Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 27. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Nígbà tí Jésù ń fi àwọn akọ̀wé àti Farisí bú, ta ni ó sọ pé wọ́n “ṣìkà pa láàárín ibùjọsìn àti pẹpẹ”? (Mátíù 23:35)
2. Ta ni ọmọkùnrin tí Bẹ́ńjámínì kọ́kọ́ bí? (Jẹ́nẹ́sísì 46:21)
3. Àlùfáà wo lọ́nà ti Árọ́nì ni a mọ̀ sí adàwékọ àti olùkọ́ Òfin? (Nehemáyà 8:1, 2)
4. Kí ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ dà lójú aráyé kí ó baà lè di ọlọ́gbọ́n ní tòótọ́? (Kọ́ríńtì Kíní 3:18, 19)
5. Kí ni a ń pe ìhà ibi tí a ń ki ohun ìṣọ̀ṣọ́ sí létí? (Léfítíkù 14:14, NW)
6. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé ó ń jẹ́ ìyọrísí ìfẹ́ owó? (Tímótì Kíní 6:10)
7. Kí ni “òkè orí” kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀run inú ìran Ìsíkẹ́ẹ̀lì jọ? (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 1:22, NW)
8. Kí ni orúkọ ìyawọlẹ̀ omi níbi tí àwọn atukọ̀ ojú omi bẹ̀rù pé ọkọ̀ wọn yóò tàn sí nígbà tí wọ́n ń gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n? (Ìṣe 27:17)
9. Igi wo ni a fi ṣe ọ̀pá Áárónì? (Númérì 17:8)
10. Báwo ni Lọ́ọ̀tì ti ṣe tó láti dáàbò bo àwọn àlejò rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn akọluni? (Jẹ́nẹ́sísì 19:6-8)
11. Orúkọ wo ni Bíbélì pe ìlú ńlá Mémúfísì tí ó wà ní Íjíbítì? (Aísáyà 19:13)
12. Kí ni a ń pe abo ìgalà pupa? (Òwe 5:19, NW)
13. Àwọn kòkòrò wo ni a pè ní “ènìyàn” nítorí ìṣètò àwùjọ wọn dídíjú dé ìwọ̀n kan? (Òwe 30:25)
14. Ta ni ará Kénáánì tí ó jẹ́ bàbá fún ìyàwó Júdà? (Jẹ́nẹ́sísì 38:2)
15. Kí ni a ń pe àdàmọ̀dì ọmọ tí akọ màlúù òun abo ẹṣin bí? (Sámúẹ́lì Kejì 13:29)
16. Ohun wo ni a sọ pé ó jẹ́ “ìríra lójú Olúwa”? (Òwe 12:22)
17. Ọlọ́run èké wo ni wọ́n wí fún Èlíjà pé àwọn 7,000 ènìyàn ní Ísírẹ́lì kò forí balẹ̀ fún? (Àwọn Ọba Kìíní 19:18)
18. Ọ̀rọ̀ wo ni a tú ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà, Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, sí, tí ó fa ìdàrúdàpọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú? (Ìṣe 2:31, King James Version)
19. Ta ló ní èrò tí kò tọ̀nà náà pé Hánà olódodo mutí yó? (Sámúẹ́lì Kíní 1:13)
20. Ta ni Pọ́ọ̀lù pè ní “ẹni tí a fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà nínú Kristi” ní ìjọ Róòmù? (Róòmù 16:10)
21. Àpọ́sítélì wo ni a ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ju èyíkéyìí lára àwọn 11 yòó kù lọ? (Mátíù 15:15)
22. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ tí wọn kò fi nà án lọ́rẹ́? (Ìṣe 22:25-29)
23. Èròjà atasánsán méjì wo ni Nikodémù lò láti múra òkú Jésù sílẹ̀ fún ìsìnkú? (Jòhánù 19:39)
24. Àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mélòó ni Jésù wò sàn ní àkókò tí ó jẹ́ pé ọ̀kan ṣoṣo lára wọn ló pa dà wá láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀? (Lúùkù 17:12-19)
25. Ẹni tí ó ní ìṣòro wo ni Òfin dẹ́bi pípe ibi wa sórí rẹ̀, níwọ̀n bí kò ti lè gbèjà ara rẹ̀? (Léfítíkù 19:14)
Àwọn Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. “Sekaráyà ọmọkùnrin Barakáyà”
2. Bélà
3. Ẹ́sírà
4. Òmùgọ̀
5. Ìsàlẹ̀ etí
6. ‘Àwọn ohun aṣeniléṣe,’ títí kan dídi ẹni tí ‘a mú ṣako lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́’
7. “Ìtànyinrin omi dídì tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀”
8. Sítísì
9. Álímọ́ńdì
10. Ó jọ̀wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ fún wọn
11. Nófì
12. Egbin
13. Èèrà
14. Ṣúà
15. Ìbaaka
16. Ahọ́n èké
17. Báálì
18. Isà òkú
19. Olórí àlùfáà Élì
20. Ápélésì
21. Pétérù
22. Pé òun jẹ́ ará Róòmù
23. Òjíá àti álóì
24. Mẹ́wàá
25. Etí dídi