Àràmàǹdà Àwọn Àtòpọ̀ Òkúta Fún Ète Wo, Nígbà Wo, Àti Báwo?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NETHERLANDS
ÌWỌ lè béèrè pé, ‘Kí ni àtòpọ̀ òkúta?’ Ó jẹ́ ibì kan tí ó ti wà ṣáájú kí a tó ṣàkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, tí wọ́n ti to òkúta gàǹgàgàǹgà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ sóròó, tí wọ́n sì fi òkúta pẹrẹsẹ kan dé orí rẹ̀, tí ó sábà máa ń yọ iyàrá, tí wọ́n máa ń lò bí ibi ìsìnkú. Ní pàtàkì, a máa ń rí wọn ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àríwá, àti gúúsù Yúróòpù.
Ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Dutch náà, Drenthe, àwọn àtòpọ̀ òkúta sábà máa ń wà ní àwọn àgbègbè onílẹ̀ títẹ́jú, tí ó fani mọ́ra. Nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tí olókìkí ayàwòrán náà, Vincent van Gogh, kọ, ó wí pé: ‘Drenthe jojú ní gbèsè gan-an débi pé n kì bá rí i ká ní n kò lè dúró níbí títí láé.’ Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìṣẹ̀dá àti àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn rí gbogbo ohun tí wọ́n lè dàníyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n lọ wo àwọn àtòpọ̀ òkúta tó wà ní Drenthe.
Àmọ́, èé ṣe tí a fi lọ́kàn ìfẹ́ sí àkójọ àwọn òkúta ìgbà láéláé? Ọ̀kan lára ìdáhùn ìbéèrè náà ni ìfẹ́ ìtọpinpin. Èé ṣe tí àwọn ènìyàn ìgbà láéláé fi ń yọ ara wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ láti yí àwọn ohun tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀, tí wọ́n gé wọn sí bí wọ́n ṣe fẹ́, tí wọ́n sì gbé wọn sókè? Àwọn òkúta kan tẹ̀wọ̀n ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù. Wọn kò sì ní àwọn ẹ̀rọ àfigbẹ́rù ìgbàlódé láti fi gbé wọn ní àwọn àkókò yẹn! Nítorí náà, kí ni a lè mọ̀ nípa àwọn àtòpọ̀ òkúta?
Àwọn Ohun Ìrántí Olókùúta Gàǹgàgàǹgà
A ka àkójọ àwọn òkúta sí òkúta ìrántí gàǹgà (“megalith,” láti inú èdè Gíríìkì, túmọ̀ sí “àpáta fífẹ̀”). Bóyá o mọ àwọn àpáta ìrántí ti ilẹ̀ Faransé dáadáa, àwọn tí a ń lo ọ̀rọ̀ ilẹ̀ Brittany kan, tí ó túmọ̀ sí “àpáta gígùn,” fún. Erékùṣù Baleares náà, Minorca, ní àwọn òkúta ìrántí gàǹgàgàǹgà tí a mọ̀ sí àwọn taula (àwọn tábìlì), tí ó ní ìdérí ńlá kan tí wọ́n gbé lé orí òkúta kan tí ó wà lóròó, tí èyí sì di lẹ́tà T ràgàjì kan.
Stonehenge, agbo àwọn òkúta gàǹgàgàǹgà, tí àwọn kan lára wọn tẹ̀wọ̀n tó 50 tọ́ọ̀nù. Nǹkan bí 80 òkúta aláwọ̀ búlúù tí wọ́n fi ṣe òpó tí wọ́n kó wá láti ibi tí ó nasẹ̀ ju 380 kìlómítà lọ láti Òkè Ńlá Preseli ní Wales, ní England, ṣì ń jọ àwọn ènìyàn lójú. Gẹ́gẹ́ bí ìwé National Geographic Society náà, Mysteries of Mankind—Earth’s Unexplained Landmarks, ṣe sọ, “àwọn ọ̀mọ̀wé rò pé ohun ìrántí náà, [Stonehenge], . . . jẹ́ tẹ́ńpìlì kan tí ó lè ti ṣàgbéyọ ìṣíkiri àyípoyípo ayérayé, ti oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀ lójú ọ̀run, àmọ́ tí kò ṣiṣẹ́ fún ète mìíràn.”
