ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/22 ojú ìwé 31
  • Àjọ OSCE—Kí Ló Jẹ́? Yóò Ha Ṣàṣeyọrí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjọ OSCE—Kí Ló Jẹ́? Yóò Ha Ṣàṣeyọrí Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ète Ìlépa Rẹ̀
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Oju-iwoye Bibeli Nipa Alaafia ati Ailewu
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Awọn Ìwéwèé Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede Yoo Ha Kẹ́sẹjárí Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Láti Inú Ipò Òṣì Paraku, Mo Bọ́ Sínú Ọrọ̀ Tó Gadabú Jù Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Jí!—1997
g97 8/22 ojú ìwé 31

Àjọ OSCE—Kí Ló Jẹ́? Yóò Ha Ṣàṣeyọrí Bí?

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní ilẹ̀ Potogí

LẸ́YÌN tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ìjàkadì agbára kan bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè olówò bòńbàtà tí ń ṣe ìjọba tiwa-n-tiwa ní Ìwọ̀ Oòrùn àti àwọn orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ Soviet tí ń ṣe ìjọba Kọ́múníìsì ní Ìlà Oòrùn. Ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ kọ̀ọ̀kan ló ní àjọ ààbò tirẹ̀: Àjọ Àdéhùn Àríwá Àtìláńtíìkì (NATO) ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn àti Àdéhùn Warsaw ní ìhà Ìlà Oòrùn.

Nígbà tí ó fi di ọdún 1975, Ogun Tútù náà ti dẹwọ́ tó fún àwọn Orílẹ̀-Èdè 35, tí ó ní United States àti Rọ́ṣíà nínú, láti fọwọ́ sí ohun tí a wá mọ̀ sí Àdéhùn Helsinki. A dá Ìpàdé Àpérò Lórí Ọ̀ràn Ààbò àti Àjọṣe Ilẹ̀ Europe (CSCE) sílẹ̀. Ó jẹ́ ojúkò alápá púpọ̀ kan fún ìfikùnlukùn àti ìdúnàádúrà láàárín àwọn ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ méjèèjì.

Níbi Àpérò Budapest ní ọdún 1994, àjọ CSCE pa orúkọ rẹ̀ dà sí Àjọ Ààbò àti Àjọṣe Ilẹ̀ Europe (OSCE). Lónìí, ó ní àwọn Orílẹ̀-Èdè 54 tí ń kópa nínú, títí kan United States, Kánádà, àti gbogbo orílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́.

Ète Ìlépa Rẹ̀

Ète ìlépa àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ mẹ́ńbà àjọ OSCE ni láti mú ààbò ilẹ̀ Europe dájú, kí wọ́n sì fún ìṣàmúlò ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìbọ́ra ogun sílẹ̀, òmìnira ìjọba tiwa-n-tiwa àti àbójútó ìforígbárí ẹlẹ́kùnjẹkùn, níṣìírí.

Wọ́n ṣe ìpàdé àpérò àjọ OSCE kan ní Lisbon, ilẹ̀ Potogí, ní December 2 àti 3, 1996. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n darí àfiyèsí sí àjọ NATO, níwọ̀n bí àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà àjọ NATO, tí ó ní United States nínú, ti fara mọ́ ìmúgbòòrò àjọ NATO, kí ó lè kó àwọn orílẹ̀-èdè míràn sí i láti Àárín Gbùngbùn àti Ìlà Oòrùn Europe mọ́ra. Ṣùgbọ́n kàkà kí Rọ́ṣíà àti àwọn alájọṣepọ̀ ìhà Ìlà Oòrùn ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ àtijọ́ mélòó kan ti ìmúgbòòrò àjọ NATO lẹ́yìn, pé kí ó kó àwọn orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ ìhà Ìlà Oòrùn àtijọ́ mọ́ra, wọ́n fẹ́ kí àjọ OSCE di ojúkò àwọn ọ̀ràn ààbò ilẹ̀ Europe.

Níbi ìpàdé náà, olórí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà, Viktor Chernomyrdin, sọ pé: “A fara mọ́ fífún àjọ OSCE tí ó jẹ́ ibì kan ṣoṣo tí gbogbo Orílẹ̀-Èdè ti lè ṣiṣẹ́ pọ̀ ní Europe, lókun. Ó jẹ́ ibi dídára jù lọ fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè láti jíròrò ọ̀ràn ààbò àti ìgbèjà.”

Ó jọ pé oòrùn ọ̀sán gangan tí ń mú hanhan náà pèsè àyíká ìfojúsọ́nà fún rere kan fún gbogbogbòò nígbà ìparí àpérò náà, láìka àwọn ohun tí ilé iṣẹ́ ìròyìn gbé jáde nípa àbájáde rẹ̀ tí kò yanjú kerekete sí. Ohun yòó wù kí ó jẹ́ àṣeyọrí tàbí ìkùnà àjọ OSCE, àwọn olùfẹ́ àlàáfíà níbi gbogbo lè ní ìdánilójú pé àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ yóò dé kárí ayé láìpẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 72:1, 7, 8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbọ̀ngàn Àṣà Ìbílẹ̀ ti Belém, ní Lisbon, ilẹ̀ Potogí, níbi tí wọ́n ti ṣe ìpàdé àpérò náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́