Jóòbù
19 Jóòbù fèsì pé:
4 Tí mo bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe,
Èmi ni mo ni àṣìṣe náà.
5 Tí ẹ bá ṣì ń gbé ara yín ga jù mí lọ,
Tí ẹ̀ ń sọ pé ó tọ́ láti fi mí ṣẹlẹ́yà,
6 Nígbà náà, kí ẹ mọ̀ pé Ọlọ́run ló ṣì mí lọ́nà,
Ó sì ti fi àwọ̀n tó fi ń dọdẹ mú mi.
7 Wò ó! Mò ń ké ṣáá pé, ‘Ìwà ipá!’ àmọ́ kò sẹ́ni tó dáhùn;+
Mò ń kígbe ṣáá pé mo nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ìdájọ́ òdodo.+
8 Ó ti fi ògiri olókùúta dí ọ̀nà mi, mi ò sì lè kọjá;
Ó ti fi òkùnkùn+ bo àwọn òpópónà mi.
9 Ó ti bọ́ ògo mi kúrò lára mi,
Ó sì ti ṣí adé kúrò lórí mi.
10 Ó wó mi lulẹ̀ yí ká títí mo fi ṣègbé;
Ó sì fa ìrètí mi tu bí igi.
11 Ó bínú sí mi gidigidi,
Ó sì kà mí sí ọ̀tá rẹ̀.+
12 Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kóra jọ, wọ́n sì gbéjà kò mí,
Wọ́n pàgọ́ yí ibùdó mi ká.
13 Ó ti lé àwọn arákùnrin mi jìnnà réré sí mi,
Àwọn tó sì mọ̀ mí ti kúrò lọ́dọ̀ mi.+
15 Mo ti di àjèjì sí àwọn àlejò inú ilé mi+ àti àwọn ẹrúbìnrin mi;
Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni mo jẹ́ lójú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, àmọ́ kò dáhùn;
Ẹnu mi ni mo fi bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú mi.
18 Àwọn ọmọdé pàápàá fojú àbùkù wò mí;
Tí mo bá dìde, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
21 Ẹ ṣàánú mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ ṣàánú mi,
Torí ọwọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti kàn mí.+
23 Ká ní wọ́n kọ ọ̀rọ̀ mi sílẹ̀ ni,
Ká ní wọ́n lè kọ ọ́ sínú ìwé!
24 Ká ní wọ́n lè fi kálàmù irin àti òjé gbẹ́ ẹ
Sára àpáta, kó lè wà níbẹ̀ títí láé!
26 Tí awọ ara mi bá ti ṣí kúrò,*
Tí mo ṣì ní ẹran lára, màá rí Ọlọ́run,
27 Ẹni tí màá rí fúnra mi,
Ẹni tí màá fi ojú ara mi rí, kì í ṣe ojú ẹlòmíì.+
Àmọ́ nínú lọ́hùn-ún, ó ti sú mi pátápátá!*
28 Torí ẹ sọ pé, ‘Báwo la ṣe ń ṣe inúnibíni sí i?’+
Nígbà tó jẹ́ pé èmi ni orísun ìṣòro náà.