ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Ìjọba Rèhóbóámù (1-12)

      • Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin lọ sí Júdà (13-17)

      • Ìdílé Rèhóbóámù (18-23)

2 Kíróníkà 11:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àṣàyàn jagunjagun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 49:27; 2Kr 14:8
  • +1Ọb 12:21-24

2 Kíróníkà 11:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 12:15

2 Kíróníkà 11:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:31; 2Kr 10:15

2 Kíróníkà 11:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ odi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:19; Mt 2:1
  • +Emọ 1:1

2 Kíróníkà 11:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 28:18
  • +1Sa 22:1

2 Kíróníkà 11:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 18:1
  • +1Sa 23:14

2 Kíróníkà 11:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:9
  • +Joṣ 10:10; Jer 34:7

2 Kíróníkà 11:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:42, 48
  • +Joṣ 14:14, 15; 2Sa 2:1

2 Kíróníkà 11:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:2, 3
  • +1Ọb 12:31, 32

2 Kíróníkà 11:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 13:33
  • +Le 17:7
  • +1Ọb 12:26, 28

2 Kíróníkà 11:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:11; 1Kr 22:1; 2Kr 15:8, 9; 30:10, 11

2 Kíróníkà 11:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:6; 17:13

2 Kíróníkà 11:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 13:1; 18:33
  • +1Ọb 15:1; 2Kr 12:16; Mt 1:7

2 Kíróníkà 11:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:17

2 Kíróníkà 11:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fọ́n lára àwọn ọmọ rẹ̀ ká.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 11:5, 11

Àwọn míì

2 Kíró. 11:1Jẹ 49:27; 2Kr 14:8
2 Kíró. 11:11Ọb 12:21-24
2 Kíró. 11:22Kr 12:15
2 Kíró. 11:41Ọb 11:31; 2Kr 10:15
2 Kíró. 11:6Jẹ 35:19; Mt 2:1
2 Kíró. 11:6Emọ 1:1
2 Kíró. 11:72Kr 28:18
2 Kíró. 11:71Sa 22:1
2 Kíró. 11:81Kr 18:1
2 Kíró. 11:81Sa 23:14
2 Kíró. 11:92Kr 32:9
2 Kíró. 11:9Joṣ 10:10; Jer 34:7
2 Kíró. 11:10Joṣ 19:42, 48
2 Kíró. 11:10Joṣ 14:14, 15; 2Sa 2:1
2 Kíró. 11:14Nọ 35:2, 3
2 Kíró. 11:141Ọb 12:31, 32
2 Kíró. 11:151Ọb 13:33
2 Kíró. 11:15Le 17:7
2 Kíró. 11:151Ọb 12:26, 28
2 Kíró. 11:16Di 12:11; 1Kr 22:1; 2Kr 15:8, 9; 30:10, 11
2 Kíró. 11:181Sa 16:6; 17:13
2 Kíró. 11:202Sa 13:1; 18:33
2 Kíró. 11:201Ọb 15:1; 2Kr 12:16; Mt 1:7
2 Kíró. 11:21Di 17:17
2 Kíró. 11:232Kr 11:5, 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 11:1-23

Kíróníkà Kejì

11 Nígbà tí Rèhóbóámù dé Jerúsálẹ́mù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pe ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì+ jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) akọgun,* láti bá Ísírẹ́lì jà, kí wọ́n lè gba ìjọba pa dà fún Rèhóbóámù.+ 2 Ìgbà náà ni Jèhófà bá Ṣemáyà,+ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Sọ fún Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ọba Júdà àti gbogbo Ísírẹ́lì ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì pé, 4 ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lọ bá àwọn arákùnrin yín jà. Kí kálukú yín pa dà sí ilé rẹ̀, torí èmi ló mú kí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀.”’”+ Nítorí náà, wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ, wọ́n pa dà, wọn ò sì lọ bá Jèróbóámù jà.

5 Rèhóbóámù ń gbé Jerúsálẹ́mù, ó sì kọ́ àwọn ìlú olódi sí Júdà. 6 Ó tipa bẹ́ẹ̀ kọ́* Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ Étámì, Tékóà,+ 7 Bẹti-súrì, Sókò,+ Ádúlámù,+ 8 Gátì,+ Máréṣà, Sífù,+ 9 Ádóráímù,+ Lákíṣì, Ásékà,+ 10 Sórà, Áíjálónì+ àti Hébúrónì,+ àwọn ìlú olódi tó wà ní Júdà àti Bẹ́ńjámínì. 11 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí àwọn ibi olódi lágbára sí i, ó sì fi àwọn aláṣẹ sínú wọn, ó ń fún wọn ní oúnjẹ àti òróró àti wáìnì, 12 ó sì fún àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ní apata ńlá àti aṣóró; ó mú kí wọ́n lágbára gan-an. Ó sì ń ṣàkóso lórí Júdà àti Bẹ́ńjámínì nìṣó.

13 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì tó wà ní gbogbo Ísírẹ́lì dúró tì í, wọ́n ń jáde wá láti gbogbo ìpínlẹ̀ wọn. 14 Àwọn ọmọ Léfì fi àwọn ibi ìjẹko wọn àti ohun ìní wọn sílẹ̀,+ wọ́n wá sí Júdà àti Jerúsálẹ́mù, torí pé Jèróbóámù àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà fún Jèhófà.+ 15 Jèróbóámù wá yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga+ àti fún àwọn ẹ̀mí èṣù+ tó rí bí ewúrẹ́* àti fún àwọn ère ọmọ màlúù tí ó ṣe.+ 16 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n ti pinnu láti máa wá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tẹ̀ lé àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wá sí Jerúsálẹ́mù láti rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 17 Ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi kọ́wọ́ ti ìjọba Júdà, wọ́n sì ti Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì lẹ́yìn, wọ́n rìn ní ọ̀nà Dáfídì àti Sólómọ́nì fún ọdún mẹ́ta.

18 Nígbà náà, Rèhóbóámù fi Máhálátì ṣe aya, bàbá rẹ̀ ni Jérímótì ọmọ Dáfídì, ìyá rẹ̀ sì ni Ábíháílì ọmọ Élíábù+ ọmọ Jésè. 19 Nígbà tó yá, ó bí àwọn ọmọkùnrin fún un, àwọn ni: Jéúṣì, Ṣemaráyà àti Sáhámù. 20 Lẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù.+ Nígbà tó yá, ó bí Ábíjà,+ Átáì, Sísà àti Ṣẹ́lómítì fún un. 21 Rèhóbóámù nífẹ̀ẹ́ Máákà ọmọ ọmọ Ábúsálómù ju gbogbo àwọn ìyàwó rẹ̀ yòókù àti àwọn wáhàrì*+ rẹ̀ lọ. Ó ní ìyàwó méjìdínlógún (18) àti ọgọ́ta (60) wáhàrì, ó sì bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti ọgọ́ta (60) ọmọbìnrin. 22 Nítorí náà, Rèhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Máákà ṣe olórí àti aṣáájú láàárín àwọn arákùnrin rẹ̀, torí ó fẹ́ fi jọba. 23 Àmọ́, ó dá ọgbọ́n, ó rán lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ* sí gbogbo agbègbè Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú olódi,+ ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun tí wọ́n nílò, ó sì fẹ́ ìyàwó púpọ̀ fún wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́