ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 46
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Àwọn ọrẹ tí wọ́n á mú wá láwọn ọjọ́ pàtàkì kan (1-15)

      • Ohun ìní tí ìjòyè fi ṣe ogún fúnni (16-18)

      • Àwọn ibi tí wọ́n á ti máa se ọrẹ (19-24)

Ìsíkíẹ́lì 46:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:32
  • +Isk 44:1, 2
  • +Ẹk 20:9

Ìsíkíẹ́lì 46:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 44:3

Ìsíkíẹ́lì 46:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 81:3; Ais 66:23

Ìsíkíẹ́lì 46:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:9, 10; Isk 45:17

Ìsíkíẹ́lì 46:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B14.

  • *

    Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 46:11

Ìsíkíẹ́lì 46:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:11-15

Ìsíkíẹ́lì 46:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 46:2

Ìsíkíẹ́lì 46:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:14; Di 16:16
  • +Isk 40:20
  • +Isk 40:24

Ìsíkíẹ́lì 46:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 16

Ìsíkíẹ́lì 46:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 45:21, 24; 46:6, 7

Ìsíkíẹ́lì 46:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3
  • +Isk 45:17
  • +Isk 46:1, 2

Ìsíkíẹ́lì 46:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:38; Nọ 28:3, 5

Ìsíkíẹ́lì 46:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:10

Ìsíkíẹ́lì 46:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn yàrá mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 42:9
  • +Isk 42:1

Ìsíkíẹ́lì 46:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:4, 5
  • +Isk 44:19

Ìsíkíẹ́lì 46:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.

  • *

    Tàbí “Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti igun wọn dọ́gba.”

Ìsíkíẹ́lì 46:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 35:13

Àwọn míì

Ìsík. 46:1Isk 40:32
Ìsík. 46:1Isk 44:1, 2
Ìsík. 46:1Ẹk 20:9
Ìsík. 46:2Isk 44:3
Ìsík. 46:3Sm 81:3; Ais 66:23
Ìsík. 46:4Nọ 28:9, 10; Isk 45:17
Ìsík. 46:5Isk 46:11
Ìsík. 46:6Nọ 28:11-15
Ìsík. 46:8Isk 46:2
Ìsík. 46:9Ẹk 23:14; Di 16:16
Ìsík. 46:9Isk 40:20
Ìsík. 46:9Isk 40:24
Ìsík. 46:11Isk 45:21, 24; 46:6, 7
Ìsík. 46:12Le 1:3
Ìsík. 46:12Isk 45:17
Ìsík. 46:12Isk 46:1, 2
Ìsík. 46:13Ẹk 29:38; Nọ 28:3, 5
Ìsík. 46:17Le 25:10
Ìsík. 46:19Isk 42:9
Ìsík. 46:19Isk 42:1
Ìsík. 46:20Le 2:4, 5
Ìsík. 46:20Isk 44:19
Ìsík. 46:242Kr 35:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 46:1-24

Ìsíkíẹ́lì

46 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Kí ẹnubodè àgbàlá inú tó dojú kọ ìlà oòrùn+ wà ní títì pa+ fún ọjọ́ mẹ́fà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ àmọ́ kí wọ́n ṣí i ní ọjọ́ Sábáàtì àti ọjọ́ òṣùpá tuntun. 2 Ìjòyè náà máa gba ibi àbáwọlé*+ ẹnubodè náà wọlé láti ìta, yóò sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó ilẹ̀kùn ẹnubodè náà. Àwọn àlùfáà yóò rú odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀, yóò sì tẹrí ba níbi ẹnubodè náà, yóò wá jáde. Àmọ́ kí wọ́n má ti ẹnubodè ibẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́. 3 Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà yóò tún tẹrí ba níwájú Jèhófà ní ibi ẹnubodè yẹn ní àwọn ọjọ́ Sábáàtì àti àwọn ọjọ́ òṣùpá tuntun.+

4 “‘Kí odindi ẹbọ sísun tí ìjòyè náà máa mú wá fún Jèhófà ní ọjọ́ Sábáàtì jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan tí ara wọn dá ṣáṣá.+ 5 Ọrẹ ọkà yóò jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà* kan fún àgbò àti ohunkóhun tó bá lè mú wá fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn pẹ̀lú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan àti òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.+ 6 Ní ọjọ́ òṣùpá tuntun, ọrẹ náà yóò jẹ́ akọ ọmọ màlúù kan nínú agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan; kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+ 7 Kí ọrẹ ọkà tó máa mú wá jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kan, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò àti ohunkóhun tí agbára rẹ̀ bá ká fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Kó sì mú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì kan wá fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.

