ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • O gbé, ìwọ Áríélì! (1-16)

        • Ọlọ́run dẹ́bi fún àwọn tó ń fi ẹnu lásán sìn ín (13)

      • Adití máa gbọ́rọ̀; afọ́jú sì máa ríran (17-24)

Àìsáyà 29:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ibi Ìdáná Pẹpẹ Ọlọ́run,” ó jọ pé Jerúsálẹ́mù ló ń tọ́ka sí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:7, 9
  • +Di 16:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 296-297

Àìsáyà 29:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:53-55
  • +Ais 51:19; Ida 1:4
  • +Jer 15:14; Sef 1:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 296-297

Àìsáyà 29:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:11; 25:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 296-297

Àìsáyà 29:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 51:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 296-297

Àìsáyà 29:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àjèjì.”

  • *

    Ìyẹn, èèpo fúlẹ́fúlẹ́ ara ọkà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 13:19; 14:22; 21:9
  • +Ais 13:11; 17:13
  • +Ais 47:9; 48:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 297

Àìsáyà 29:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 2:10; Jer 50:25; Na 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 297

Àìsáyà 29:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:12, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 297-298

Àìsáyà 29:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì ṣófo.”

  • *

    Tàbí “tí ọkàn rẹ̀ sì gbẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:12; Jer 51:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 297-298

Àìsáyà 29:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hab 1:5
  • +Ais 6:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 298-299

Àìsáyà 29:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:10; Ro 11:8
  • +Jer 14:14; 27:15
  • +Mik 3:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 298-299

Àìsáyà 29:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 298-299

Àìsáyà 29:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 298-299

Àìsáyà 29:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:1; Jer 5:2
  • +Mt 15:7-9; Mk 7:6-8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 299, 301

Àìsáyà 29:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 28:21; Hab 1:5
  • +Jer 8:9; 1Kọ 1:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 299

Àìsáyà 29:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìmọ̀ràn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:1
  • +Isk 8:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 299-300

Àìsáyà 29:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ wo bí ẹ ṣe gbé nǹkan gbòdì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 64:8
  • +Jer 18:6
  • +Ro 9:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 301

Àìsáyà 29:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 35:1; 41:19
  • +Ais 32:14, 15

Àìsáyà 29:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 35:5; 42:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 232-233, 235

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 298, 300

Àìsáyà 29:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:16

Àìsáyà 29:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 2:1

Àìsáyà 29:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹni tó ń báni wí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 5:10
  • +Isk 13:19

Àìsáyà 29:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, nítorí ìtìjú àti ìjákulẹ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:7; Mik 7:20
  • +Joẹ 2:27

Àìsáyà 29:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:11
  • +Ais 8:13; Ho 3:5

Àìsáyà 29:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣìnà nínú ẹ̀mí.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 301

Àwọn míì

Àìsá. 29:12Sa 5:7, 9
Àìsá. 29:1Di 16:16
Àìsá. 29:2Di 28:53-55
Àìsá. 29:2Ais 51:19; Ida 1:4
Àìsá. 29:2Jer 15:14; Sef 1:7
Àìsá. 29:32Ọb 24:11; 25:1
Àìsá. 29:4Ais 51:23
Àìsá. 29:5Ais 13:19; 14:22; 21:9
Àìsá. 29:5Ais 13:11; 17:13
Àìsá. 29:5Ais 47:9; 48:3
Àìsá. 29:61Sa 2:10; Jer 50:25; Na 1:3
Àìsá. 29:7Jer 25:12, 14
Àìsá. 29:8Ais 10:12; Jer 51:24
Àìsá. 29:9Hab 1:5
Àìsá. 29:9Ais 6:9
Àìsá. 29:10Ais 6:10; Ro 11:8
Àìsá. 29:10Jer 14:14; 27:15
Àìsá. 29:10Mik 3:7
Àìsá. 29:11Ais 8:16
Àìsá. 29:13Ais 48:1; Jer 5:2
Àìsá. 29:13Mt 15:7-9; Mk 7:6-8
Àìsá. 29:14Ais 28:21; Hab 1:5
Àìsá. 29:14Jer 8:9; 1Kọ 1:19
Àìsá. 29:15Ais 30:1
Àìsá. 29:15Isk 8:12
Àìsá. 29:16Ais 64:8
Àìsá. 29:16Jer 18:6
Àìsá. 29:16Ro 9:20, 21
Àìsá. 29:17Ais 35:1; 41:19
Àìsá. 29:17Ais 32:14, 15
Àìsá. 29:18Ais 35:5; 42:16
Àìsá. 29:19Ais 41:16
Àìsá. 29:20Mik 2:1
Àìsá. 29:21Emọ 5:10
Àìsá. 29:21Isk 13:19
Àìsá. 29:22Ne 9:7; Mik 7:20
Àìsá. 29:22Joẹ 2:27
Àìsá. 29:23Ais 45:11
Àìsá. 29:23Ais 8:13; Ho 3:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 29:1-24

