ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/8 ojú ìwé 22-24
  • Híhun Súẹ́tà—Ní Patagonia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Híhun Súẹ́tà—Ní Patagonia
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣe Súẹ́tà Lọ́nà Ti Ayé Àtijọ́
  • Híhun Oríṣiríṣi
  • Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe É Lóde Òní
  • Ṣe O Fẹ́ Ra Súẹ́tà Kan?
  • Àlàyé Nípa Oríṣiríṣi Àwọ̀ àti Aṣọ Láyé Ìgbà Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kúbùsù Òtútù
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 5/8 ojú ìwé 22-24

Híhun Súẹ́tà—Ní Patagonia

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AJẸNTÍNÀ

“ÒTÚTÙ ń mú mi!” Ta ni kò tíì sọ ọ̀rọ̀ yẹn rí ní àwọn àgbègbè tí ipò ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì? Ohun tí ó sì ti lè jẹ́ ìhùwàpadà wa ni pé, ‘Súẹ́tà mi dà?’ lẹ́yìn náà.

Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń wọ súẹ́tà, o ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí wọ́n ṣe ṣe é? Báwo ni wọ́n ṣe ran òwú rẹ̀? Báwo ni wọ́n ṣe gbé àwọn àwọ̀ rẹ̀ jáde? Níbí ní Ajẹntínà, a ní àwọn Àmẹ́ríńdíà ọmọ onílẹ̀ tí wọ́n ń fi ọwọ́ ṣe gbogbo èyí. Ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ wọn, kí a sì rí bí wọ́n ṣe ń ṣe é.

Ṣíṣe Súẹ́tà Lọ́nà Ti Ayé Àtijọ́

Àwọn mélòó kan nínú àwọn Mapuche, ẹ̀yà Àmẹ́ríńdíà kan lára àwọn ènìyàn Araucania, ń gbé ìhà gúúsù Patagonia, ní Ajẹntínà. Wọ́n ń lo ọ̀nà ti àbáláyé tí wọ́n ń gbà rànwú, tí wọ́n sì ń gbà kùn ún. Ní ìgbà ìrúwé ní ìhà Gúúsù Ìlàjì Ayé, tí oṣù November bá ń parí lọ, tí oṣù December sì ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ni wọ́n máa ń rẹ́ irun ara àgùntàn, wọ́n máa ń lo àlùmọ́gàjí onírin-lílẹ̀ tí wọ́n ṣe fún ète yẹn. Rírẹ́ irun àgùntàn jẹ́ iṣẹ́ ọnà kan tí ó yẹ kí ènìyàn rí!

Ó ṣe kedere pé òwú tí ń bọ́ lára àgùntàn máa ń ní koríko, ewéko, àti iyẹ̀pẹ̀ lọ̀kọ̀tì lára. Nítorí náà, a ní láti fọ̀ ọ́ dáradára. A ń ṣe èyí nípa rírì í bọnú omi gbígbóná, kí a wá yọ ọ́ jáde kí ó lè gbẹ. Lẹ́yìn náà ni a óò yọ àwọn àbààwọ́n yòókù. A mọ èyí sí escardado, tàbí gbígbọ̀n. Bí wọ́n bá ṣe èyí dáradára, irun náà yóò mọ́, yóò gbẹ, yóò sì rọ̀ dáadáa. Èyí túmọ̀ sí pé irun àgùntàn náà ti tó láti sọ di òwú ìhunṣọ, tàbí fọ́nrán òwú.

Ọ̀nà àbáláyé méjì ló wà tí wọ́n ń gbà ṣe fọ́nrán òwú. Nínú ọ̀kan, wọ́n máa ń lo ọ̀pá olórí kékeré kan. (Wo fọ́tò 1.) Ẹni tí ń rànwú náà yóò sọ òwú náà di fọ́nrán òwú nípa wíwé e mọ́ ọ̀pá olórí kékeré náà bí ó ti ń fi ọwọ́ kan ra òwú náà mọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó sì ń lọ́ ọ. Fọ́nrán òwú náà yóò wá pọ̀ lára igi olórí kékeré náà. Ìwọ̀n òwú tí wọ́n wé mọ́ igi olórí kékeré náà ló ń pinnu bí fọ́nrán òwú náà yóò ṣe nípọn tó.

