ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Émọ́sì 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Émọ́sì

      • Ìkéde ìdájọ́ Ọlọ́run (1-8)

        • Ọlọ́run ń fi àṣírí ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn (7)

      • Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Samáríà (9-15)

Émọ́sì 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Di 7:6; Sm 147:19, 20
  • +Da 9:11, 12; Ho 12:2; Emọ 4:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 24

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 137-138

Émọ́sì 3:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wọ́n pàdé bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn?”

Émọ́sì 3:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    2/8/1999, ojú ìwé 15

Émọ́sì 3:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “láìjẹ́ pé ìdẹ wà nínú rẹ̀?”

Émọ́sì 3:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àṣírí rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 6:13; 18:17; Sm 25:14; Ais 42:9; Da 9:22; Ifi 1:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 12

    10/1/1999, ojú ìwé 5

    5/1/1997, ojú ìwé 18-19

Émọ́sì 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 1:2
  • +Jer 20:9; Emọ 7:14, 15; Iṣe 4:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 15

    11/15/2004, ojú ìwé 14

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 165-166

    Jí!,

    2/8/1999, ojú ìwé 15

Émọ́sì 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:22, 23
  • +Ho 7:1; Emọ 4:1

Émọ́sì 3:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6
  • +Ho 11:6; Emọ 6:8

Émọ́sì 3:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àga ìnàyìn ará Damásíkù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:4; Emọ 6:4

Émọ́sì 3:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jẹ́rìí lòdì sí.”

Émọ́sì 3:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 4:9
  • +1Ọb 12:32, 33; Ho 13:2
  • +2Ọb 23:15, 16; 2Kr 31:1; 34:1, 7; Ho 10:2; Mik 1:6

Émọ́sì 3:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Ọ̀pọ̀ ilé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 22:39
  • +Emọ 6:11

Àwọn míì

Émọ́sì 3:2Ẹk 19:5; Di 7:6; Sm 147:19, 20
Émọ́sì 3:2Da 9:11, 12; Ho 12:2; Emọ 4:12
Émọ́sì 3:7Jẹ 6:13; 18:17; Sm 25:14; Ais 42:9; Da 9:22; Ifi 1:1
Émọ́sì 3:8Emọ 1:2
Émọ́sì 3:8Jer 20:9; Emọ 7:14, 15; Iṣe 4:19, 20
Émọ́sì 3:92Ọb 17:22, 23
Émọ́sì 3:9Ho 7:1; Emọ 4:1
Émọ́sì 3:112Ọb 17:6
Émọ́sì 3:11Ho 11:6; Emọ 6:8
Émọ́sì 3:12Ais 8:4; Emọ 6:4
Émọ́sì 3:14Ho 4:9
Émọ́sì 3:141Ọb 12:32, 33; Ho 13:2
Émọ́sì 3:142Ọb 23:15, 16; 2Kr 31:1; 34:1, 7; Ho 10:2; Mik 1:6
Émọ́sì 3:151Ọb 22:39
Émọ́sì 3:15Emọ 6:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Émọ́sì 3:1-15

Émọ́sì

3 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa yín, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, nípa gbogbo ìdílé tí mo mú jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì:

 2 ‘Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé tó wà láyé.+

Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí ẹ jíhìn nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín.+

 3 Ǹjẹ́ àwọn méjì lè jọ rìn láìjẹ́ pé wọ́n ṣe àdéhùn?*

 4 Ǹjẹ́ kìnnìún máa ké ramúramù nínú igbó láìjẹ́ pé ó ti rí ẹran tó fẹ́ pa?

Ǹjẹ́ ọmọ kìnnìún* máa kùn hùn-ùn láti ibi tó fara pa mọ́ sí láìjẹ́ pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ nǹkan kan?

 5 Ǹjẹ́ ẹyẹ lè kó sí pańpẹ́ lórí ilẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ti dẹ pańpẹ́ náà?*

Ṣé pańpẹ́ lè ré lórí ilẹ̀ nígbà tí kò tíì mú nǹkan kan?

 6 Tí èèyàn bá fun ìwo nínú ìlú, ǹjẹ́ àyà àwọn ará ìlú kò ní já?

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ nínú ìlú, ǹjẹ́ kì í ṣe Jèhófà ló fà á?

 7 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kò ní ṣe ohunkóhun

Láìjẹ́ pé ó ti fi àṣírí ọ̀rọ̀ náà* han àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ wòlíì.+

 8 Kìnnìún ti ké ramúramù!+ Ta ni kò ní bẹ̀rù?

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti sọ̀rọ̀! Ta ni kò ní sọ tẹ́lẹ̀?’+

 9 ‘Ẹ kéde rẹ̀ lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò ní Áṣídódì

Àti lórí àwọn ilé gogoro tó láàbò nílẹ̀ Íjíbítì.

Ẹ sọ pé: “Ẹ kóra jọ sórí àwọn òkè Samáríà;+

Ẹ wo ìdàrúdàpọ̀ tó wà ní àárín rẹ̀

Àti jìbìtì tó wà nínú rẹ̀.+

10 Nítorí wọn kò mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́,” ni Jèhófà wí,

“Àwọn tó ń mú ìwà ipá àti ìparun pọ̀ sí i nínú àwọn ilé gogoro wọn tó láàbò.”’

11 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí,

‘Ọ̀tá kan máa yí ilẹ̀ náà ká,+

Á sì mú kí agbára rẹ tán,

Ohun tó wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò ni wọ́n á sì kó lọ.’+

12 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí,

‘Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń já ẹsẹ̀ méjì tàbí etí kan gbà kúrò lẹ́nu kìnnìún,

Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe já àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà,

Àwọn tó ń jókòó sórí ibùsùn rèǹtèrente àti sórí àga ìnàyìn tó rẹwà* ní Samáríà.’+

13 ‘Ẹ gbọ́, kí ẹ sì kìlọ̀ fún* ilé Jékọ́bù,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

14 ‘Ní ọjọ́ tí màá mú kí Ísírẹ́lì jíhìn nítorí ìdìtẹ̀* rẹ̀,+

Ni màá mú kí àwọn pẹpẹ Bẹ́tẹ́lì pẹ̀lú jíhìn;+

A ó ṣẹ́ àwọn ìwo pẹpẹ náà, wọ́n á sì já bọ́ sílẹ̀.+

15 Màá wó ilé ìgbà òtútù àti ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lulẹ̀.’

‘Àwọn ilé tí wọ́n fi eyín erin kọ́ á ṣègbé,+

Àwọn ilé ńlá* á sì pa run,’+ ni Jèhófà wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́