ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀ (1-5)

      • Kí wọ́n máa ka ẹ̀mí sí pàtàkì (6-9)

      • Kí wọ́n máa gba tàwọn aláìní rò (10-18)

      • Òfin nípa pípèéṣẹ́ (19-22)

Diutarónómì 24:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 5:31, 32; Mk 10:4, 11
  • +Mal 2:16; Mt 1:19; 19:3-8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2018, ojú ìwé 11

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2016, ojú ìwé 10-11

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 222

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2008, ojú ìwé 25

    8/15/1993, ojú ìwé 4-5

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 104-105

Diutarónómì 24:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:7

Diutarónómì 24:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ̀ ọ́.”

Diutarónómì 24:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 20:7; Owe 5:18; Onw 9:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 24:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìdógò.”

  • *

    Tàbí “torí ẹ̀mí onítọ̀hún; torí ọkàn onítọ̀hún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:26, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2014, ojú ìwé 7

    9/15/2004, ojú ìwé 26

Diutarónómì 24:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:28; 40:15
  • +Ẹk 21:16
  • +Di 19:18, 19; 21:20, 21

Diutarónómì 24:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ẹ̀tẹ̀” ní ìtumọ̀ tó pọ̀, ó lè túmọ̀ sí oríṣiríṣi àrùn tó máa ń wà ní awọ ara, tó sì lè ran ẹlòmíì. Ó tún lè jẹ́ àwọn àrùn kan tó máa ń wà lára aṣọ tàbí lára ilé.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 13:2, 15; Mk 1:44; Lk 17:14

Diutarónómì 24:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 12:10, 15

Diutarónómì 24:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:7, 8; Owe 3:27

Diutarónómì 24:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 24:9, 10

Diutarónómì 24:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:26, 27

Diutarónómì 24:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:39, 43; Owe 14:31

Diutarónómì 24:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:13; Jer 22:13; Mt 20:8
  • +Owe 22:22, 23; Jem 5:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2018, ojú ìwé 32

Diutarónómì 24:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 25:3, 4
  • +Isk 18:20

Diutarónómì 24:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìlóbìí.”

  • *

    Tàbí “ìdógò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:21, 22
  • +Ẹk 22:26, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2019, ojú ìwé 24-25

Diutarónómì 24:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:15

Diutarónómì 24:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:9; 23:22; Rut 2:16; Sm 41:1
  • +Di 15:7, 10; Owe 11:24; 19:17; Lk 6:38; 2Kọ 9:6; 1Jo 3:17

Diutarónómì 24:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:10; Di 26:13

Àwọn míì

Diu. 24:1Mt 5:31, 32; Mk 10:4, 11
Diu. 24:1Mal 2:16; Mt 1:19; 19:3-8
Diu. 24:2Le 21:7
Diu. 24:5Di 20:7; Owe 5:18; Onw 9:9
Diu. 24:6Ẹk 22:26, 27
Diu. 24:7Jẹ 37:28; 40:15
Diu. 24:7Ẹk 21:16
Diu. 24:7Di 19:18, 19; 21:20, 21
Diu. 24:8Le 13:2, 15; Mk 1:44; Lk 17:14
Diu. 24:9Nọ 12:10, 15
Diu. 24:10Di 15:7, 8; Owe 3:27
Diu. 24:12Job 24:9, 10
Diu. 24:13Ẹk 22:26, 27
Diu. 24:14Le 25:39, 43; Owe 14:31
Diu. 24:15Le 19:13; Jer 22:13; Mt 20:8
Diu. 24:15Owe 22:22, 23; Jem 5:4
Diu. 24:162Kr 25:3, 4
Diu. 24:16Isk 18:20
Diu. 24:17Ẹk 22:21, 22
Diu. 24:17Ẹk 22:26, 27
Diu. 24:18Di 5:15
Diu. 24:19Le 19:9; 23:22; Rut 2:16; Sm 41:1
Diu. 24:19Di 15:7, 10; Owe 11:24; 19:17; Lk 6:38; 2Kọ 9:6; 1Jo 3:17
Diu. 24:20Le 19:10; Di 26:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 24:1-22