Nínú ọ̀nà kejì tí a ń gbà ṣe fọ́nrán òwú, àgbá kan tí a fi ń rànwú ni a ń lò, èyí tí arànwú náà ń fi ìgbẹ́sẹ̀lé kan darí. Wọ́n óò gba ojú ihò kan kó òwú sínú àgbá náà, arànwú náà yóò sì máa pinnu bí fọ́nrán òwú náà yóò ṣe nípọn tó. (Wo fọ́tò 2.) Gbàrà tí fọ́nrán òwú náà bá ti di òun, a lè wá dì í rìbìtì bí ìdì owú tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin ń rà. Àmọ́ ti kíkun òwú náà sí àwọ̀ oríṣiríṣi ńkọ́? Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ìyẹn?

Nípa fífi omi tí ó ní iyọ̀ díẹ̀ se irú àwọn gbòǹgbò tàbí irúgbìn kan fún nǹkan bí 30 ìṣẹ́jú ni àwọn Mapuche fi ń rí àwọn àwọ̀ mú jáde. Èyí bá ọ̀nà tí àwọn kan lára àwọn ẹ̀yà Navajo ti Àmẹ́ríńdíà ní Arizona, U.S.A., ń gbà ṣe àwọ̀ àwọn kúbùsù tí wọ́n ń hun dọ́gba. Ní Ajẹntínà, láti ṣe gbòǹgbò àwọ̀ ìyeyè, àwọn Mapuche máa ń se gbòǹgbò ewéko michai, orúkọ tí àwọn Àmẹ́ríńdíà ń pe irúgbìn Berberis darwinii; láti lè rí àwọ̀ ilẹ̀ tí ó ní àwọ̀ fúnfun tóótòòtó lára mú jáde, wọ́n ń lo ewéko radal, tàbí awùsá ẹgàn; láti rí àwọ̀ pupa, wọ́n ń lo irúgbìn beet. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é yìí ń gba agbára, àwọn àwọ̀ náà kò lè tètè ṣá. Wàyí o, níwọ̀n bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fọ́nrán òwú náà ti ní àwọ̀ tirẹ̀, a lè bẹ̀rẹ̀ híhun súẹ́tà náà.

Híhun Oríṣiríṣi

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni àwọn obìnrin ti máa ń fi abẹ́rẹ́ hun fọ́nrán òwú tí wọ́n ń sọ di aṣọ pẹlẹbẹ tí a lè gán pọ̀ fi ṣe ẹ̀wù. Wọ́n lè lo abẹ́rẹ́ mẹ́rin láti hun ìbọ̀sẹ̀, apá ẹ̀wù, àti aṣọ tí ó dà bí àpò. Ìwé kan sọ pé, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Arébíà ni aṣọ híhun ti bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 200 Sànmánì Tiwa. Òye iṣẹ́ yìí wá tàn dé Yúróòpù, àwọn ará Sípéènì sì mú iṣẹ́ aṣọ híhun wọ Gúúsù àti Àáríngbùngbùn Amẹ́ríkà ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mẹ̀kúnnù kan ní àgbègbè náà lè ti máa ṣe iṣẹ́ ọnà náà tẹ́lẹ̀ rí.

Ọ̀rẹ́ wa tí ń hunṣọ wá béèrè pé, “Báwo lẹ ṣe fẹ́ kí súẹ́tà náà rí?” Ohun tí a bá sọ ni yóò pinnu bí àwọn abẹ́rẹ́ tí yóò lò yóò ṣe fẹ̀ tó àti bí òwú tí yóò lò yóò ṣe nípọn tó. Lẹ́yìn náà, “Àwọ̀ wo ni ẹ fẹ́?” Bí a bá pinnu ìyẹn, ó lè wá bẹ̀rẹ̀ híhun ún.

Ohun tí ń ya ẹni tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa aṣọ híhun lẹ́nu ni pé a lè pín ọgbọ́n ọnà aṣọ híhun sí ọ̀nà méjì pàtó—híhun, tàbí bọrọgidi, bí àwọn kan ṣe ń pè é, àti ọlọ́nà. Ọlọ́nà jẹ́ irú híhun bọrọgidi tí a dorí rẹ̀ kodò, ó sì ń rí bí ìgbátí lára rẹ̀. Tí a bá kan oríṣi híhun méjì yìí pọ̀, a lè ṣe bátànì oríṣiríṣi.

