ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Òpin ti dé (1-27)

        • Àjálù tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (5)

        • Wọ́n ju owó sí ojú ọ̀nà (19)

        • Wọ́n á sọ tẹ́ńpìlì di aláìmọ́ (22)

Ìsíkíẹ́lì 7:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 68, 70

Ìsíkíẹ́lì 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 5:11
  • +Jer 16:18; Isk 16:43
  • +Isk 6:13

Ìsíkíẹ́lì 7:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:12; Da 9:12

Ìsíkíẹ́lì 7:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “jí.”

Ìsíkíẹ́lì 7:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2007, ojú ìwé 11

Ìsíkíẹ́lì 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 34:21
  • +Jer 7:20; Isk 5:13

Ìsíkíẹ́lì 7:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 13:14
  • +Ais 66:6; Isk 33:29

Ìsíkíẹ́lì 7:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Òdòdó ẹ̀yẹ.”

  • *

    Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 66

Ìsíkíẹ́lì 7:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 59:6; Jer 6:7; Mik 6:12

Ìsíkíẹ́lì 7:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé, àwọn tó ń rà àti àwọn tó ń tà kò ní rí àǹfààní kankan, torí gbogbo wọn ló máa pa run.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:18

Ìsíkíẹ́lì 7:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “torí àṣìṣe rẹ̀.”

Ìsíkíẹ́lì 7:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:5
  • +Jer 7:20; 12:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 68, 69-70

Ìsíkíẹ́lì 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:25
  • +Jer 14:18; Isk 5:12

Ìsíkíẹ́lì 7:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 59:11

Ìsíkíẹ́lì 7:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé, ìbẹ̀rù á mú kí wọ́n máa tọ̀ sára.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 21:7

Ìsíkíẹ́lì 7:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

  • *

    Ní Héb., “jìnnìjìnnì sì bò wọ́n.”

  • *

    Ìyẹn ni pé, wọ́n á fá orí wọn torí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 3:24
  • +Ais 22:12

Ìsíkíẹ́lì 7:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wọn.”

  • *

    Ìyẹn, fàdákà àti wúrà wọn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:4; Sef 1:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 69-70

Ìsíkíẹ́lì 7:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àwọn ohun tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà wọn ṣe.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:1, 7; Jer 7:30

Ìsíkíẹ́lì 7:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, wúrà àti fàdákà wọn tí wọ́n fi ṣe ère.

Ìsíkíẹ́lì 7:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó jọ pé ibi mímọ́ Jèhófà ní inú lọ́hùn-ún ló ń sọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 18:17
  • +2Kr 36:19; Ida 1:10

Ìsíkíẹ́lì 7:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tí wọ́n á fi kó wọn lẹ́rú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:6, 7; Ida 3:7
  • +2Ọb 21:16; 24:3, 4; Jer 2:34; Isk 9:9
  • +Ais 59:6; Mik 2:2

Ìsíkíẹ́lì 7:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:48-51; Isk 21:31; Hab 1:6
  • +Jer 6:12; Ida 5:2
  • +Isk 21:2

Ìsíkíẹ́lì 7:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:21; Jer 8:15

Ìsíkíẹ́lì 7:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:1, 2; 37:17
  • +Sm 74:9; Ida 2:9; Isk 20:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 66, 70

Ìsíkíẹ́lì 7:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìrẹ̀wẹ̀sì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 52:10
  • +Isk 6:13

Àwọn míì

Ìsík. 7:4Isk 5:11
Ìsík. 7:4Jer 16:18; Isk 16:43
Ìsík. 7:4Isk 6:13
Ìsík. 7:52Ọb 21:12; Da 9:12
Ìsík. 7:7Sef 1:14
Ìsík. 7:82Kr 34:21
Ìsík. 7:8Jer 7:20; Isk 5:13
Ìsík. 7:9Jer 13:14
Ìsík. 7:9Ais 66:6; Isk 33:29
Ìsík. 7:10Sef 1:14
Ìsík. 7:11Ais 59:6; Jer 6:7; Mik 6:12
Ìsík. 7:12Sef 1:18
Ìsík. 7:14Jer 4:5
Ìsík. 7:14Jer 7:20; 12:12
Ìsík. 7:15Le 26:25
Ìsík. 7:15Jer 14:18; Isk 5:12
Ìsík. 7:16Ais 59:11
Ìsík. 7:17Isk 21:7
Ìsík. 7:18Ais 3:24
Ìsík. 7:18Ais 22:12
Ìsík. 7:19Owe 11:4; Sef 1:18
Ìsík. 7:202Ọb 21:1, 7; Jer 7:30
Ìsík. 7:22Jer 18:17
Ìsík. 7:222Kr 36:19; Ida 1:10
Ìsík. 7:23Jer 39:6, 7; Ida 3:7
Ìsík. 7:232Ọb 21:16; 24:3, 4; Jer 2:34; Isk 9:9
Ìsík. 7:23Ais 59:6; Mik 2:2
Ìsík. 7:24Di 28:48-51; Isk 21:31; Hab 1:6
Ìsík. 7:24Jer 6:12; Ida 5:2
Ìsík. 7:24Isk 21:2
Ìsík. 7:25Ais 57:21; Jer 8:15
Ìsík. 7:26Jer 21:1, 2; 37:17
Ìsík. 7:26Sm 74:9; Ida 2:9; Isk 20:3
Ìsík. 7:27Jer 52:10
Ìsík. 7:27Isk 6:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 7:1-27

Ìsíkíẹ́lì

7 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìyí: ‘Òpin! Òpin ti dé bá igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà. 3 Òpin ti dé bá yín báyìí, màá bínú sí yín. Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. 4 Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín,+ torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san. Ẹ ó jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+

5 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Wò ó! Àjálù, àjálù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ń bọ̀.+ 6 Òpin ń bọ̀; òpin yóò dé; yóò dé* bá yín lójijì. Wò ó! Ó ń bọ̀. 7 Ó* ti dé bá yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ náà. Àkókò ń bọ̀, ọjọ́ náà sún mọ́lé.+ Gbogbo nǹkan dà rú, ariwo ayọ̀ kò sì dún lórí àwọn òkè.