Diutarónómì

24 “Tí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, àmọ́ tí obìnrin náà ò tẹ́ ẹ lọ́rùn torí ó rí ohun kan tí kò dáa nípa rẹ̀, kó kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un,+ kó fi lé e lọ́wọ́, kó sì ní kó kúrò ní ilé òun.+ 2 Tí obìnrin náà bá ti kúrò ní ilé rẹ̀, ó lè lọ fẹ́ ọkùnrin míì.+ 3 Tí ọkùnrin kejì bá kórìíra rẹ̀,* tó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tó fi lé e lọ́wọ́, tó sì ní kó kúrò ní ilé òun tàbí tí ọkùnrin kejì tó fẹ́ ẹ bá kú, 4 ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ tó lé e kúrò nílé ò ní lè gbà á pa dà mọ́ láti fi ṣe aya lẹ́yìn tó ti di aláìmọ́, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà. O ò gbọ́dọ̀ mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.

5 “Tí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, kò gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ yan àwọn iṣẹ́ míì fún un. Kó wà lómìnira fún ọdún kan, kó sì dúró sílé kó lè máa múnú ìyàwó rẹ̀ dùn.+

6 “Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ gba ọlọ tàbí ọmọ ọlọ láti fi ṣe ìdúró,*+ torí ohun tó ń gbé ẹ̀mí onítọ̀hún ró* ló fẹ́ gbà láti fi ṣe ìdúró yẹn.

7 “Tí ẹ bá rí ẹnì kan tó jí ọ̀kan* lára àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì gbé, tó ti fìyà jẹ ẹ́, tó sì ti tà á,+ ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó jí èèyàn gbé náà.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+

8 “Tí àrùn ẹ̀tẹ̀* bá yọ, kí ẹ rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì bá ní kí ẹ ṣe.+ Kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. 9 Ẹ rántí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà, nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì.+

10 “Tí o bá yá ọmọnìkejì rẹ ní ohunkóhun,+ o ò gbọ́dọ̀ wọ inú ilé lọ bá a láti gba ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró. 11 Ìta ni kí o dúró sí, kí ẹni tí o yá ní nǹkan mú ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró wá bá ọ níta. 12 Tí ẹni náà bá sì jẹ́ aláìní, ohun tó fi ṣe ìdúró ò gbọ́dọ̀ sun ọ̀dọ̀ rẹ mọ́jú.+ 13 Gbàrà tí oòrùn bá wọ̀ ni kí o rí i pé o dá ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà fún un, kó lè rí aṣọ fi sùn,+ á sì súre fún ọ; èyí á sì jẹ́ òdodo lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.

14 “O ò gbọ́dọ̀ rẹ́ alágbàṣe tó jẹ́ aláìní àti tálákà jẹ, ì báà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí àjèjì tó wà ní ilẹ̀ rẹ, nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 15 Ọjọ́ yẹn gan-an ni kí o fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀,+ kí oòrùn tó wọ̀, torí pé aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí* rẹ̀ ró. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, wàá sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.+

16 “Ẹ má pa àwọn bàbá torí ohun tí àwọn ọmọ wọn ṣe, ẹ má sì pa àwọn ọmọ torí ohun tí àwọn bàbá wọn ṣe.+ Kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+

17 “O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dá ẹjọ́ àjèjì tàbí ọmọ aláìníbaba,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba aṣọ opó láti fi ṣe ìdúró.*+ 18 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì rà ọ́ pa dà kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.

19 “Tí o bá kórè oko rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí ọkà kan sínú oko, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ gbé e. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.+

20 “Tí o bá lu igi ólífì rẹ, o ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Kí o fi ohun tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó.+

21 “Tí o bá kórè èso àjàrà inú ọgbà rẹ, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ kó àwọn èso tó bá ṣẹ́ kù. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó. 22 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́