Àìsáyà

29 “O gbé ìwọ Áríélì,* Áríélì, ìlú tí Dáfídì pàgọ́ sí!+

Ẹ máa bá a lọ lọ́dọọdún;

Ẹ máa ṣe àwọn àjọyọ̀+ ní àkókò wọn.

 2 Àmọ́ màá mú ìdààmú bá Áríélì,+

Ó máa ṣọ̀fọ̀, ó máa dárò,+

Ó sì máa dà bí ibi ìdáná pẹpẹ Ọlọ́run fún mi.+

 3 Màá pàgọ́ yí ọ ká,

Màá ṣe ọgbà láti dó tì ọ́,

Màá sì ṣe àwọn ohun tí màá fi gbógun tì ọ́.+

 4 A máa rẹ̀ ọ́ wálẹ̀;

Wàá máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀,

Iyẹ̀pẹ̀ ò sì ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere.

Ohùn rẹ á máa jáde látinú ilẹ̀+

Bí ohùn abẹ́mìílò,

Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ á sì máa dún ṣíoṣío látinú iyẹ̀pẹ̀.

 5 Àwọn ọ̀tá* rẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ máa dà bí eruku lẹ́búlẹ́bú,+

Àwọn ìkà tó pọ̀ rẹpẹtẹ sì máa dà bí ìyàngbò* tó ń fẹ́ lọ.+

Ó sì máa ṣẹlẹ̀ lójijì, ká tó ṣẹ́jú pẹ́.+

 6 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa fún ọ láfiyèsí

Pẹ̀lú ààrá, ìmìtìtì ilẹ̀ àti ariwo ńlá,

Pẹ̀lú ìjì, atẹ́gùn líle àti ọwọ́ iná tó ń jẹni run.”+

 7 Gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ tí wọ́n ń gbógun ja Áríélì,+

Gbogbo àwọn tí wọ́n ń gbógun jà á,

Àwọn ilé gogoro tí wọ́n fi dó tì í,

Àti àwọn tó ń kó ìdààmú bá a,

Máa wá dà bí àlá, ìran òru.

 8 Àní, ó máa dà bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa lá àlá pé òun ń jẹun,

Àmọ́ tó jí, tí ebi ṣì ń pa á*

Àti bí ìgbà tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,

Àmọ́ tó jí, tó ti rẹ̀ ẹ́, tí òùngbẹ ṣì ń gbẹ ẹ́.*

Bó ṣe máa rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè tó pọ̀ rẹpẹtẹ nìyí,

Àwọn tó gbógun ja Òkè Síónì.+

 9 Kí ẹnu yà yín, kí ẹ sì ṣe kàyéfì;+

Ẹ fọ́ ara yín lójú, kí ẹ sì fọ́jú.+

Wọ́n ti yó, àmọ́ kì í ṣe wáìnì ni wọ́n mu yó;

Wọ́n ń ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́, àmọ́ kì í ṣe ọtí ló ń mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

10 Torí Jèhófà ti da ẹ̀mí oorun àsùnwọra lù yín;+

Ó ti pa ojú yín dé, ẹ̀yin wòlíì,+

Ó sì ti bo orí yín, ẹ̀yin aríran.+

11 Gbogbo ìran dà bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a gbé èdìdì lé fún yín.+ Tí wọ́n bá fún ẹni tó mọ̀wé kà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á sókè,” á sọ pé: “Mi ò lè kà á, torí wọ́n ti gbé èdìdì lé e.” 12 Tí wọ́n bá sì fún ẹni tí kò mọ̀wé kà ní ìwé náà, tí wọ́n sọ pé: “Jọ̀ọ́, kà á,” á sọ pé: “Mi ò lè kàwé rárá.”

13 Jèhófà sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi,

Wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi,+

Àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi;

Àṣẹ èèyàn tí wọ́n kọ́ wọn ló sì ń mú kí wọ́n máa bẹ̀rù mi.+

14 Torí náà, èmi ni Ẹni tó tún máa ṣe àwọn ohun àgbàyanu sí àwọn èèyàn yìí,+

Ohun àgbàyanu kan tẹ̀ lé òmíràn;

Ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n wọn máa ṣègbé,

Òye àwọn olóye wọn sì máa fara pa mọ́.”+

15 Ó mà ṣe o, fún àwọn tó sapá gidigidi kí wọ́n lè fi ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe* pa mọ́ fún Jèhófà.+

Ibi tó ṣókùnkùn ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ wọn,

Tí wọ́n ń sọ pé: “Ta ló rí wa,

Ta ló mọ̀ nípa wa?”+

16 Ẹ wo bí ẹ ṣe ń dorí nǹkan kodò!*

Ṣé ojú kan náà ló yẹ ká fi wo amọ̀kòkò àti amọ̀?+

Ṣé ó yẹ kí ohun tí a dá sọ nípa ẹni tó dá a pé:

“Òun kọ́ ló dá mi”?+

Ṣé ohun tí a ṣe sì máa ń sọ fún ẹni tó ṣe é pé:

“Kò fi òye hàn”?+

17 Kò ní pẹ́ rárá tí Lẹ́bánónì fi máa di ọgbà eléso,+

A sì máa ka ọgbà eléso náà sí igbó.+

18 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn adití máa gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà,

Àwọn afọ́jú sì máa ríran látinú ìṣúdùdù àti òkùnkùn.+

19 Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ máa yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà,

Àwọn tó sì jẹ́ aláìní láàárín àwọn èèyàn máa yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+

20 Torí pé ìkà èèyàn kò ní sí mọ́,

Òpin máa dé bá afọ́nnu,

Gbogbo àwọn tó sì wà lójúfò láti ṣe ìkà máa pa run,+

21 Àwọn tó ń fi ọ̀rọ̀ èké dá àwọn míì lẹ́bi,

Tí wọ́n ń dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ de olùgbèjà* ní ẹnubodè ìlú+

Àti àwọn tó ń jiyàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fi ìdájọ́ òdodo du olódodo.+

22 Torí náà, ohun tí Jèhófà, ẹni tó ra Ábúráhámù pa dà,+ sọ fún ilé Jékọ́bù nìyí:

“Ojú ò ní ti Jékọ́bù mọ́,

Ojú rẹ̀ ò sì ní funfun mọ́.*+

23 Torí tó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,

Tí wọ́n jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ mi, ní àárín rẹ̀,+

Wọ́n máa sọ orúkọ mi di mímọ́;

Àní, wọ́n máa sọ Ẹni Mímọ́ Jékọ́bù di mímọ́,

Wọ́n sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run Ísírẹ́lì gidigidi.+

24 Àwọn tó ní èrò tí kò tọ́* máa ní òye,

Àwọn tó ń ráhùn sì máa gba ìtọ́ni.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́