“Àwárí Oníyebíye ti Ìmọ̀”
Ọkùnrin kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn THENEWS ní Lagos, Nàìjíríà, kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè yẹn, ó sì fi àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yí ṣàpèjúwe Jí! Ó ṣàlàyé pé:
“Ìgbàkigbà tí mo bá ka ẹ̀dà Jí!, mo máa ń ní ìsúnniṣe láti kọ̀wé sí i yín. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, bí mo bá ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà náà, ẹ̀dà míràn ìwé ìròyìn náà tí òun pẹ̀lú dára, kódà tí ó dára jù, yóò dé, yóò sì tún mú mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
“Kí ni kókó pàtàkì jù lọ nínú gbogbo èyí? Ní èrò tèmi, Jí! jẹ́ àwárí oníyebíye ti ìmọ̀. N kì í fìgbà gbogbo rí ìtẹ̀jáde kan tí ó níye lórí púpọ̀, tí ó lẹ́wà, tí kò pọ̀ síbì kan, tí a sì fòye gbé kalẹ̀ tó o. Ẹ̀bùn tí kò láfiwé kan ló jẹ́ fún aráyé.
“Mo fẹ́ láti sọ èyí látọkàn wá pé: Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀. Ẹ máa bá iṣẹ́ àgbàyanu náà lọ.”
Ó dá wa lójú pé ìwọ pẹ̀lú yóò jàǹfààní nínú kíka Jí! Bí ìwọ yóò bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà míràn gbà tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.