Kí Á Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Ènìyàn Ni Àbí Kí A Máà Gbẹ́kẹ̀ Lé wọn
Ó LÈ jẹ́ ohun tí ó ṣòro láti mọ̀ bóyá kí á gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn ni àbí kí á máà gbẹ́kẹ̀ lé wọn. Ọ̀nà méjèèjì ló ní ewu tirẹ̀, pàápàá jù lọ nínú ayé tí ẹ̀tàn àti ilẹ̀ dídà ti gbalẹ̀ kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo wa ni a nílò àwọn ọ̀rẹ́ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí yóò tì wá lẹ́yìn ní àkókò ìṣòro. (Owe 17:17) Ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Romu kan, Phaedrus, sọ àgbákò náà ní ọ̀nà yìí pé: “Yálà ènìyàn gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn ní o, tàbí ènìyàn kò gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn ni o, kò sí èyí tí kò léwu.”
Gbígbẹ́kẹ̀ lé Ènìyàn Lè Léwu
Kí ni ìdí tí gbígbẹ́kẹ̀ lé ẹlòmíràn fi lè léwu? Ó dára, gbé ìkìlọ̀ tí ìwé ìròyìn Psychology Today fúnni yẹ̀ wò. Ó ṣàpèjúwe àwọn kan tí ń kó ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ènìyàn nífà gẹ́gẹ́ bí “apanirun” tí ń “lo oògùn àti àwọ̀ méjì láti tan àwọn tí ń bẹ ní àyíká wọn jẹ́, láti yí wọn lẹ́kọrọ, kí wọn sì ba ìgbésí ayé wọn jẹ.” Ó ṣe kedere pé, tí irú àwọn atannijẹ bẹ́ẹ̀ bá ń bẹ́ ní àyíká, jíjẹ́ ẹni tí ń gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn lápọ̀jù léwu gbáà.
Ẹnì kan tí ó máa ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ènìyàn lápọ̀jù lè jẹ́ ọ̀dẹ̀, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni tí a lè tètè tàn jẹ, tí á sì yí lẹ́kọrọ. Àpẹẹrẹ ìṣe ọ̀dẹ̀ dídára jù lọ ni Alàgbà Arthur Conan Doyle, ẹni tí ó kọ́kọ́ ṣẹ̀dà àgbà nínú àwọn ìtàn àròsọ ògbójú ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, Sherlock Holmes. Ní ọdún 1917, àwọn ọmọbìnrin méjì, Elsie Wright àti ìbátan rẹ̀, Frances Griffiths, sọ pé àwọn bá àwọn iwin ṣeré nínú ọgbà ilé àwọn ní Cottingley, England. Wọ́n tilẹ̀ fi àwọn fọ́tò àwọn iwin náà hàn láti lè fi kín ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn.
Conan Doyle, tí ó nífẹ̀ẹ́ ọkàn nínú ìbẹ́mìílò lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ìgbà tí ọmọkùnrin rẹ̀ ti kú, fọkàn tán wọn, ó sì gba ìtàn àwọn iwin náà gbọ́—bí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti gbà á gbọ́ ní àkókò yẹn. Àfìgbà tí ó tó nǹkan bí ọdún 55 lẹ́yìn náà kí àwọn ọmọbìnrin náà tó jẹ́wọ́ pé arúmọjẹ ni gbogbo rẹ̀ àti pé, àwọ́n gé “àwọn iwin” náà jáde láti inú ìwé kan ni, kí àwọ́n tóó ya fọ́tò rẹ̀. Frances Griffiths sọ ìyàlẹ́nu rẹ̀ jáde pé a tilẹ̀ rí ẹni tí ó gba ìtàn àwọn gbọ́. Ó sọ pé: “Ohun àràmàǹdà ló ṣì máa ń jẹ́ fún mi nígbà gbogbo pé ẹnì kan lè ya ọ̀dẹ̀ pátápátá gbáà débi tí yóò fi gbà gbọ́ pé iwin tòótọ́ ni àwọn iwin náà.”—Hoaxers and Their Victims.
