ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Jèhóṣáfátì dara pọ̀ mọ́ Áhábù (1-11)

      • Mikáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọn ò ní ṣẹ́gun (12-27)

      • Wọ́n pa Áhábù ní Ramoti-gílíádì (28-34)

2 Kíróníkà 18:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 17:5
  • +1Ọb 16:28, 33; 21:25

2 Kíróníkà 18:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi ọ̀pọ̀ àgùntàn àti màlúù rúbọ.”

  • *

    Tàbí “bẹ̀ ẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:2-4; 2Kr 19:2
  • +Di 4:41-43; 1Kr 6:77, 80

2 Kíróníkà 18:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 2:1; 1Ọb 22:5, 6

2 Kíróníkà 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 3:11
  • +1Ọb 22:7, 8

2 Kíróníkà 18:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:4; 19:9, 10
  • +Jer 38:4

2 Kíróníkà 18:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:9-12

2 Kíróníkà 18:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ti.”

2 Kíróníkà 18:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 3:5

2 Kíróníkà 18:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:9, 10
  • +1Ọb 22:13-17

2 Kíróníkà 18:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:28; Iṣe 20:27

2 Kíróníkà 18:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:14, 17; Nọ 27:16, 17

2 Kíróníkà 18:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:18

2 Kíróníkà 18:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:1; Isk 1:26; Ifi 20:11
  • +Job 1:6; Da 7:9, 10
  • +1Ọb 22:19-23

2 Kíróníkà 18:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “áńgẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 104:4

2 Kíróníkà 18:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 19:14; Isk 14:9

2 Kíróníkà 18:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 18:10
  • +2Kr 18:7
  • +Jer 20:2; Mk 14:65
  • +1Ọb 22:24-28

2 Kíróníkà 18:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 16:10; Iṣe 5:18

2 Kíróníkà 18:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 16:29

2 Kíróníkà 18:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 20:8; 1Ọb 22:29-33; 2Kr 18:2

2 Kíróníkà 18:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:10; 2Kr 13:14

2 Kíróníkà 18:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ta ọfà rẹ̀ láìfojú sun nǹkan kan.”

  • *

    Ní Héb., “nínú ibùdó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:34, 35

2 Kíróníkà 18:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 18:22

Àwọn míì

2 Kíró. 18:12Kr 17:5
2 Kíró. 18:11Ọb 16:28, 33; 21:25
2 Kíró. 18:21Ọb 22:2-4; 2Kr 19:2
2 Kíró. 18:2Di 4:41-43; 1Kr 6:77, 80
2 Kíró. 18:42Sa 2:1; 1Ọb 22:5, 6
2 Kíró. 18:62Ọb 3:11
2 Kíró. 18:61Ọb 22:7, 8
2 Kíró. 18:71Ọb 18:4; 19:9, 10
2 Kíró. 18:7Jer 38:4
2 Kíró. 18:81Ọb 22:9-12
2 Kíró. 18:11Mik 3:5
2 Kíró. 18:12Ais 30:9, 10
2 Kíró. 18:121Ọb 22:13-17
2 Kíró. 18:13Jer 23:28; Iṣe 20:27
2 Kíró. 18:16Le 26:14, 17; Nọ 27:16, 17
2 Kíró. 18:171Ọb 22:18
2 Kíró. 18:18Ais 6:1; Isk 1:26; Ifi 20:11
2 Kíró. 18:18Job 1:6; Da 7:9, 10
2 Kíró. 18:181Ọb 22:19-23
2 Kíró. 18:20Sm 104:4
2 Kíró. 18:22Ais 19:14; Isk 14:9
2 Kíró. 18:232Kr 18:10
2 Kíró. 18:232Kr 18:7
2 Kíró. 18:23Jer 20:2; Mk 14:65
2 Kíró. 18:231Ọb 22:24-28
2 Kíró. 18:262Kr 16:10; Iṣe 5:18
2 Kíró. 18:27Nọ 16:29
2 Kíró. 18:28Joṣ 20:8; 1Ọb 22:29-33; 2Kr 18:2
2 Kíró. 18:31Ẹk 14:10; 2Kr 13:14
2 Kíró. 18:331Ọb 22:34, 35
2 Kíró. 18:342Kr 18:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 18:1-34