8 “‘Tí ìjòyè náà bá fẹ́ wọlé, kó gba ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà wọlé, ibẹ̀ náà ni kó sì gbà jáde.+ 9 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá sì wá síwájú Jèhófà nígbà àjọ̀dún,+ kí àwọn tó bá gba ẹnubodè àríwá+ wọlé láti jọ́sìn gba ẹnubodè gúúsù+ jáde, kí àwọn tó bá sì gba ẹnubodè gúúsù wọlé gba ẹnubodè àríwá jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ẹnubodè tó gbà wọlé jáde, ẹnubodè tó kọjú sí wọn ni kí wọ́n gbà jáde. 10 Ní ti ìjòyè tó wà láàárín wọn, nígbà tí wọ́n bá wọlé ni kó wọlé, nígbà tí wọ́n bá sì jáde ni kó jáde. 11 Nígbà àwọn àjọyọ̀ àti àjọ̀dún, kí ọrẹ ọkà jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò àti ohunkóhun tó bá lè mú wá fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, kí ó mú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì kan wá fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.+

12 “‘Tí ìjòyè náà bá pèsè odindi ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tó fi ṣe ọrẹ àtinúwá sí Jèhófà, kí wọ́n ṣí ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn fún un, kó sì pèsè odindi ẹbọ sísun rẹ̀ àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rẹ̀ bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.+ Tó bá sì ti jáde, kí wọ́n ti ẹnubodè náà.+

13 “‘Lójoojúmọ́, máa pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá láti fi ṣe odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà.+ Àràárọ̀ ni kí o máa ṣe é. 14 Ní àràárọ̀, kí o tún máa pèsè ìdá mẹ́fà òṣùwọ̀n eéfà láti fi ṣe ọrẹ ọkà, pẹ̀lú òróró tó kún ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì láti fi wọ́n ìyẹ̀fun tó kúnná bí ọrẹ ọkà tí ẹ ó máa mú wá fún Jèhófà déédéé. Bó ṣe máa rí títí lọ nìyí. 15 Kí wọ́n máa pèsè akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, ọrẹ ọkà àti òróró ní àràárọ̀ láti fi ṣe odindi ẹbọ sísun déédéé.’

16 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Tí ìjòyè náà bá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀bùn láti fi ṣe ogún, yóò di ohun ìní àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun ìní tí wọ́n jogún ni. 17 Àmọ́ tó bá mú lára ogún rẹ̀ tó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀; ó máa jẹ́ ti ìránṣẹ́ náà títí di ọdún òmìnira;+ yóò wá pa dà di ti ìjòyè náà. Àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan ló lè jogún ohun ìní rẹ̀ títí láé. 18 Ìjòyè náà kò gbọ́dọ̀ fipá gba ohun ìní kankan tó jẹ́ ogún àwọn èèyàn náà. Inú nǹkan ìní tirẹ̀ ni kó ti fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní ogún, kí wọ́n má bàa lé ìkankan nínú àwọn èèyàn mi kúrò nídìí ohun ìní wọn.’”

19 Ó wá mú mi gba ọ̀nà àbáwọlé+ tó dojú kọ àríwá,+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè tó lọ sí àwọn yàrá ìjẹun mímọ́* tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà, mo sì rí ibì kan lẹ́yìn rẹ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn. 20 Ó sọ fún mi pé: “Ibí ni àwọn àlùfáà yóò ti máa se ẹbọ ẹ̀bi àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n á sì ti máa yan ọrẹ ọkà,+ kí wọ́n má bàa gbé ohunkóhun jáde lọ sí àgbàlá ìta, kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn náà di mímọ́.”+

21 Ó mú mi jáde wá sí àgbàlá ìta, ó mú mi gba igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbàlá náà, mo sì rí àgbàlá kan ní igun kọ̀ọ̀kan àgbàlá ìta. 22 Àgbàlá kéékèèké wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbàlá náà, gígùn wọn jẹ́ ogójì (40) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ wọn sì jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. Ìwọ̀n mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba.* 23 Ògiri àgbàlá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ìgbásẹ̀ yí ká, ìsàlẹ̀ ìgbásẹ̀ àwọn ògiri náà sì ni ibi tí wọ́n ti ń se àwọn ohun tí wọ́n mú wá bí ọrẹ. 24 Ó wá sọ fún mi pé: “Àwọn ilé yìí ni àwọn ìránṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì ti ń se ohun tí àwọn èèyàn mú wá láti fi rúbọ.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́