Ǹjẹ́ o lè rí pańpẹ́ tí Conan Doyle kó sí? Ó fi àìnirònú fọkàn tán ìtàn náà kìkì nítorí pé ó fẹ́ kí ó jẹ́ òtítọ́. Òǹkọ̀wé Norman Moss sọ pé: “Àwọn ènìyàn lè tàn wá jẹ kìkì nítorí pé ìhùwàsí wa ti dojú agbára ìrònú wa dé, a sì máa ń fi àdììdìtán ojú wo àwọn nǹkan. . . . Nígbà míràn, a máa ń gbà pé nǹkan jẹ́ òtítọ́ nítorí pé ó jẹ́ ohun tí a fẹ́ kí ó jẹ́ òtítọ́.” (The Pleasures of Deception) Ìyẹn kín ìkìlọ̀ tí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì, Demosthenes, sọ ní nǹkan bí 350 ọdún ṣaájú Sànmánì Tiwa lẹ́yìn pé: “Ohun tí ó rọrùn láti ṣe jù lọ ni láti tan ara ẹni, nítorí ohun tí ènìyàn bá ń fẹ́ ni ó máa ń gbà gbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́.” Gbígbẹ́kẹ̀ lé kìkì ìmọ̀lára wa lè léwu.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè retí, o lè ronú pé àpẹẹrẹ tí ó lọ ré kọjá ààlà ni èyí, àti pé ìwọ kò lè ya dìndìnrìn tán pátápátá bíi ti Conan Doyle. Ṣùgbọ́n kì í ṣe kìkì àwọn ọ̀dẹ̀ nìkan ni wọ́n wà nínú ewu dídi ẹni tí a tàn jẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra, tí wọ́n sì máa ń ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fara jọ ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ti mú lẹ́gọ̀ tí wọ́n sì ti tàn jẹ.
Kí Ènìyàn Máà Gbẹ́kẹ̀ lé Ẹnì Kankan Lè Léwu
Bí ó ti wù kí ó rí, ewú wà nínú kí ènìyàn máà ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹnì kankan tàbí nínú ohunkóhun. Àìnígbẹkẹ̀lé dà bíi nǹkan tí ń dípẹtà lọ. Ó lè máa gín ìbáṣepọ̀ tí kì bá ti ṣe tímọ́tímọ́, kí ó sì kún fún ayọ̀ jẹ díẹ̀díẹ̀, kí ó sì bà á jẹ́. Ìwà àìgbáraléni lílé kenkà àti ìwà àìnígbẹkẹ̀lé nínú ènìyàn lọ́nà tí ó nípọn lè mú kí o jẹ́ aláìláyọ̀, àti aláìbẹ́nìkanrẹ́. Ó lè ba ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́ débi tí òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Samuel Johnson, fi kọ̀wé pé, “ó máa ń mú ayọ̀ wá fún ẹnì kan nígbà tí àwọn ènìyàn bá ń rẹ́ ẹ jẹ lẹ́ẹ̀kọ̀kan, ju pé kí ó máà gbẹ́kẹ̀ lé ẹnì kankan lọ.”
Àìnígbẹkẹ̀lé nínú ènìyàn lè fi ìlera rẹ sínú ewu. Bóyá o ti fura pé àwọn ìmọ̀lára lílágbára bí ìbínú lè mú kí o wà nínú ewu àrùn ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìwádìí kan fi hàn pé jíjẹ́ ẹni tí kì í gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn lè ṣe ohun kan náà? Ìwé ìròyìn Chatelaine sọ pé: “Kì í ṣe kìkì àwọn ènìyàn tí wọ́n tètè máa ń bínú nìkan ni ó lè mú kí ìṣeéṣe kí wọ́n ní àrùn ọkàn-àyà lọ sókè nítorí ìwà wọn. Ìwádìí tuntun fi hàn pé, ìwà àìbánirẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, irú bí ànímọ́ fífẹ́ láti jẹ́ ẹni tí kì í gbára lé ènìyàn, tí kì í sì gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn, lè fi ọ́ sínú ewu.”