Àtòpọ̀ òkúta kan lónìí wulẹ̀ jẹ́ ìgbékalẹ̀ ohun ìrántí ìsìnkú ni, níwọ̀n bí àgbájọ iyanrìn tàbí iyẹ̀pẹ̀ ti bo àwọn àpáta gbígbórín náà mọ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Àwọn àwárí ti fi hàn pé àwọn àtòpọ̀ òkúta náà jẹ́ sàréè ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn kan. Àwọn ẹ̀rí kan fi hàn pé ó lé ní ọgọ́rùn-ún ènìyàn tí wọ́n sin sínú àwọn àtòpọ̀ òkúta pàtó kan—itẹ́ òkú náà ló já sí!
Ní Netherlands, àwọn àtòpọ̀ òkúta 53 ni wọ́n ti pa mọ́ di ìsinsìnyí; 52 lára wọ́n wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Drenthe. Lọ́nà gbígbàfiyèsí, wọn kò tò wọ́n wúruwùru, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni wọ́n tò dáradára láti ìlà oòrùn kan ìwọ̀ oòrùn, ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù, tí ó ṣeé ṣe kí ó ní nǹkan láti ṣe pẹ̀lú àwọn ipò tí oòrùn ń wà láti ìgbà kan sí òmíràn. Àwọn kọ́lékọ́lé ìgbà láéláé lo àwọn àpáta nínàró tí ó gbé àwọn mìíràn ró àti àwọn òkúta ìdérí ńláńlá, wọ́n sì fi àwọn òkúta kéékèèké dí àwọn àlàfo rẹ̀. Wọ́n da òkúta sí ilẹ̀ ibẹ̀. Àtòpọ̀ àwọn òkúta tí ó tóbi jù lọ ní Netherlands, nítòsí abúlé Borger, gùn ní mítà 22, ó ṣì ní àpáta 47 síbẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn òkúta ìdérí tí ó ní gùn ní nǹkan bí mítà mẹ́ta, ó sì wọn 20 tọ́ọ̀nù! Gbogbo èyí ń gbé àwọn ìbéèrè bí mélòó kan dìde.
Ìgbà Wo Ni Wọ́n Tò Wọ́n Pọ̀? Ta Ní Tò Wọ́n, Báwo, àti fún Ète Wo?
Àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn kò ní ìdáhùn pàtó nítorí pé kò sí ìtàn tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ láti Yúróòpù ayé ìgbà yẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó bá a mu láti tọ́ka sí àwọn àtòpọ̀ òkúta bí ohun ìrántí àràmàǹdà. Kí wá ni a mọ̀ nípa wọn? Ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀, kí ni àwọn ènìyàn sọ?
Ní ọdún 1660, “Ẹni Ọ̀wọ̀” Picardt, láti ìlú kékeré Coevorden, ní Drenthe, ó sọ pé, àwọn òmìrán ló tò wọ́n pọ̀. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn aláṣẹ àdúgbò fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú àwọn sàréè wọ̀nyí. Nítorí pé àwọn ènìyàn ń lo àwọn òkúta náà láti fi rọ àwọn ògiri ìsédò, tí wọ́n sì ń fi wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì àti ibùgbé, Ẹ̀ka Àbójútó Ọ̀ràn Ìrísí Ojú Ilẹ̀ ní Drenthe gbé òfin kan kalẹ̀ ní July 21, 1734, tí ń dáàbò bo àwọn àtòpọ̀ òkúta náà.
