Émọ́sì
3 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa yín, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì:
2 ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé tó wà láyé.+
Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ẹ jíhìn nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
3 Ǹjẹ́ àwọn méjì lè jọ rìn láìjẹ́ pé wọ́n ṣe àdéhùn?*
4 Ǹjẹ́ kìnnìún máa ké ramúramù nínú igbó láìjẹ́ pé ó ti rí ẹran tó fẹ́ pa?
Ǹjẹ́ ọmọ kìnnìún* máa kùn hùn-ùn láti ibi tó fara pa mọ́ sí láìjẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ nǹkan kan?
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ti dẹ pańpẹ́ náà?*
Ṣé pańpẹ́ lè ré lórí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan?
6 Tí èèyàn bá fun ìwo nínú ìlú, ǹjẹ́ àyà àwọn ará ìlú kò ní já?
Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú, ǹjẹ́ kì í ṣe Jèhófà ló fà á?
7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kò ní ṣe ohunkóhun
Láìjẹ́ pé ó ti fi àṣírí ọ̀rọ̀ náà* han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ wòlíì.+
8 Kìnnìún ti ké ramúramù!+ Ta ni kò ní bẹ̀rù?
Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kò ní sọ tẹ́lẹ̀?’+
9 ‘Ẹ kéde rẹ̀ lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Áṣídódì
Àti lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò nílẹ̀ Íjíbítì.
Ẹ sọ pé: “Ẹ kóra jọ sórí àwọn òkè Samáríà;+
Ẹ wo ìdàrúdàpọ̀ tó wà ní àárín rẹ̀
Àti jìbìtì tó wà nínú rẹ̀.+
10 Nítorí wọn kò mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,” ni Jèhófà wí,
“Àwọn tó ń mú ìwà ipá àti ìparun pọ̀ sí i nínú àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò.”’
11 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,
‘Ọ̀tá kan máa yí ilẹ̀ náà ká,+
Á sì mú kí agbára rẹ tán,
Ohun tó wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò ni wọ́n á sì kó lọ.’+
12 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,
‘Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń já ẹsẹ̀ méjì tàbí etí kan gbà kúrò lẹ́nu kìnnìún,
Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà,
Àwọn tó ń jókòó sórí ibùsùn rèǹtèrente àti sórí àga ìnàyìn tó rẹwà* ní Samáríà.’+
13 ‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún* ilé Jékọ́bù,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
14 ‘Ní ọjọ́ tí màá mú kí Ísírẹ́lì jíhìn nítorí ìdìtẹ̀* rẹ̀,+
Ni màá mú kí àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì pẹ̀lú jíhìn;+
A ó ṣẹ́ àwọn ìwo pẹpẹ náà, wọ́n á sì já bọ́ sílẹ̀.+
15 Màá wó ilé ìgbà òtútù àti ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lulẹ̀.’