ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì (1-7)

      • Ibi Mímọ́ Jù Lọ (8-14)

      • Àwọn òpó bàbà méjì (15-17)

2 Kíróníkà 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:1, 37
  • +Jẹ 22:2, 14
  • +2Sa 24:25; 1Kr 21:18
  • +2Sa 24:18; 1Kr 21:22

2 Kíróníkà 3:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ń lò jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5), àmọ́ àwọn kan sọ pé “ìwọ̀n tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀” tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ gígùn tó jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 51.8 (ínǹṣì 20.4). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:2

2 Kíróníkà 3:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Gọ̀bì.”

  • *

    Tàbí “ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ lára fífẹ̀ ilé náà.”

  • *

    Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ kan pè é ní “ọgọ́fà (120),” àmọ́ àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtàwọn ìtumọ̀ míì pè é ní “ogún (20) ìgbọ̀nwọ́.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:3

2 Kíróníkà 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:15, 22
  • +1Ọb 6:29
  • +1Ọb 6:21

2 Kíróníkà 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:2, 8
  • +1Kr 29:3, 4

2 Kíróníkà 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:29
  • +Ẹk 26:1; 1Ọb 6:29

2 Kíróníkà 3:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 26:33; 1Ọb 8:6; Heb 9:24
  • +1Ọb 6:20

2 Kíróníkà 3:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14

2 Kíróníkà 3:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:23-28

2 Kíróníkà 3:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:6; 1Kr 28:18

2 Kíróníkà 3:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, sápá Ibi Mímọ́.

2 Kíróníkà 3:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:51; Heb 10:19, 20
  • +Ẹk 26:31, 33

2 Kíróníkà 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:13
  • +1Ọb 7:15-22; 2Ọb 25:17; 2Kr 4:11-13; Jer 52:22, 23

2 Kíróníkà 3:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gúúsù.”

  • *

    Tàbí “àríwá.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Kí Ó [ìyẹn, Jèhófà] Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in.”

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Nínú Okun.”

Àwọn míì

2 Kíró. 3:11Ọb 6:1, 37
2 Kíró. 3:1Jẹ 22:2, 14
2 Kíró. 3:12Sa 24:25; 1Kr 21:18
2 Kíró. 3:12Sa 24:18; 1Kr 21:22
2 Kíró. 3:31Ọb 6:2
2 Kíró. 3:41Ọb 6:3
2 Kíró. 3:51Ọb 6:15, 22
2 Kíró. 3:51Ọb 6:29
2 Kíró. 3:51Ọb 6:21
2 Kíró. 3:61Kr 29:2, 8
2 Kíró. 3:61Kr 29:3, 4
2 Kíró. 3:7Ẹk 26:29
2 Kíró. 3:7Ẹk 26:1; 1Ọb 6:29
2 Kíró. 3:8Ẹk 26:33; 1Ọb 8:6; Heb 9:24
2 Kíró. 3:81Ọb 6:20
2 Kíró. 3:101Ọb 6:23-28
2 Kíró. 3:111Ọb 8:6; 1Kr 28:18
2 Kíró. 3:14Mt 27:51; Heb 10:19, 20
2 Kíró. 3:14Ẹk 26:31, 33
2 Kíró. 3:152Ọb 25:13
2 Kíró. 3:151Ọb 7:15-22; 2Ọb 25:17; 2Kr 4:11-13; Jer 52:22, 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 3:1-17

Kíróníkà Kejì

3 Nígbà náà, Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà+ sí Jerúsálẹ́mù lórí Òkè Moráyà,+ níbi tí Jèhófà ti fara han Dáfídì bàbá rẹ̀,+ ibẹ̀ ni Dáfídì ṣètò sílẹ̀ ní ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì. 2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà ní ọjọ́ kejì, oṣù kejì, ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. 3 Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tòótọ́ tí Sólómọ́nì fi lélẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,+ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ti tẹ́lẹ̀.* 4 Ibi àbáwọlé* tó wà níwájú jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó bá fífẹ̀ ilé náà mu,* gíga rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; * ó wá fi ògidì wúrà bò ó nínú.+ 5 Ó fi igi júnípà bo ilé ńlá náà, lẹ́yìn náà, ó fi wúrà tó dára bò ó,+ ó wá ya àwòrán igi ọ̀pẹ+ àti ẹ̀wọ̀n+ sára rẹ̀. 6 Yàtọ̀ síyẹn, ó fi òkúta iyebíye tó rẹwà+ bo ilé náà; wúrà+ tó lò sì jẹ́ wúrà láti Páfáímù. 7 Ó fi wúrà bo ilé náà àti àwọn igi ìrólé rẹ̀, ó tún fi bo àwọn ibi àbáwọlé rẹ̀,+ àwọn ògiri rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fín àwọn kérúbù sára àwọn ògiri náà.+

8 Ó ṣe apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé náà mu, ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́. Ó fi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) tálẹ́ńtì* wúrà tó dára bò ó.+ 9 Ìwọ̀n wúrà fún ìṣó jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì;* ó sì fi wúrà bo àwọn yàrá orí òrùlé.

10 Lẹ́yìn náà, ó ṣe ère kérúbù méjì sínú apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+ 11 Gígùn ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà lápapọ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; ìyẹ́ apá kan kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ìyẹ́ apá kérúbù kejì. 12 Ìyẹ́ apá kan kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri kejì ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ọ̀kan lára ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́. 13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù yìí nà jáde ní ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí inú.*

14 Bákan náà, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti aṣọ àtàtà ṣe aṣọ ìdábùú,+ ó sì ṣe iṣẹ́ ọnà kérúbù sí i lára.+

15 Lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó méjì+ síwájú ilé náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùndínlógójì (35), ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+ 16 Ó ṣe àwọn ẹ̀wọ̀n tó dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn, ó sì fi wọ́n sórí àwọn òpó náà, ó ṣe ọgọ́rùn-ún (100) pómégíránétì, ó sì fi wọ́n sára àwọn ẹ̀wọ̀n náà. 17 Ó ṣe àwọn òpó náà síwájú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan sápá ọ̀tún,* èkejì sápá òsì;* ó pe èyí tó wà lápá ọ̀tún ní Jákínì* àti èyí tó wà lápá òsì ní Bóásì.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́