8 “‘Láìpẹ́, inú mi á ru sí yín,+ màá bínú sí yín gidigidi.+ Màá fi iṣẹ́ ọwọ́ yín dá yín lẹ́jọ́, màá sì pè yín wá jíhìn torí gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. 9 Mi ò ní ṣàánú yín; mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ Màá fi ìwà yín san yín lẹ́san, ẹ ó sì jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe. Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ló ń fìyà jẹ yín.+

10 “‘Wò ó, ọjọ́ náà! Wò ó, ó ń bọ̀!+ Ó* ti dé bá yín; ọ̀pá ti yọ ìtànná, ìgbéraga* sì ti rúwé. 11 Ìwà ipá ti hù, ó sì ti di ọ̀pá ìwà burúkú.+ Wọn ò ní yè bọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ọrọ̀ wọn, àwọn èèyàn àti òkìkí wọn kò sì ní yè bọ́. 12 Àkókò á tó, ọjọ́ náà á dé. Kí ẹni tó ń ra nǹkan má ṣe yọ̀, kí ẹni tó sì ń ta nǹkan má ṣe ṣọ̀fọ̀, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.*+ 13 Tí ẹni tó ta nǹkan bá tiẹ̀ yè é, kò ní pa dà sí ìdí ohun tó tà, torí ìran náà kan gbogbo wọn. Kò sẹ́ni tó máa pa dà, kò sì sẹ́ni tó máa gba ara rẹ̀ là torí àṣìṣe òun fúnra rẹ̀.*

14 “‘Wọ́n ti fun kàkàkí,+ gbogbo èèyàn sì ti gbára dì, àmọ́ kò sẹ́ni tó ń lọ sí ojú ogun, torí pé mo bínú sí gbogbo wọn.+ 15 Idà wà níta,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú. Idà ni yóò pa ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa run àwọn tó bá wà nínú ìlú.+ 16 Àwọn tó bá jàjà bọ́ yóò sá lọ sórí àwọn òkè, kálukú wọn á sì ké tẹ̀dùntẹ̀dùn torí àṣìṣe rẹ̀ bí àwọn àdàbà inú àfonífojì.+ 17 Gbogbo ọwọ́ wọn á rọ jọwọrọ, omi á sì máa ro tótó ní orúnkún wọn.*+ 18 Wọ́n ti wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+ jìnnìjìnnì sì bá wọn.* Ojú á ti gbogbo wọn, orí gbogbo wọn á sì pá.*+

19 “‘Wọ́n á ju fàdákà wọn sí ojú ọ̀nà, wúrà wọn á sì di ohun ìríra lójú wọn. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.+ Kò ní tẹ́ wọn* lọ́rùn, wọn ò sì ní yó, torí ó* ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó ń mú kí wọ́n ṣe àṣìṣe. 20 Wọ́n ń fi ẹwà àwọn ohun ọ̀ṣọ́ wọn yangàn, wọ́n sì fi wọ́n* ṣe àwọn ère wọn tó ń ríni lára, àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn.+ Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kó di ohun ìríra lójú wọn. 21 Màá mú kí àwọn àjèjì kó wọn, màá sì mú kí àwọn ẹni burúkú inú ayé kó wọn* bí ẹrù ogun, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́.

22 “‘Èmi yóò yí ojú mi kúrò lọ́dọ̀ wọn,+ wọ́n á sì sọ ibi ìṣúra* mi di aláìmọ́, àwọn olè á wọ ibẹ̀, wọ́n á sì sọ ọ́ di aláìmọ́.+

23 “‘Ṣe ẹ̀wọ̀n,*+ torí wọ́n ń fi ìdájọ́ ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ ìwà ipá sì kún ìlú náà.+ 24 Màá mú orílẹ̀-èdè tó burú jù wá,+ wọ́n á sì gba àwọn ilé wọn,+ màá fòpin sí ìgbéraga àwọn alágbára, àwọn ibi mímọ́ wọn á sì di aláìmọ́.+ 25 Nígbà tí wọ́n bá ń jẹ̀rora, wọ́n á wá àlàáfíà àmọ́ wọn kò ní rí i.+ 26 Àjálù á ré lu àjálù, wọ́n á gbọ́ ìròyìn kan tẹ̀ lé òmíràn, àwọn èèyàn á wá ìran lọ sọ́dọ̀ wòlíì,+ àmọ́ òfin* yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àlùfáà, ìmọ̀ràn ò sì ní sí lẹ́nu àwọn àgbààgbà.+ 27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,+ ìbànújẹ́* máa bá àwọn ìjòyè, ìbẹ̀rù yóò sì mú kí ọwọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa gbọ̀n. Ìwà wọn ni màá fi san wọ́n lẹ́san, èmi yóò sì dá wọn lẹ́jọ́ bí wọ́n ṣe dá àwọn míì lẹ́jọ́. Wọ́n á sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́