ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì jẹ búrẹ́dì àfihàn ní Nóbù (1-9)

      • Dáfídì ṣe bí ayírí ní Gátì (10-15)

1 Sámúẹ́lì 21:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:9, 19
  • +1Sa 18:13

1 Sámúẹ́lì 21:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ní ìbálòpọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 25:30; Le 24:5, 9; Mt 12:3, 4
  • +Ẹk 19:15; Le 15:16; 2Sa 11:11

1 Sámúẹ́lì 21:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 15:18

1 Sámúẹ́lì 21:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 24:7-9; Mk 2:25, 26; Lk 6:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 76

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2005, ojú ìwé 30

    9/1/2002, ojú ìwé 18

1 Sámúẹ́lì 21:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:9; Sm 52:àkọlé
  • +Jẹ 36:1

1 Sámúẹ́lì 21:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:51, 54
  • +1Sa 17:2, 50
  • +Ẹk 28:6

1 Sámúẹ́lì 21:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 27:1
  • +Joṣ 11:22; 1Sa 5:8; 17:4; 27:2; Sm 56:àkọlé

1 Sámúẹ́lì 21:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:6-8; 29:4, 5

1 Sámúẹ́lì 21:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 56:3, 6

1 Sámúẹ́lì 21:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ní ọwọ́ wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:àkọlé

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2005, ojú ìwé 24

Àwọn míì

1 Sám. 21:11Sa 22:9, 19
1 Sám. 21:11Sa 18:13
1 Sám. 21:4Ẹk 25:30; Le 24:5, 9; Mt 12:3, 4
1 Sám. 21:4Ẹk 19:15; Le 15:16; 2Sa 11:11
1 Sám. 21:5Le 15:18
1 Sám. 21:6Le 24:7-9; Mk 2:25, 26; Lk 6:3, 4
1 Sám. 21:71Sa 22:9; Sm 52:àkọlé
1 Sám. 21:7Jẹ 36:1
1 Sám. 21:91Sa 17:51, 54
1 Sám. 21:91Sa 17:2, 50
1 Sám. 21:9Ẹk 28:6
1 Sám. 21:101Sa 27:1
1 Sám. 21:10Joṣ 11:22; 1Sa 5:8; 17:4; 27:2; Sm 56:àkọlé
1 Sám. 21:111Sa 18:6-8; 29:4, 5
1 Sám. 21:12Sm 56:3, 6
1 Sám. 21:13Sm 34:àkọlé
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 21:1-15

Sámúẹ́lì Kìíní

21 Nígbà tó yá, Dáfídì wá sọ́dọ̀ àlùfáà Áhímélékì ní Nóbù.+ Jìnnìjìnnì bá Áhímélékì nígbà tó pàdé Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi dá wá, tí kò sẹ́ni tó tẹ̀ lé ọ?”+ 2 Dáfídì dá àlùfáà Áhímélékì lóhùn pé: “Ọba ní kí n ṣe ohun kan, àmọ́ ó sọ pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan mọ ohunkóhun nípa iṣẹ́ tí mo rán ọ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ.’ Torí náà, mo bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mi ṣe àdéhùn pé ká pàdé níbì kan. 3 Ní báyìí, tí búrẹ́dì márùn-ún bá wà ní ìkáwọ́ rẹ, ṣáà fún mi tàbí ohunkóhun tó bá wà.” 4 Àmọ́ àlùfáà náà dá Dáfídì lóhùn pé: “Kò sí búrẹ́dì lásán, búrẹ́dì mímọ́+ ló wà, tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà kò bá ti fọwọ́ kan obìnrin.”*+ 5 Dáfídì dá àlùfáà náà lóhùn pé: “A ti rí i dájú pé a yẹra fún àwọn obìnrin bí a ti máa ń ṣe nígbà tí mo bá jáde ogun.+ Tí ara àwọn ọkùnrin náà bá wà ní mímọ́ nígbà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì ni wọ́n bá lọ, ṣé wọn ò ní wà ní mímọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ pàtàkì bíi tòní yìí?” 6 Àlùfáà náà bá fún un ní búrẹ́dì mímọ́,+ torí pé kò sí búrẹ́dì míì nílẹ̀ àfi búrẹ́dì àfihàn, tí a mú kúrò níwájú Jèhófà kí a lè fi búrẹ́dì tuntun rọ́pò rẹ̀ ní ọjọ́ tí a mú un kúrò.

7 Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, tí a dá dúró níwájú Jèhófà. Dóẹ́gì+ ni orúkọ rẹ̀, ará Édómù+ ni, òun sì ni olórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Sọ́ọ̀lù.

8 Dáfídì wá sọ fún Áhímélékì pé: “Ṣé ọ̀kọ̀ tàbí idà kankan wà ní ìkáwọ́ rẹ níbí? Mi ò mú idà mi tàbí àwọn ohun ìjà mi dání, nítorí iṣẹ́ ọba jẹ́ kánjúkánjú.” 9 Àlùfáà náà bá sọ pé: “Idà Gòláyátì+ ará Filísínì tí o pa ní Àfonífojì* Élà+ wà níbí, òun ni wọ́n faṣọ wé lẹ́yìn éfódì+ yẹn. Tí o bá fẹ́ mú un, o lè mú un, torí òun nìkan ló wà níbí.” Dáfídì wá sọ pé: “Kò sí èyí tó dà bíi rẹ̀. Mú un fún mi.”

10 Lọ́jọ́ yẹn, Dáfídì gbéra, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ+ nítorí Sọ́ọ̀lù, níkẹyìn ó dé ọ̀dọ̀ Ákíṣì ọba Gátì.+ 11 Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sọ fún un pé: “Ṣé kì í ṣe Dáfídì ọba ilẹ̀ náà nìyí? Ṣé òun kọ́ ni wọ́n kọrin fún, tí wọ́n ń jó tí wọ́n sì ń sọ pé,

‘Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,

Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá’?”+

12 Dáfídì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́kàn, ẹ̀rù sì bẹ̀rẹ̀ sí í bà á gan-an+ nítorí Ákíṣì ọba Gátì. 13 Torí náà, ó díbọ́n lójú wọn bíi pé orí òun ti yí,+ ó sì ń ṣe bí ayírí láàárín wọn.* Ó ń ha ara àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè, ó sì ń wa itọ́ sí irùngbọ̀n rẹ̀. 14 Níkẹyìn, Ákíṣì sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ rí i pé orí ọkùnrin yìí ti yí! Kí ló dé tí ẹ fi mú un wá sọ́dọ̀ mi? 15 Ṣé àwọn wèrè tó wà níbí kò tó ni, tí màá fi ní kí eléyìí wá máa ṣe wèrè níwájú mi? Ṣé ó yẹ kí irú ọkùnrin yìí wọ ilé mi?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́