ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́nẹ́sísì 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jẹ́nẹ́sísì

      • Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje (1-3)

      • Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé (4)

      • Ọkùnrin àti obìnrin nínú ọgbà Édẹ́nì (5-25)

        • Ọlọ́run fi erùpẹ̀ mọ ọkùnrin (7)

        • Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ (15-17)

        • Ọlọ́run dá obìnrin (18-25)

Jẹ́nẹ́sísì 2:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àti gbogbo ọmọ ogun wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:6; Sm 146:6

Jẹ́nẹ́sísì 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ohun tó ti ń dá.”

  • *

    Tàbí “gbogbo ohun tó ti ń dá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 31:17; Heb 4:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 56

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 22

    10/1/2001, ojú ìwé 30

    7/15/1998, ojú ìwé 14-16

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 45-46

Jẹ́nẹ́sísì 2:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2012, ojú ìwé 22

    7/15/2011, ojú ìwé 24-25

    10/1/2001, ojú ìwé 30

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 46-48, 189

Jẹ́nẹ́sísì 2:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Orúkọ yìí, יהוה (YHWH), ni a fi ń dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tó fara hàn. Wo Àfikún A4.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:18

Jẹ́nẹ́sísì 2:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/1998, ojú ìwé 9

Jẹ́nẹ́sísì 2:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.” Lédè Hébérù, neʹphesh, èyí tó túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:19; Sm 103:14; Onw 3:20
  • +Jẹ 7:22; Ais 42:5; Iṣe 17:25
  • +1Kọ 15:45, 47

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 4 2017 ojú ìwé 5-6

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2009, ojú ìwé 4

    9/1/2009, ojú ìwé 12-13

    4/1/1999, ojú ìwé 14-15

    10/1/1997, ojú ìwé 19

    9/1/1994, ojú ìwé 8

    Ìmọ̀, ojú ìwé 81

    Ayọ, ojú ìwé 113, 115

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 33-34

Jẹ́nẹ́sísì 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:15; 3:23
  • +Jẹ 1:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 3-4

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 33, 34-36

Jẹ́nẹ́sísì 2:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:22, 24; Ifi 2:7
  • +Jẹ 2:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1702

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2011, ojú ìwé 7-8

    4/15/1999, ojú ìwé 7-8

    Jí!,

    10/8/1998, ojú ìwé 7

    Ayọ, ojú ìwé 113

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 34-36

Jẹ́nẹ́sísì 2:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó sì di orí mẹ́rin.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2011, ojú ìwé 5-6

Jẹ́nẹ́sísì 2:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Tígírísì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:4
  • +Jẹ 10:8, 11
  • +Jẹ 15:18; Di 11:24

Jẹ́nẹ́sísì 2:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:28; 2:8; Sm 115:16

Jẹ́nẹ́sísì 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 2:8, 9; 3:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 42-43

    Ìmọ̀, ojú ìwé 57

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 38-39, 44-45

Jẹ́nẹ́sísì 2:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:19; Sm 146:4; Onw 9:5, 10; Isk 18:4; Ro 5:12; 1Kọ 15:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2019 ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2018, ojú ìwé 5-6

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2015, ojú ìwé 4

    9/15/2014, ojú ìwé 24-25

    1/1/2003, ojú ìwé 4

    1/15/2001, ojú ìwé 4-5

    3/1/1991, ojú ìwé 5-6

    Jí!,

    7/2006, ojú ìwé 28-29

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 42-43, 61-62

    Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ojú ìwé 8-9

    Nígbà Tí A Bá Kú, ojú ìwé 21

    Ìmọ̀, ojú ìwé 57-58

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 36-39, 44-45, 57-59

Jẹ́nẹ́sísì 2:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:8, 9; 1Ti 2:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    1/2014, ojú ìwé 15

