ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Wọ́n ṣẹ́gun Ábúsálómù, wọ́n sì pa á (1-18)

      • Dáfídì gbọ́ nípa ikú Ábúsálómù (19-33)

2 Sámúẹ́lì 18:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 20:18

2 Sámúẹ́lì 18:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sí ìkáwọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:16; 10:7
  • +2Sa 23:18, 19
  • +1Kr 2:15, 16
  • +2Sa 15:19, 21

2 Sámúẹ́lì 18:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọn ò lè fọkàn sí wa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 21:17
  • +2Sa 17:1-3; Ida 4:20

2 Sámúẹ́lì 18:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:12

2 Sámúẹ́lì 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 17:26

2 Sámúẹ́lì 18:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 3:7; Owe 24:21, 22
  • +2Sa 16:15

2 Sámúẹ́lì 18:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka

  • *

    Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka

  • *

    Ní Héb., “láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”

  • *

    Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka

2 Sámúẹ́lì 18:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:16; 18:2

2 Sámúẹ́lì 18:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ká ní mo tiẹ̀ ń wọn ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà ní àtẹ́wọ́ mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:5

2 Sámúẹ́lì 18:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ká ní mo ti ṣe àdàkàdekè sí ọkàn rẹ̀ ni.”

2 Sámúẹ́lì 18:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ “ọ̀kọ̀.” Ní Héb., “ọ̀pá.”

2 Sámúẹ́lì 18:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:10; Owe 2:22; 20:20; 30:17

2 Sámúẹ́lì 18:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 7:24, 26; 8:29; 10:23, 27

2 Sámúẹ́lì 18:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 14:17
  • +2Sa 14:27

2 Sámúẹ́lì 18:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:35, 36; 17:17
  • +Sm 9:4

2 Sámúẹ́lì 18:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:5

2 Sámúẹ́lì 18:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:6

2 Sámúẹ́lì 18:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “agbègbè náà.”

2 Sámúẹ́lì 18:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:4
  • +2Ọb 9:17

2 Sámúẹ́lì 18:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:19

2 Sámúẹ́lì 18:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbé ọwọ́ wọn sókè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 22:47; Sm 144:1

2 Sámúẹ́lì 18:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:22

2 Sámúẹ́lì 18:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 18:21
  • +2Sa 22:49; Sm 55:18; 94:1; 124:2, 3

2 Sámúẹ́lì 18:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 27:2

2 Sámúẹ́lì 18:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:10; 17:14; 19:1; Owe 19:13

Àwọn míì

2 Sám. 18:1Owe 20:18
2 Sám. 18:22Sa 8:16; 10:7
2 Sám. 18:22Sa 23:18, 19
2 Sám. 18:21Kr 2:15, 16
2 Sám. 18:22Sa 15:19, 21
2 Sám. 18:32Sa 21:17
2 Sám. 18:32Sa 17:1-3; Ida 4:20
2 Sám. 18:52Sa 18:12
2 Sám. 18:62Sa 17:26
2 Sám. 18:7Sm 3:7; Owe 24:21, 22
2 Sám. 18:72Sa 16:15
2 Sám. 18:102Sa 8:16; 18:2
2 Sám. 18:122Sa 18:5
2 Sám. 18:152Sa 12:10; Owe 2:22; 20:20; 30:17
2 Sám. 18:17Joṣ 7:24, 26; 8:29; 10:23, 27
2 Sám. 18:18Jẹ 14:17
2 Sám. 18:182Sa 14:27
2 Sám. 18:192Sa 15:35, 36; 17:17
2 Sám. 18:19Sm 9:4
2 Sám. 18:202Sa 18:5
2 Sám. 18:21Jẹ 10:6
2 Sám. 18:242Sa 18:4
2 Sám. 18:242Ọb 9:17
2 Sám. 18:272Sa 18:19
2 Sám. 18:282Sa 22:47; Sm 144:1
2 Sám. 18:292Sa 18:22
2 Sám. 18:312Sa 18:21
2 Sám. 18:312Sa 22:49; Sm 55:18; 94:1; 124:2, 3
2 Sám. 18:32Sm 27:2
2 Sám. 18:332Sa 12:10; 17:14; 19:1; Owe 19:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 18:1-33

