyàn náà. 15 Gbàrà tí àwọn tó gbé Àpótí náà dé Jọ́dánì, tí àwọn àlùfáà tó gbé Àpótí náà sì ki ẹsẹ̀ wọn bọ etí omi náà (ó ṣẹlẹ̀ pé odò Jọ́dánì máa ń kún bo bèbè rẹ̀+ ní gbogbo ọjọ́ ìkórè), 16 omi tó ń ṣàn wá látòkè dáwọ́ dúró. Ó dúró bí ìsédò* síbi tó jìnnà gan-an ní Ádámù, ìlú tó wà nítòsí Sárétánì, èyí tó sì lọ sí Òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,* ṣàn lọ títí tó fi gbẹ. Omi odò náà dáwọ́ dúró, àwọn èèyàn náà sì sọdá síbi tó dojú kọ Jẹ́ríkò. 17 Àwọn àlùfáà tó gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà dúró sójú kan lórí ilẹ̀+ ní àárín Jọ́dánì, nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì ń gba orí ilẹ̀ kọjá,+ wọ́n dúró títí gbogbo orílẹ̀-èdè náà fi sọdá Jọ́dánì tán.