ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 7:24
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Jóṣúà àti gbogbo Ísírẹ́lì wá mú Ákánì+ ọmọ Síírà, fàdákà náà, ẹ̀wù oyè náà àti wúrà gbọọrọ náà,+ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, akọ màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, agbo ẹran rẹ̀, àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀, wọ́n sì kó wọn wá sí Àfonífojì* Ákórì.+

  • Jóṣúà 7:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Wọ́n kó òkúta jọ pelemọ lé e lórí, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí dòní. Bí inú tó ń bí Jèhófà gidigidi ṣe rọlẹ̀ nìyẹn.+ Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Àfonífojì Ákórì* títí dòní.

  • Jóṣúà 8:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Ó gbé ọba Áì kọ́ sórí òpó igi* títí di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn sì ti fẹ́ wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n sọ òkú rẹ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi.+ Wọ́n sì jù ú síbi àbáwọlé ẹnubodè ìlú náà, wọ́n kó òkúta lé e lórí pelemọ, ó sì wà níbẹ̀ títí dòní.

  • Jóṣúà 10:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Wọ́n mú àwọn ọba márààrún yìí jáde wá bá a látinú ihò náà: ọba Jerúsálẹ́mù, ọba Hébúrónì, ọba Jámútì, ọba Lákíṣì àti ọba Ẹ́gílónì.+

  • Jóṣúà 10:27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 27 Nígbà tí oòrùn wọ̀, Jóṣúà pàṣẹ pé kí wọ́n gbé wọn kúrò lórí òpó+ kí wọ́n sì jù wọ́n sí inú ihò àpáta tí wọ́n fara pa mọ́ sí. Wọ́n wá yí àwọn òkúta ńlá sí ẹnu ihò náà, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní olónìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́