Sámúẹ́lì Kejì

18 Nígbà náà, Dáfídì ka iye àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì yan àwọn kan ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún.+ 2 Dáfídì wá fi ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà sábẹ́ àṣẹ* Jóábù,+ ó fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù, ó sì wá fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ítáì+ ará Gátì. Ọba sọ fún àwọn ọkùnrin náà pé: “Èmi náà á bá yín lọ.” 3 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “O ò lè lọ o,+ nítorí tí a bá sá, ọ̀rọ̀ wa ò lè jọ wọ́n lójú;* kódà tí ìdajì wa bá kú, kò lè jẹ́ nǹkan kan lójú wọn, nítorí ìwọ nìkan tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) gbogbo wa.+ Torí náà, ó máa dára kí o máa ràn wá lọ́wọ́ látinú ìlú.” 4 Ọba sọ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ bá rí pé ó dára jù ni màá ṣe.” Torí náà, ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè ìlú, gbogbo àwọn èèyàn náà sì jáde lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. 5 Ọba wá pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítáì pé: “Ẹ ṣe ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù jẹ́jẹ́ nítorí mi.”+ Gbogbo àwọn ọkùnrin náà gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí nítorí Ábúsálómù.

6 Àwọn ọkùnrin náà lọ sí pápá láti pàdé Ísírẹ́lì, ìjà náà sì wáyé ní igbó Éfúrémù.+ 7 Ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì+ ti ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ ọ̀pọ̀ èèyàn sì kú lọ́jọ́ yẹn, ọ̀kẹ́ kan (20,000) èèyàn ló kú. 8 Ogun náà dé gbogbo agbègbè náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tí igbó kìjikìji pa lọ́jọ́ yẹn pọ̀ ju àwọn tí idà pa lọ.

9 Níkẹyìn, Ábúsálómù ṣàdédé pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ni Ábúsálómù gùn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* náà sì gba abẹ́ àwọn ẹ̀ka tó díjú lára igi ńlá kan, orí Ábúsálómù há sínú igi ńlá náà, ó rọ̀ dirodiro lókè,* kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí ó gùn sì kọjá lọ. 10 Ọkùnrin kan bá rí i, ó sì sọ fún Jóábù+ pé: “Wò ó! Mo rí Ábúsálómù tó so rọ̀ sórí igi ńlá kan.” 11 Jóábù sọ fún ọkùnrin tó wá sọ̀rọ̀ fún un pé: “Ìgbà tí o rí i, kí ló dé tí o ò ṣá a balẹ̀ níbẹ̀? Tayọ̀tayọ̀ ni mi ò bá fi fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá àti àmùrè kan.” 12 Àmọ́ ọkùnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Kódà, ká ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà ni o fún mi,* mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọmọ ọba; nítorí a gbọ́ tí ọba pàṣẹ fún ìwọ àti Ábíṣáì pẹ̀lú Ítáì pé, ‘Ẹni yòówù tí ì báà jẹ́, ẹ ṣọ́ra kí ewu kankan má wu ọ̀dọ́kùnrin náà, Ábúsálómù.’+ 13 Ká ní mo ti ṣàìgbọràn ni, tí mo sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ọba kò ní ṣàìmọ̀ nípa rẹ̀, ìwọ náà ò sì ní dáàbò bò mí.” 14 Jóábù bá sọ pé: “Mi ò ní fi àkókò mi ṣòfò lọ́dọ̀ rẹ mọ́!” Torí náà, ó mú aṣóró* mẹ́ta, ó sì fi wọ́n gún ọkàn Ábúsálómù ní àgúnyọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè ní àárín igi ńlá náà. 15 Nígbà náà, àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá tó ń gbé àwọn ohun ìjà Jóábù wá, wọ́n sì kọ lu Ábúsálómù títí ó fi kú.+ 16 Jóábù wá fun ìwo, àwọn ọkùnrin náà sì pa dà lẹ́yìn Ísírẹ́lì tí wọ́n ń lépa; Jóábù ní kí wọ́n dáwọ́ dúró. 17 Wọ́n gbé Ábúsálómù, wọ́n sọ ọ́ sínú kòtò ńlá kan nínú igbó, wọ́n sì kó òkúta lé e lórí pelemọ.+ Gbogbo Ísírẹ́lì sì sá lọ sí ilé wọn.