Ronú Nípa Ìgbésẹ̀ Rẹ Tìṣọ́ratìṣọ́ra
Kí ni o lè ṣe? Bibeli fún wa ní àwọn ìmọ̀ran rere lórí ọ̀ràn yìí. Owe 14:15 (NW) sọ pé: “Ẹnì kan tí ó jẹ́ aláìnírìírí ń gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́.” Eléyìí kì í ṣe ìwà àìgbáralé ènìyàn tí ń pani run. Ìránnilétí gidi ni ó jẹ́ fún wa láti ṣọ́ra. Kìkì aláìmọ̀kan, tí kò sí ìrírí ni yóò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó bá gbọ́ láìrònú. Ó dára pé òwe Bibeli yẹn ń bá a lọ pé: “Ṣùgbọ́n ọlọgbọ́n máa ń ronú nípa àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.” Òǹkọ̀wé eré ìtàgé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, William Shakespeare, kọ̀wé pé: “Máà gbẹ́kẹ̀ lé pákó tí ó ti rà.” Òmùgọ̀ gbáà ni ẹnikẹ́ni tí ó ronú pé àwọn pákó afárá tí ó wà lórí ibi tí ó jìn sísàlẹ̀ kan lè ti rà, tí ó sì gbẹ́sẹ̀ lé wọn. Nígbà náà, báwo ni o ṣe lè ‘ronú nípa àwọn ìgbésẹ̀’ rẹ, kí ó má baà gbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lórí asán?
Bibeli fún wa níṣìírí pé, kí a máa dán ohun tí àwọn ènìyàn sọ wò, dípò tí a óò kàn fi gba gbogbo ohun tí a bá gbọ́ láìrònú. Ó sọ pé: “Etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò, bí adùn ẹnu ti í tọ́ oúnjẹ wò.” (Jobu 34:3) Òtítọ́ ha kọ́ ni ìyẹn bí? A kì í ha í tọ́ oúnjẹ wò kí á tó gbé e mì bí? Ó yẹ kí a dán ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn ènìyàn wò kí a tóó tẹ́wọ́ gbà wọn pẹ̀lú. Kò sí ẹni tí ó bá ń sọ òtítọ́ tí yóò bínú tí a bá wádìí ohun tí ó sọ wò. Òwe àwọn ará Scotland kín òtítọ́ náà lẹ́yìn pé ó yẹ kí a wádìí láti rí i dájú pé ohun kan jẹ́ òtítọ́ nípa sísọ pé: “Ẹni tí ó bá tàn mi lẹ́ẹ̀kan, ìtìjú rẹ̀ ni; tí ó bá tàn mí lẹ́ẹ̀mejì, ìtìjú mi ni.”
Aposteli Paulu gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ dán ohun gbogbo wò.” (1 Tessalonika 5:21, Today’s English Version) Ọ̀rọ̀ tí aposteli Paulu lò fún ‘dán wò’ ni a tún lò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú dídán àwọn mẹ́táàlì ṣíṣeyebíye wò láti rí i bí wọ́n bá jẹ́ ojúlówó. Ọlọgbọ́n ènìyàn máa ń dán nǹkan wò nígbà gbogbo láti rí i bí ohun tí òun ń rà bá jẹ́ ojúlówó. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè rà ohun tí wọ́n ń pé ní páńda—ohun kan tí ó dà bíi wúrà, ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé aláìníyelórí ni, ní ti gidi.
