ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Fi gbogbo ọkàn rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà (1-9)

        • “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì” (4)

        • Kí àwọn òbí máa kọ́ àwọn ọmọ wọn (6, 7)

      • Ẹ má ṣe gbàgbé Jèhófà (10-15)

      • Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà wò (16-19)

      • Ẹ sọ fún àwọn ọmọ yín (20-25)

Diutarónómì 6:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:19; Di 4:9
  • +Owe 3:1, 2

Diutarónómì 6:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:7; Ais 42:8; Sek 14:9; Mk 12:29, 32; 1Kọ 8:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2016, ojú ìwé 18-22

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2012, ojú ìwé 23

    12/15/1992, ojú ìwé 29

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 12-13

Diutarónómì 6:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

  • *

    Tàbí “okunra rẹ; ohun tí o ní.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12; 11:13; 30:6; Mt 22:37
  • +Mk 12:30, 33; Lk 10:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2007, ojú ìwé 15-16

    6/15/2005, ojú ìwé 20

    10/1/1995, ojú ìwé 13

Diutarónómì 6:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 50

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2008, ojú ìwé 14

    5/15/2007, ojú ìwé 15-16

    4/1/2006, ojú ìwé 8-9

    6/15/2005, ojú ìwé 20

    4/1/2005, ojú ìwé 11-12

    6/1/1998, ojú ìwé 20

    12/1/1996, ojú ìwé 11

    7/1/1991, ojú ìwé 26

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 55-57, 58-59, 70-71

    Ìmọ̀, ojú ìwé 146

Diutarónómì 6:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ọmọ rẹ; tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́kàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:19; Di 4:9; Owe 22:6; Ef 6:4
  • +Di 11:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 50

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2019, ojú ìwé 26-27

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2013, ojú ìwé 16

    4/1/2008, ojú ìwé 14

    9/1/2007, ojú ìwé 22

    5/15/2007, ojú ìwé 15-16

    11/1/2006, ojú ìwé 4-6

    4/1/2006, ojú ìwé 8-9

    6/15/2005, ojú ìwé 20-21

    4/15/2005, ojú ìwé 6-7

    4/1/2005, ojú ìwé 11-12

    1/1/2005, ojú ìwé 26

    6/15/2004, ojú ìwé 5

    6/1/1998, ojú ìwé 20-22

    12/1/1996, ojú ìwé 11

    5/1/1995, ojú ìwé 10

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 55-57, 58-59, 70-71

    Ìmọ̀, ojú ìwé 146

Diutarónómì 6:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láàárín ojú rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 11:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2005, ojú ìwé 13

    9/15/2004, ojú ìwé 26

    7/15/1995, ojú ìwé 29

    5/1/1995, ojú ìwé 11-12

Diutarónómì 6:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2005, ojú ìwé 13

    7/15/1995, ojú ìwé 29

    5/1/1995, ojú ìwé 11-12

Diutarónómì 6:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18
  • +Joṣ 24:13; Sm 105:44

Diutarónómì 6:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:10

Diutarónómì 6:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:7

Diutarónómì 6:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12; 13:4
  • +Lk 4:8
  • +Jer 12:16

Diutarónómì 6:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:14

Diutarónómì 6:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:5; Di 4:24
  • +Ẹk 32:9, 10; Nọ 25:3; Di 11:16, 17; Ond 2:14
  • +2Ọb 17:18

Diutarónómì 6:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 4:7; Lk 4:12; 1Kọ 10:9
  • +Ẹk 17:2, 7; Sm 95:8, 9; Heb 3:8, 9

Diutarónómì 6:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18

Diutarónómì 6:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:30

Diutarónómì 6:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:3
  • +Di 4:34

Diutarónómì 6:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:5; Di 1:8

Diutarónómì 6:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 111:10; Owe 14:27
  • +Le 18:5; Di 4:1; Ga 3:12

Diutarónómì 6:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “là ń pa mọ́ níwájú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 12:13; Ro 10:5