18 Nígbà tí Ábúsálómù ṣì wà láàyè, ó ṣe òpó kan, ó sì gbé e nàró fún ara rẹ̀ ní Àfonífojì* Ọba,+ torí ó sọ pé: “Mi ò ní ọmọkùnrin tí á máa jẹ́ orúkọ mi lọ.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe òpó náà, Ohun Ìrántí Ábúsálómù ni wọ́n sì ń pè é títí di òní yìí.

19 Áhímáásì+ ọmọ Sádókù sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti bá a dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ bí ó ṣe gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+ 20 Àmọ́ Jóábù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ìwọ ló máa lọ ròyìn lónìí, o lè lọ ròyìn lọ́jọ́ míì, àmọ́ lónìí, o ò ní lọ ròyìn, nítorí pé ọmọ ọba ló kú.”+ 21 Nígbà náà, Jóábù sọ fún ọmọ Kúṣì+ kan pé: “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ni ọmọ Kúṣì náà bá tẹrí ba fún Jóábù, ó sì sáré lọ. 22 Áhímáásì ọmọ Sádókù tún sọ fún Jóábù pé: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé ọmọ Kúṣì náà.” Àmọ́, Jóábù sọ pé: “Ọmọ mi, kí nìdí tí o fi fẹ́ sá tẹ̀ lé e, nígbà tí kò sí nǹkan tí o máa ròyìn?” 23 Síbẹ̀, ó ní: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé e.” Nítorí náà, Jóábù sọ fún un pé: “Sá tẹ̀ lé e!” Áhímáásì sì sáré gba agbègbè Jọ́dánì,* níkẹyìn, ó kọjá ọmọ Kúṣì náà.

24 Ní àkókò yìí, Dáfídì jókòó sí àárín ẹnubodè+ méjèèjì tó wà ní ìlú náà, olùṣọ́+ sì lọ sí orí òrùlé ẹnubodè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan tí òun nìkan ń sáré bọ̀. 25 Nítorí náà, olùṣọ́ ké sí ọba, ó sì sọ fún un. Ọba sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ òun nìkan ló ń bọ̀, á jẹ́ pé ìròyìn ló mú wá.” Bí ó ṣe ń sún mọ́ tòsí, 26 olùṣọ́ rí ọkùnrin míì tó ń sáré bọ̀. Olùṣọ́ bá pe aṣọ́bodè, ó ní: “Wò ó! Ọkùnrin míì ń dá sáré bọ̀!” Ọba sọ pé: “Ìròyìn ni ẹni yìí náà ń mú bọ̀.” 27 Olùṣọ́ sọ pé: “Mo rí i pé ẹni àkọ́kọ́ ń sáré bí Áhímáásì+ ọmọ Sádókù,” torí náà ọba sọ pé: “Èèyàn rere ni, ìròyìn ayọ̀ ló máa ń mú wá.” 28 Áhímáásì ké sí ọba pé: “Àlàáfíà ni!” Ó tẹrí ba fún ọba, ó sì dojú bolẹ̀. Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó dìtẹ̀* sí olúwa mi ọba lé e lọ́wọ́!”+

29 Àmọ́, ọba sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Áhímáásì fèsì pé: “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba àti ìránṣẹ́ rẹ, mo rí i tí ariwo sọ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, àmọ́ mi ò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀.”+ 30 Nítorí náà, ọba sọ pé: “Bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, dúró síbẹ̀.” Ó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì dúró síbẹ̀.

31 Lẹ́yìn náà, ọmọ Kúṣì dé,+ ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi ọba gbọ́ ìròyìn yìí: Jèhófà ti dá ẹjọ́ rẹ lọ́nà tó tọ́ lónìí bí ó ṣe gbà ọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.”+ 32 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún ọmọ Kúṣì pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Ọmọ Kúṣì fèsì pé: “Kí gbogbo àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba àti gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ dà bí ọ̀dọ́kùnrin náà!”+

33 Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá ọba, ó lọ sí yàrá tó wà lórí ẹnubodè, ó sì bú sẹ́kún, bí ó ṣe ń rìn lọ, ó ń sọ pé: “Ọmọ mi Ábúsálómù, ọmọ mi, ọmọ mi Ábúsálómù! Ì bá dáa ká ní èmi ni mo kú dípò rẹ, Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́