Kíróníkà Kejì

18 Jèhóṣáfátì ní ọrọ̀ àti ògo tó pọ̀ gan-an,+ àmọ́ ó bá Áhábù+ dána. 2 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ó lọ sọ́dọ̀ Áhábù ní Samáríà,+ Áhábù sì pa ọ̀pọ̀ àgùntàn àti màlúù* fún òun àti àwọn tó bá a wá. Ó wá rọ̀ ọ́* pé kó tẹ̀ lé òun lọ gbéjà ko Ramoti-gílíádì.+ 3 Áhábù ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì ọba Júdà pé: “Ṣé wàá tẹ̀ lé mi lọ sí Ramoti-gílíádì?” Ó dá a lóhùn pé: “Ìkan náà ni èmi àti ìwọ, ìkan náà sì ni àwọn èèyàn mi àti àwọn èèyàn rẹ, a ó tì ọ́ lẹ́yìn nínú ogun náà.”

4 Àmọ́, Jèhóṣáfátì sọ fún ọba Ísírẹ́lì pé: “Jọ̀wọ́, kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà.”+ 5 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì kó àwọn wòlíì jọ, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọkùnrin, ó sì bi wọ́n pé: “Ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà tàbí ká má lọ?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Lọ, Ọlọ́run tòótọ́ yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”

6 Jèhóṣáfátì wá sọ pé: “Ṣé kò sí wòlíì Jèhófà níbí ni?+ Ẹ jẹ́ ká tún wádìí lọ́dọ̀ rẹ̀.”+ 7 Ni ọba Ísírẹ́lì bá sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ọkùnrin kan ṣì wà+ tí a lè ní kó bá wa wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà; ṣùgbọ́n mo kórìíra rẹ̀, nítorí kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi ibi ṣáá.+ Mikáyà ni orúkọ rẹ̀, ọmọ Ímílà ni.” Síbẹ̀, Jèhóṣáfátì sọ pé: “Kí ọba má sọ bẹ́ẹ̀.”

8 Torí náà, ọba Ísírẹ́lì pe òṣìṣẹ́ ààfin kan, ó sì sọ fún un pé: “Lọ pe Mikáyà ọmọ Ímílà wá kíákíá.”+ 9 Lásìkò náà, ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà wà ní ìjókòó, kálukú lórí ìtẹ́ rẹ̀, wọ́n wọ ẹ̀wù oyè; wọ́n jókòó sí ibi ìpakà tó wà ní àtiwọ ẹnubodè Samáríà, gbogbo àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ níwájú wọn. 10 Ìgbà náà ni Sedekáyà ọmọ Kénáánà ṣe àwọn ìwo irin fún ara rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ohun tí o máa fi kan* àwọn ará Síríà pa nìyí títí wàá fi pa wọ́n run.’” 11 Ohun kan náà ni gbogbo àwọn wòlíì tó kù ń sọ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Lọ sí Ramoti-gílíádì, wàá ṣẹ́gun;+ Jèhófà yóò sì fi í lé ọba lọ́wọ́.”

12 Òjíṣẹ́ tó lọ pe Mikáyà sọ fún un pé: “Wò ó! Ohun rere ni àwọn wòlíì ń sọ fún ọba, ọ̀rọ̀ wọn kò ta kora. Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yàtọ̀ sí tiwọn,+ kí o sì sọ ohun rere.”+ 13 Ṣùgbọ́n Mikáyà sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè, ohun tí Ọlọ́run mi bá sọ fún mi ni màá sọ.”+ 14 Lẹ́yìn náà, ó wọlé sọ́dọ̀ ọba, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Mikáyà, ṣé ká lọ bá Ramoti-gílíádì jà àbí ká má lọ?” Lójú ẹsẹ̀, ó fèsì pé: “Lọ, wàá ṣẹ́gun; a ó sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.” 15 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ìgbà mélòó ni màá ní kí o búra pé òótọ́ lo máa sọ fún mi ní orúkọ Jèhófà?” 16 Nítorí náà, ó sọ pé: “Mo rí i tí gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tú ká lórí àwọn òkè, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.+ Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn yìí kò ní ọ̀gá. Kí kálukú pa dà sí ilé rẹ̀ ní àlàáfíà.’”

