ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Sólómọ́nì béèrè ọgbọ́n (1-12)

      • Ọrọ̀ Sólómọ́nì (13-17)

2 Kíróníkà 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:25; Onw 2:9; Mt 6:28, 29; 12:42

2 Kíróníkà 1:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:4; 1Kr 21:29

2 Kíróníkà 1:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 13:5
  • +1Kr 16:1

2 Kíróníkà 1:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “máa ń wádìí lọ́dọ̀ Rẹ̀ níbẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 38:1, 2
  • +Ẹk 31:2-5

2 Kíróníkà 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:4

2 Kíróníkà 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:5-9

2 Kíróníkà 1:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:8
  • +1Kr 28:5; Sm 89:28, 29

2 Kíróníkà 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:12; 1Kr 28:6; Sm 132:11
  • +Jẹ 13:14, 16

2 Kíróníkà 1:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tí màá fi máa jáde níwájú àwọn èèyàn yìí, tí màá sì fi máa wọlé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 2:6; Jem 1:5
  • +Sm 72:1, 2

2 Kíróníkà 1:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “ọ̀pọ̀ ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:10-13, 28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 19

2 Kíróníkà 1:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:25; 2Kr 9:22; Onw 2:9

2 Kíróníkà 1:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:4

2 Kíróníkà 1:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn agẹṣin.”

  • *

    Tàbí “àwọn agẹṣin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:16; 1Ọb 4:26
  • +2Kr 8:5, 6
  • +2Kr 9:25

2 Kíróníkà 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:21
  • +1Ọb 10:27; 2Kr 9:27

2 Kíróníkà 1:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “láti Íjíbítì àti Kúè; àwọn oníṣòwò ọba á rà wọ́n láti Kúè,” ó lè jẹ́ pé Sìlíṣíà ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 9:28
  • +1Ọb 10:28, 29

Àwọn míì

2 Kíró. 1:11Kr 29:25; Onw 2:9; Mt 6:28, 29; 12:42
2 Kíró. 1:31Ọb 3:4; 1Kr 21:29
2 Kíró. 1:41Kr 13:5
2 Kíró. 1:41Kr 16:1
2 Kíró. 1:5Ẹk 38:1, 2
2 Kíró. 1:5Ẹk 31:2-5
2 Kíró. 1:61Ọb 3:4
2 Kíró. 1:71Ọb 3:5-9
2 Kíró. 1:82Sa 7:8
2 Kíró. 1:81Kr 28:5; Sm 89:28, 29
2 Kíró. 1:92Sa 7:12; 1Kr 28:6; Sm 132:11
2 Kíró. 1:9Jẹ 13:14, 16
2 Kíró. 1:10Owe 2:6; Jem 1:5
2 Kíró. 1:10Sm 72:1, 2
2 Kíró. 1:111Ọb 3:10-13, 28
2 Kíró. 1:121Kr 29:25; 2Kr 9:22; Onw 2:9
2 Kíró. 1:131Ọb 3:4
2 Kíró. 1:14Di 17:16; 1Ọb 4:26
2 Kíró. 1:142Kr 8:5, 6
2 Kíró. 1:142Kr 9:25
2 Kíró. 1:151Ọb 10:21
2 Kíró. 1:151Ọb 10:27; 2Kr 9:27
2 Kíró. 1:162Kr 9:28
2 Kíró. 1:161Ọb 10:28, 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 1:1-17

Kíróníkà Kejì

1 Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ń lágbára sí i nínú ìjọba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì sọ ọ́ di ẹni ńlá tó ta yọ.+

2 Sólómọ́nì ránṣẹ́ pe gbogbo Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn olórí agbo ilé. 3 Nígbà náà, Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ náà lọ sí ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ torí pé ibẹ̀ ni àgọ́ ìpàdé Ọlọ́run tòótọ́ wà, èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa ní aginjù. 4 Àmọ́, Dáfídì ti gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wá láti Kiriati-jéárímù+ sí ibi tí Dáfídì ṣètò sílẹ̀ fún un; ó ti pa àgọ́ fún un ní Jerúsálẹ́mù.+ 5 Wọ́n ti gbé pẹpẹ bàbà+ tí Bẹ́sálẹ́lì+ ọmọ Úráì ọmọ Húrì ṣe sí iwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà; Sólómọ́nì àti gbogbo ìjọ sì máa ń gbàdúrà níwájú rẹ̀.* 6 Sólómọ́nì wá rú àwọn ẹbọ níbẹ̀ níwájú Jèhófà, ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹran ẹbọ sísun ló sì fi rúbọ lórí pẹpẹ bàbà+ tó wà ní àgọ́ ìpàdé.

7 Ní òru yẹn, Ọlọ́run fara han Sólómọ́nì, ó sì sọ fún un pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 8 Ni Sólómọ́nì bá sọ fún Ọlọ́run pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Dáfídì bàbá mi+ lọ́nà tó ga, o sì ti fi mí jọba ní ipò rẹ̀.+ 9 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi ṣẹ,+ nítorí o ti fi mí jọba lórí àwọn èèyàn tó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.+ 10 Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀+ tí màá fi máa darí àwọn èèyàn yìí,* nítorí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ yìí?”+

11 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ yìí àti pé o ò béèrè ọlá, ọrọ̀ àti ògo tàbí ikú* àwọn tó kórìíra rẹ, bẹ́ẹ̀ ni o ò béèrè ẹ̀mí gígùn,* àmọ́ o béèrè ọgbọ́n àti ìmọ̀ kí o lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,+ 12 màá fún ọ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀; màá tún fún ọ ní ọlá àti ọrọ̀ àti iyì irú èyí tí àwọn ọba tó ṣáájú rẹ kò ní, kò sì ní sí èyí tó máa ní irú rẹ̀ lẹ́yìn rẹ.”+

13 Nítorí náà, Sólómọ́nì dé láti ibi gíga tó wà ní Gíbíónì,+ láti iwájú àgọ́ ìpàdé, sí Jerúsálẹ́mù; ó sì ń ṣàkóso Ísírẹ́lì. 14 Sólómọ́nì ń kó kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin jọ;* ó ní ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin,*+ ó sì kó wọn sí àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ àti sí tòsí ọba ní Jerúsálẹ́mù.+ 15 Ọba mú kí fàdákà àti wúrà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta,+ ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+ 16 Íjíbítì ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹṣin wá fún Sólómọ́nì,+ àwùjọ àwọn oníṣòwò ọba á sì ra agbo ẹṣin* náà ní iye kan.+ 17 Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) fàdákà ni wọ́n ń ra kẹ̀kẹ́ ẹṣin kọ̀ọ̀kan láti Íjíbítì, àádọ́jọ (150) fàdákà sì ni wọ́n ń ra ẹṣin kọ̀ọ̀kan; wọ́n á wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ọba àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ọba Síríà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́