Àwọn míì

Diu. 6:2Jẹ 18:19; Di 4:9
Diu. 6:2Owe 3:1, 2
Diu. 6:4Di 5:7; Ais 42:8; Sek 14:9; Mk 12:29, 32; 1Kọ 8:6
Diu. 6:5Di 10:12; 11:13; 30:6; Mt 22:37
Diu. 6:5Mk 12:30, 33; Lk 10:27
Diu. 6:7Jẹ 18:19; Di 4:9; Owe 22:6; Ef 6:4
Diu. 6:7Di 11:19
Diu. 6:8Di 11:18
Diu. 6:10Jẹ 15:18
Diu. 6:10Joṣ 24:13; Sm 105:44
Diu. 6:11Di 8:10
Diu. 6:12Ond 3:7
Diu. 6:13Di 10:12; 13:4
Diu. 6:13Lk 4:8
Diu. 6:13Jer 12:16
Diu. 6:14Ẹk 34:14
Diu. 6:15Ẹk 20:5; Di 4:24
Diu. 6:15Ẹk 32:9, 10; Nọ 25:3; Di 11:16, 17; Ond 2:14
Diu. 6:152Ọb 17:18
Diu. 6:16Mt 4:7; Lk 4:12; 1Kọ 10:9
Diu. 6:16Ẹk 17:2, 7; Sm 95:8, 9; Heb 3:8, 9
Diu. 6:18Jẹ 15:18
Diu. 6:19Ẹk 23:30
Diu. 6:22Ẹk 7:3
Diu. 6:22Di 4:34
Diu. 6:23Ẹk 13:5; Di 1:8
Diu. 6:24Sm 111:10; Owe 14:27
Diu. 6:24Le 18:5; Di 4:1; Ga 3:12
Diu. 6:25Onw 12:13; Ro 10:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 6:1-25

Diutarónómì

6 “Èyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fi lélẹ̀ láti kọ́ yín, kí ẹ lè máa pa wọ́n mọ́ tí ẹ bá ti sọdá sí ilẹ̀ tí ẹ máa gbà, 2 kí ẹ lè máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì máa pa gbogbo òfin àti àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa láṣẹ fún yín mọ́, ẹ̀yin àti ọmọ yín àti ọmọ ọmọ yín,+ ní gbogbo ọjọ́ ayé yín, kí ẹ̀mí yín lè gùn.+ 3 Kí o fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì rí i pé ò ń pa wọ́n mọ́, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn, bí Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ ṣe ṣèlérí fún ọ gẹ́lẹ́.

4 “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.+ 5 Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ+ àti gbogbo okun rẹ*+ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. 6 Rí i pé o fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sọ́kàn, 7 kí o máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ+ léraléra,* kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ, nígbà tí o bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.+ 8 So ó mọ́ ọwọ́ rẹ bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí rẹ.*+ 9 Kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé rẹ àti sí àwọn ẹnubodè rẹ.

10 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé òun máa fún ọ,+ àwọn ìlú tó tóbi tó sì dára, tí kì í ṣe ìwọ lo kọ́ ọ,+ 11 àwọn ilé tí gbogbo onírúurú ohun rere tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fún kún inú wọn, àwọn kòtò omi tí ìwọ kò gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà àti igi ólífì tí ìwọ kò gbìn, tí o jẹ, tí o sì yó,+ 12 rí i pé o ò gbàgbé Jèhófà,+ ẹni tó mú ọ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò ní ilé ẹrú. 13 Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o máa bẹ̀rù,+ òun ni kí o máa sìn,+ orúkọ rẹ̀ sì ni kí o máa fi búra.+ 14 Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, èyíkéyìí nínú ọlọ́run àwọn èèyàn tó yí yín ká,+ 15 torí Ọlọ́run tó fẹ́ kí á máa sin òun nìkan ṣoṣo ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ+ tó wà láàárín rẹ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí ọ gidigidi,+ yóò sì pa ọ́ run kúrò lórí ilẹ̀.+

16 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò,+ bí ẹ ṣe dán an wò ní Másà.+ 17 Kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín mọ́ délẹ̀délẹ̀ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀, tó pa láṣẹ pé kí ẹ máa tẹ̀ lé. 18 Kí o máa ṣe ohun tó tọ́, tó sì dáa ní ojú Jèhófà, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o lè wọ ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà búra fún àwọn baba ńlá rẹ nípa rẹ̀, kí o sì gbà á,+ 19 nígbà tí o bá lé gbogbo ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.+

20 “Lọ́jọ́ iwájú, tí ọmọ rẹ bá bi ọ́ pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ àwọn ìránnilétí, àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run wa pa láṣẹ fún yín?’ 21 kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì. 22 Ojú wa ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu tó lágbára tó sì ń ṣọṣẹ́ kọ lu Íjíbítì,+ Fáráò àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.+ 23 Ó sì mú wa kúrò níbẹ̀, kó lè mú wa wá síbí láti fún wa ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá wa nípa rẹ̀.+ 24 Jèhófà wá pàṣẹ fún wa pé ká máa tẹ̀ lé gbogbo ìlànà yìí, ká sì máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa fún àǹfààní ara wa títí lọ,+ ká lè máa wà láàyè+ bí a ṣe wà láàyè títí dòní. 25 A ó sì kà wá sí olódodo tí a bá rí i pé gbogbo àṣẹ yìí là ń pa mọ́ láti fi hàn pé à ń ṣègbọràn sí* Jèhófà Ọlọ́run wa, bó ṣe pa á láṣẹ fún wa.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́