17 Nígbà náà, ọba Ísírẹ́lì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Ǹjẹ́ mi ò sọ fún ọ pé, ‘Kò ní sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi, àfi ibi’?”+

18 Mikáyà bá sọ pé: “Nítorí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀,+ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run+ sì dúró lápá ọ̀tún rẹ̀ àti lápá òsì rẹ̀.+ 19 Jèhófà sì sọ pé, ‘Ta ló máa tan Áhábù ọba Ísírẹ́lì, kí ó lè lọ kí ó sì kú ní Ramoti-gílíádì?’ Ẹni tibí ń sọ báyìí, ẹni tọ̀hún sì ń sọ nǹkan míì. 20 Ni ẹ̀mí*+ kan bá jáde wá, ó dúró níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé, ‘Màá tàn án.’ Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Báwo lo ṣe máa ṣe é?’ 21 Ó dáhùn pé, ‘Màá jáde lọ, màá sì di ẹ̀mí tó ń tanni jẹ ní ẹnu gbogbo wòlíì rẹ̀.’ Torí náà, ó sọ pé, ‘O máa tàn án, kódà, wàá ṣe àṣeyọrí. Lọ, kí o sì ṣe bẹ́ẹ̀.’ 22 Wò ó, Jèhófà ti fi ẹ̀mí tó ń tanni jẹ sí ẹnu àwọn wòlíì rẹ yìí,+ àmọ́ àjálù ni Jèhófà sọ pé ó máa bá ọ.”

23 Sedekáyà+ ọmọ Kénáánà wá sún mọ́ tòsí, ó sì gbá Mikáyà  + létí,+ ó sọ pé: “Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Jèhófà gbà kúrò lára mi tó fi wá bá ọ sọ̀rọ̀?”+ 24 Mikáyà dá a lóhùn pé: “Wò ó! Wàá rí ọ̀nà tó gbà lọ́jọ́ tí o máa lọ sá pa mọ́ sí yàrá inú lọ́hùn-ún.” 25 Ìgbà náà ni ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ẹ mú Mikáyà, kí ẹ sì fà á lé ọwọ́ Ámọ́nì olórí ìlú àti Jóáṣì ọmọ ọba. 26 Ẹ sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí ọba sọ nìyí: “Ẹ fi ọ̀gbẹ́ni yìí sínú ẹ̀wọ̀n,+ kí ẹ sì máa fún un ní oúnjẹ díẹ̀ àti omi díẹ̀, títí màá fi dé ní àlàáfíà.”’” 27 Àmọ́ Mikáyà sọ pé: “Tí o bá pa dà ní àlàáfíà, á jẹ́ pé Jèhófà kò bá mi sọ̀rọ̀.”+ Ó tún sọ pé: “Ẹ fọkàn sí i o, gbogbo ẹ̀yin èèyàn.”

28 Ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì ọba Júdà bá lọ sí Ramoti-gílíádì.+ 29 Ọba Ísírẹ́lì sì sọ fún Jèhóṣáfátì pé: “Màá para dà, màá sì lọ sójú ogun, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, wọ ẹ̀wù oyè rẹ.” Torí náà, ọba Ísírẹ́lì para dà, wọ́n sì bọ́ sójú ogun. 30 Ọba Síríà ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe bá ẹnikẹ́ni jà, ì báà jẹ́ ẹni kékeré tàbí ẹni ńlá, àfi ọba Ísírẹ́lì.” 31 Gbàrà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí Jèhóṣáfátì, wọ́n sọ lọ́kàn ara wọn pé: “Ọba Ísírẹ́lì nìyí.” Nítorí náà, wọ́n yíjú sí i láti bá a jà; Jèhóṣáfátì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́,+ Jèhófà ràn án lọ́wọ́, Ọlọ́run sì darí wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 32 Nígbà tí àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin rí i pé kì í ṣe ọba Ísírẹ́lì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n pa dà lẹ́yìn rẹ̀.

33 Àmọ́, ọkùnrin kan ṣàdédé ta ọfà rẹ̀,* ó sì ba ọba Ísírẹ́lì láàárín ibi tí ẹ̀wù irin rẹ̀ ti so pọ̀. Torí náà, ọba sọ fún ẹni tó ń wa kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ pé: “Yí pa dà, kí o sì gbé mi jáde kúrò lójú ogun,* nítorí mo ti fara gbọgbẹ́ gan-an.”+ 34 Ìjà náà le gan-an jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, kódà wọ́n ní láti gbé ọba Ísírẹ́lì nàró nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ará Síríà jà títí di ìrọ̀lẹ́; ó sì kú nígbà tí oòrùn wọ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́