Ọdún 1912 ni àwọn ògbógi ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàyẹ̀wò fínnífínní nípa àwọn àtòpọ̀ òkúta bí mélòó kan. Wọ́n rí àwọn àfọ́kù apẹ (àpáàdì) àwọn ohun èlò (àwọn ẹ̀rú àáké olókùúta líle, àwọn ẹ̀rú ọfà), àti àwọn ohun ọ̀ṣọ́ bí ìlẹ̀kẹ̀ amber nínú àwọn àtòpọ̀ òkúta ṣùgbọ́n ìwọ̀nba egungun òkú díẹ̀ ni wọ́n rí, níwọ̀n bí ìwọ̀nyí kò ti pa mọ́ dáradára nínú ilẹ̀ oníyanrìn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń rí àwọn apẹ tí ó pọ̀ tó 600. Ká sọ pé abọ́ oúnjẹ méjì tàbí mẹ́ta ni wọ́n gbé fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òkú náà, ó ní láti jẹ́ pé àwọn tí wọ́n sin sínú àwọn sàréè kan pọ̀ díẹ̀.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwọn òkúta tí kò nílé, tí àwọn ìṣàn òkìtì yìnyín gbé wá láti Scandinavia, láàárín àwọn sànmánì olómidídì ní ìgbà láéláé, ni a tò pọ̀ di àwọn àtòpọ̀ òkúta. Wọ́n fi ìtẹnumọ́ kéde pé àwọn tó tò wọ́n pọ̀ ni àwọn àgbẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ àwùjọ tí a pè ní àwùjọ “Ife Onírìísí Àrọ,” tí a pè lórúkọ yẹn nítorí àwọn ife onírìísí àrọ tí wọ́n rí.
Àbá èrò orí kan nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà tò wọ́n pọ̀ sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n to àwọn àpáta wíwúwo náà sórí ọmọlanke onípákó, kí wọ́n sì máa fi okùn aláwọ fà á. Láti lè gbé àwọn ìdérí òkúta náà sókè, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n da iyanrìn àti amọ̀ jọ.” Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ bí wọ́n ti ṣe èyí dájú. Kí ló dé tí wọn kò wulẹ̀ sin àwọn òkú bí a ṣe ń sin òkú? Èrò wo ni àwọn tí wọ́n tò wọ́n pọ̀ ní nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú? Èé ṣe tí wọ́n fi àwọn oríṣiríṣi nǹkan sílẹ̀ nínú àwọn sàréè náà? Ńṣe ni àwọn olùwádìí wulẹ̀ lè méfò ìdáhùn. Nítorí pé ó ti pẹ́ gan-an tí wọ́n ti to àwọn àtòpọ̀ òkúta náà pọ̀, kò rọrùn láti sọ ìgbà tí ó jẹ́ pàtó, ẹni tí ó ṣe é, ìdí tí ó fi ṣe é, àti bí ó ṣe ṣe é.
Nígbà tí a bá jí àwọn òkú dìde ní àkókò tí Ọlọ́run yàn, ó ṣeé ṣe kí àwọn tí wọn yóò padà wá lè dáhùn díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. (Jòhánù 5:28; Ìṣe 24:15) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn tí wọ́n to àwọn òkúta náà pọ̀ lè wá sọ ìgbà tí àwọn gbé ayé, ẹni tí wọ́n jẹ́, ìdí tí wọ́n ṣe to àwọn ohun ìrántí wọn kíkàmàmà, àti bí wọ́n ṣe ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
“Taula” kan ní Minorca, Sípéènì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àtòpọ̀ òkúta nítòsí Havelte, Netherlands
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Stonehenge, Britain
Nísàlẹ̀: Àwọn Àtòpọ̀ Òkúta Ràgàjìràgàjì nítòsí Borger, Netherlands
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àtòpọ̀ òkúta tí a tún ṣe nítòsí abúlé Schoonoord, Netherlands, tí a ti rí òkìtì àfamọ̀ṣe àti òkúta tí ó yọ síta
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Sàréè gígùn ní Emmen (Schimmeres), Netherlands