    3/8/2005, ojú ìwé 10-11

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2012, ojú ìwé 25

    9/1/2012, ojú ìwé 4-5

    5/15/2011, ojú ìwé 8-9

    11/15/2000, ojú ìwé 24-25

    7/15/1995, ojú ìwé 10-11

    7/1/1991, ojú ìwé 9

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 34

    Ayọ, ojú ìwé 82

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 45

Jẹ́nẹ́sísì 2:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “alààyè ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 1:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2016, ojú ìwé 28

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 36

Jẹ́nẹ́sísì 2:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 27

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 36, 45

Jẹ́nẹ́sísì 2:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2011, ojú ìwé 7

    9/1/2009, ojú ìwé 13

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 41

Jẹ́nẹ́sísì 2:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mk 10:9; 1Ti 2:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2011, ojú ìwé 7

    9/1/2009, ojú ìwé 13

    1/1/2004, ojú ìwé 30

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 41

Jẹ́nẹ́sísì 2:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 11:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2004, ojú ìwé 30

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 41

Jẹ́nẹ́sísì 2:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wà pẹ̀lú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 2:16; Mt 19:5; Mk 10:7, 8; Ro 7:2; 1Kọ 6:16; Ef 5:31; Heb 13:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 42

    Jí!,

    No. 1 2021 ojú ìwé 4

    4/8/2005, ojú ìwé 27

    2/8/2002, ojú ìwé 6

    2/8/2001, ojú ìwé 12-13

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2017, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2016, ojú ìwé 8-9

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2011, ojú ìwé 13

    1/15/2011, ojú ìwé 14-16

    2/1/2010, ojú ìwé 27

    1/1/2004, ojú ìwé 30

    11/15/2000, ojú ìwé 25

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 23

    Ayọ, ojú ìwé 77-78

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 41-42

Jẹ́nẹ́sísì 2:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 42

Àwọn míì

Jẹ́n. 2:1Ne 9:6; Sm 146:6
Jẹ́n. 2:2Ẹk 31:17; Heb 4:4
Jẹ́n. 2:4Ais 45:18
Jẹ́n. 2:7Jẹ 3:19; Sm 103:14; Onw 3:20
Jẹ́n. 2:7Jẹ 7:22; Ais 42:5; Iṣe 17:25
Jẹ́n. 2:71Kọ 15:45, 47
Jẹ́n. 2:8Jẹ 2:15; 3:23
Jẹ́n. 2:8Jẹ 1:26
Jẹ́n. 2:9Jẹ 3:22, 24; Ifi 2:7
Jẹ́n. 2:9Jẹ 2:17
Jẹ́n. 2:14Da 10:4
Jẹ́n. 2:14Jẹ 10:8, 11
Jẹ́n. 2:14Jẹ 15:18; Di 11:24
Jẹ́n. 2:15Jẹ 1:28; 2:8; Sm 115:16
Jẹ́n. 2:16Jẹ 2:8, 9; 3:2
Jẹ́n. 2:17Jẹ 3:19; Sm 146:4; Onw 9:5, 10; Isk 18:4; Ro 5:12; 1Kọ 15:22
Jẹ́n. 2:181Kọ 11:8, 9; 1Ti 2:13
Jẹ́n. 2:19Jẹ 1:26
Jẹ́n. 2:22Mk 10:9; 1Ti 2:13
Jẹ́n. 2:231Kọ 11:8
Jẹ́n. 2:24Mal 2:16; Mt 19:5; Mk 10:7, 8; Ro 7:2; 1Kọ 6:16; Ef 5:31; Heb 13:4
Jẹ́n. 2:25Jẹ 3:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jẹ́nẹ́sísì 2:1-25

Jẹ́nẹ́sísì

2 Bí Ọlọ́run ṣe parí dídá ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tó wà nínú wọn* nìyẹn.+ 2 Nígbà tó fi máa di ọjọ́ keje, Ọlọ́run ti parí iṣẹ́ tó ti ń ṣe,* ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ tó ti ń ṣe.*+ 3 Ọlọ́run wá bù kún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, torí ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi lẹ́yìn gbogbo ohun tó ti dá, ìyẹn gbogbo ohun tó ní lọ́kàn.

