Sáàmù
Sí olùdarí. Orin Dáfídì.
64 Gbọ́ ohùn mi Ọlọ́run, bí mo ṣe ń bẹ̀bẹ̀.+
Yọ mí nínú ìbẹ̀rù ọ̀tá.
2 Dáàbò bò mí lọ́wọ́ ohun tí àwọn ẹni ibi ń gbèrò ní ìkọ̀kọ̀,+
Lọ́wọ́ àwùjọ àwọn aṣebi.
3 Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà;
Wọ́n dojú ọ̀rọ̀ burúkú wọn kọni bí ọfà,
4 Kí wọ́n lè ta aláìlẹ́bi lọ́fà láti ibi tí wọ́n fara pa mọ́ sí;
Wọ́n ta á lọ́fà lójijì, láìbẹ̀rù.
5 Wọn ò jáwọ́ nínú èrò ibi wọn;*
Wọ́n sọ bí wọ́n ṣe máa dẹ pańpẹ́ wọn pa mọ́.
Wọ́n sọ pé: “Ta ló máa rí wọn?”+
6 Wọ́n ń wá ọ̀nà tuntun láti ṣe ohun tí kò tọ́;
Wọ́n ń hùmọ̀ ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn ní ìkọ̀kọ̀;+
Inú kálukú wọn jìn.
7 Àmọ́ Ọlọ́run yóò ta wọ́n lọ́fà;+
Ọfà yóò dọ́gbẹ́ sí wọn lára lójijì,
8 Ahọ́n àwọn fúnra wọn yóò mú kí wọ́n ṣubú;+
Gbogbo àwọn tó ń wò wọ́n yóò mi orí.
9 Nígbà náà, ẹ̀rù á ba gbogbo èèyàn,
Wọ́n á máa kéde ohun tí Ọlọ́run ti ṣe,
Wọ́n á sì lóye àwọn iṣẹ́ rẹ̀ jinlẹ̀.+