Jẹ́ Afòyebánilò àti Awàdéédéé
Ó dájú pé a fẹ́ láti jẹ́ ẹni tí ń fòye bá àwọn ẹlòmíràn lò nínú ọ̀ràn yìí, a kò sì fẹ́ láti jẹ́ ẹni tí ń fura sí àwọn ẹlòmíràn láìnídìí. (Filippi 4:5) Má ṣe yára máa ro nǹkan mìíràn sí ìgbésẹ̀ ẹnikẹ́ni. Ríro nǹkan mìíràn sí ìgbésẹ̀ àwọn ẹlòmíràn lè jẹ́ ọ̀nà tí ó yá jù láti ba ìbáṣepọ̀ tí ó dára, tí ó sì ṣe tímọ́tímọ́ jẹ́. Ó máa ń dára jù pé kí o ní in lọ́kàn pé, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń fẹ́ láti ṣe ohun tí ó dára jù lọ fún ọ, dípò ríro nǹkan tí kò dára sí ìgbésẹ̀ wọn nígbà tí ipò líle koko bá yọjú.
Fi àyè sílẹ̀ fún àìpé àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn. Akọ̀wé Kristin von Kreisler sọ pé: “Ọ̀dàlẹ̀ ọ̀rẹ́ ba ìgbẹ́kẹ̀lé tí a ní nínú rẹ̀ jẹ́.” Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìwà ọ̀dàlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tí kò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe tàbí kí ó jẹ́ nítorí àṣìṣe tí ó ń kábàámọ̀ lé nísinsìnyí. Nítorí náà, ó ń bá a lọ pé: “Má ṣe kó gbogbo ìrònú jọ sórí ìwà ọ̀dàlẹ̀ náà—tàbí kí o jẹ́ kí ó má ṣe mú ọ gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹlòmíràn mọ́.” Má ṣe jẹ́ kí àwọn ìrírí kíkorò, tí kò dára, gba ayọ̀ tí ó lè wá láti inú mímú ìbáṣepọ̀ onígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé dàgbà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.
Jẹ́ ẹni tí ó wà déédéé. O kò ní láti gbé nǹkan sójú nígbà tí o bá fẹ́ gbé àwọn ènìyàn yẹ̀ wò; ẹnì kan tí ó máa ń ṣọ́ra yóò máa wà lójúfò nígbà gbogbo. Ẹ̀wẹ̀, Dokita Redford Williams dámọ̀ràn pé kí á ní in lọ́kàn pé àwọn ẹlòmíràn ń ṣe gbogbo ohun tí ó dára jù lọ tí wọ́n lè ṣe, kí a gbìyànjú láti lóye ojú ìwòye wọn, kí á sì “máa fi gbígbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹlòmíràn dánra wò” nígbàkígbà tí ó bá ṣeé ṣe. Ó lè sàn jù láti gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn lápọ̀jù jù kí ènìyàn má tilẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni lọ.
Ẹni tí ó kọ ìwé Owe inú Bibeli gbà pé, “àwọn alábàákẹ́gbẹ́ kan wà, tí wọ́n máa ń ba ọkàn ara wọn jẹ́”—àwọn ni àwọn tí wọn yóò gbìyànjú láti kó ọ nífà nítorí pé o gbẹ́kẹ̀ lé wọn. Irú wọn pọ̀ yamùrá nínú ayé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fún àwọn ẹlòmíràn ní àkókò àti àǹfààní láti fi hàn pé àwọ́n jẹ́ ẹni tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀, ìwọ yóò sì rí àwọn ọ̀rẹ́ tí yóò ‘rọ̀ mọ́ ọ típẹ́típẹ́ ju arákùnrin lọ.’—Owe 18:24, NW.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹnì kan tàbí ohun kan ha wà tí o lè gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá, láìsí ìbẹ̀rù kankan pé yóò kó ọ nífà nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé e tàbí pé yóò dà ọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ó wà. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò ní ṣókí ibi tí o lè gbé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lé pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ pátápátá.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
“Ẹnì kan tí ó jẹ́ aláìnírìírí ń gba ọ̀rọ̀ gbogbo gbọ́, ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó gbọ́n féfé máa ń ronú nípa àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀.” —Owe 14:15, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Fi àyè sílẹ̀ fún àìpé àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn