Sáàmù
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín tí a yí sí Ṣẹ́mínítì.* Orin Dáfídì.
6 Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìrunú rẹ.+
2 Ṣojú rere sí mi,* Jèhófà, nítorí ó ti ń rẹ̀ mí.
Wò mí sàn, Jèhófà,+ nítorí àwọn egungun mi ń gbọ̀n.
6 Àárẹ̀ ti mú mi nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi;+
Láti òru mọ́jú ni omijé mi ń rin ibùsùn mi gbingbin;*
Ẹkún mi ti fi omi kún àga tìmùtìmù mi.+
8 Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń hùwà burúkú,
Nítorí pé Jèhófà yóò gbọ́ igbe ẹkún mi.+
9 Jèhófà yóò gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún ojú rere;+
Jèhófà yóò dáhùn àdúrà mi.
10 Ojú á ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi, ìdààmú á sì bá wọn;
Ìtìjú òjijì á mú wọn sá pa dà.+