Jóòbù
7 “Ǹjẹ́ ìgbésí ayé ẹni kíkú lórí ilẹ̀ kò dà bí iṣẹ́ àṣekára tó pọn dandan?
Ṣé kì í ṣe bíi ti alágbàṣe ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ rí?+
2 Ó ń retí òjìji bíi ti ẹrú,
Ó sì ń dúró de owó iṣẹ́ rẹ̀ bíi ti alágbàṣe.+
3 Torí náà, a ti yan àwọn oṣù asán fún mi,
Àwọn òru ìbànújẹ́ ni a sì ti kà sílẹ̀ fún mi.+
4 Nígbà tí mo dùbúlẹ̀, mo béèrè pé, ‘Ìgbà wo ni màá dìde?’+
Àmọ́ bí òru náà ṣe ń falẹ̀, ṣe ni mò ń yí kiri títí ilẹ̀ fi mọ́.*
8 Ojú tó rí mi báyìí kò ní rí mi mọ́;
Ojú rẹ máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.+
11 Torí náà, mi ò ní pa ẹnu mi mọ́.
12 Ṣé èmi ni òkun tàbí ẹran ńlá inú òkun,
Tí o fi máa yan ẹ̀ṣọ́ tì mí?
13 Nígbà tí mo sọ pé, ‘Àga mi máa tù mí nínú;
Ibùsùn mi máa bá mi dín ìbànújẹ́ mi kù,’
14 O wá fi àwọn àlá dẹ́rù bà mí,
O sì fi àwọn ìran dáyà já mi,
15 Tó fi jẹ́ pé mo* fara mọ́ ọn kí wọ́n sé mi léèémí,
16 Mo kórìíra ayé mi gidigidi;+ mi ò fẹ́ wà láàyè mọ́.
Fi mí sílẹ̀, torí àwọn ọjọ́ mi dà bí èémí.+
18 Kí ló dé tí ò ń yẹ̀ ẹ́ wò ní àràárọ̀,
Tí o sì ń dán an wò ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú?+
19 Ṣé o ò ní gbójú kúrò lọ́dọ̀ mi ni,
Kí o sì fi mí sílẹ̀ kí n lè ráyè gbé itọ́ mì?+
20 Tí mo bá ṣẹ̀, ṣé mo lè ṣe ọ́ níbi, ìwọ Ẹni tó ń kíyè sí aráyé?+
Kí ló dé tí o dájú sọ mí?
Àbí mo ti di ìnira fún ọ ni?
21 Kí ló dé tí o ò dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì,
Kí o sì gbójú fo àṣìṣe mi?
Torí láìpẹ́, màá dùbúlẹ̀ sínú erùpẹ̀,+
O máa wá mi, àmọ́ mi ò ní sí mọ́.”