4 Ìtàn ọ̀run àti ayé nìyí, ní àkókò tí Ọlọ́run dá wọn, ní ọjọ́ tí Jèhófà* Ọlọ́run dá ayé àti ọ̀run.+

5 Kò sí igbó kankan ní ayé nígbà yẹn, ewéko kankan ò sì tíì hù, torí Jèhófà Ọlọ́run ò tíì rọ òjò sórí ilẹ̀, kò sì sí ẹnì kankan tó máa ro ilẹ̀. 6 Àmọ́ omi máa ń sun látinú ilẹ̀, á sì rin gbogbo ilẹ̀.

7 Jèhófà Ọlọ́run fi erùpẹ̀+ ilẹ̀ mọ ọkùnrin, ó mí èémí ìyè+ sí ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì di alààyè.*+ 8 Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì,+ ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá+ síbẹ̀. 9 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí gbogbo igi tó dùn-ún wò, tó sì dára fún oúnjẹ hù látinú ilẹ̀, ó sì mú kí igi ìyè+ hù ní àárín ọgbà náà pẹ̀lú igi ìmọ̀ rere àti búburú.+

10 Odò kan ń ṣàn jáde láti Édẹ́nì, tí omi rẹ̀ ń rin ọgbà náà, ó sì pín sí odò mẹ́rin* níbẹ̀. 11 Orúkọ odò àkọ́kọ́ ni Píṣónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà wà. 12 Wúrà ilẹ̀ náà dára. Gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù àti òkúta ónísì tún wà níbẹ̀. 13 Orúkọ odò kejì ni Gíhónì; òun ló yí gbogbo ilẹ̀ Kúṣì ká. 14 Orúkọ odò kẹta ni Hídẹ́kẹ́lì;*+ òun ló ṣàn lọ sí ìlà oòrùn Ásíríà.+ Odò kẹrin sì ni Yúfírétì.+

15 Jèhófà Ọlọ́run mú ọkùnrin náà, ó sì fi sínú ọgbà Édẹ́nì kó lè máa ro ó, kó sì máa tọ́jú rẹ̀.+ 16 Jèhófà Ọlọ́run tún pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé: “O lè jẹ èso gbogbo igi tó wà nínú ọgbà yìí ní àjẹtẹ́rùn.+ 17 Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú, torí ó dájú pé ọjọ́ tí o bá jẹ ẹ́ lo máa kú.”+

18 Jèhófà Ọlọ́run wá sọ pé: “Kò dáa kí ọkùnrin náà máa dá wà. Màá ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀.”+ 19 Jèhófà Ọlọ́run dá gbogbo ẹranko látinú ilẹ̀ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sọ́dọ̀ ọkùnrin náà láti wo orúkọ tó máa sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn; orúkọ tí ọkùnrin náà bá sì sọ ohun alààyè* kọ̀ọ̀kan ni wọ́n ń jẹ́.+ 20 Ọkùnrin náà wá sọ gbogbo ẹran ọ̀sìn lórúkọ àti gbogbo ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run pẹ̀lú gbogbo ẹranko, àmọ́ kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan fún ọkùnrin náà tó máa jẹ́ ẹnì kejì rẹ̀. 21 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sun oorun àsùnwọra. Nígbà tó ń sùn, ó yọ ọ̀kan lára egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran bo ibẹ̀. 22 Jèhófà Ọlọ́run wá fi egungun ìhà tó yọ lára ọkùnrin náà mọ obìnrin, ó sì mú un wá fún ọkùnrin náà.+

23 Ni ọkùnrin náà bá sọ pé:

“Èyí gan-an ni egungun látinú egungun mi

Àti ẹran ara látinú ẹran ara mi.

Obìnrin ni yóò máa jẹ́,

Torí ara ọkùnrin ló ti wá.”+

24 Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin á ṣe fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́* ìyàwó rẹ̀, wọ́n á sì di ara kan.+ 25 Ọkùnrin náà àti ìyàwó rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò;+ síbẹ̀ ojú ò tì wọ́n.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́