Ahunṣọ wa hun súẹ́tà náà láwẹ́láwẹ́, lẹ́yìn náà ló gán wọn pọ̀—iwájú, ẹ̀yìn, àwọn apá, àti ọrùn—di odindi. Dájúdájú, ó ń gba ọ̀pọ̀ wákàtí, ọ̀pọ̀ ọjọ́ pàápàá, láti ṣe ẹ̀wù náà. Nítorí náà, bí wọ́n bá fi ọ̀kan ta ọ́ lọ́rẹ, má ṣe fojú tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀! Wọ́n lo ọ̀pọ̀ sùúrù lórí rẹ̀.

Bí Wọ́n Ṣe Ń Ṣe É Lóde Òní

Láti ìgbà ìyípadà sí sànmánì iṣẹ́ ẹ̀rọ, a ti ṣàwárí àwọn ẹ̀rọ tí ó lè hun ẹgbẹẹgbẹ̀rún súẹ́tà láàárín àkókò tí kò tó nǹkan. Lónìí, kọ̀ǹpútà ló sábà ń darí àwọn ẹ̀rọ tí ń hun aṣọ wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀ obìnrin ń lo àwọn ẹ̀rọ tí ó kéré díẹ̀ ní ilé, èyí kì í sì gba àkókò púpọ̀.

Ní Patagonia, híhun aṣọ ṣì jẹ́ ohun tí a ń ṣe nínú ìdílé níbi tí ìyá ti ń hun aṣọ, tí ọkọ àti àwọn ọmọ sì ń ṣèrànwọ́ láti parí èyí tí a ti ṣe yanjú. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń lo ẹ̀rọ ìhunṣọ tí a ń lò nínú ilé, wọn óò sì wá ta àṣẹ́kù ohun tí wọ́n ṣe fún ilé iṣẹ́ kan tí ń ṣe aṣọ híhun. Èyí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwéwèé ìnáwó ìdílé.

Ṣe O Fẹ́ Ra Súẹ́tà Kan?

Kí ni o gbọ́dọ̀ gbé yẹ̀ wò bí o bá fẹ́ ra súẹ́tà? Bí o bá fẹ́ súẹ́tà tí wọ́n fi ọwọ́ hun, ó ṣeé ṣe kí iye tí o máa fi rà á pọ̀, nítorí náà, ó lè jẹ́ èyí tí ó dára gan-an ni ìwọ yóò rí rà níye náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o nílò, fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yan súẹ́tà rẹ, kí o sì yẹ bí ó ṣe jẹ́ ojúlówó sí wò. Báwo ni o ṣe lè ṣe ìyẹn? Yẹ bí àwọn ibi tí wọ́n rán pọ̀ lára ẹ̀wù náà ti ṣe mọ́ra dáadáa tó àti bí ọrùn rẹ̀ bá bá ọ mu wò. Wo bí fọ́nrán òwú náà ṣe rí lọ́wọ́ àti ohun tí wọ́n fi ṣe é. Ògédé òwú ha ni bí? Àdàlù ha ni bí? Bí a bá fà á, ó ha máa ń tètè nà láìpadà sípò mọ́, tàbí ó ha máa ń padà sí bí wọ́n ṣe ṣe é bí? Tí o bá ti rà á, gbogbo ìgbà tí o bá wọ súẹ́tà rẹ, máa ronú nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lórí rẹ̀, ní pàtàkì bí ó bá jẹ́ pé ọwọ́ ni wọ́n fi hun ún ní Patagonia!

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 22]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

GÚÚSÙ AMẸ́RÍKÀ

AJẸNTÍNÀ

Patagonia

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

1. Lílo ọ̀pá olórí kékeré láti ṣe fọ́nrán òwú

2. Àgbá ìrànwú ni ọ̀nà yíyájùlọ láti fi ṣe fọ́nrán òwú

3. Àyẹ̀wò àwọn òwú tí a kó sínú àgbá ìrànwú

4. Híhun ún lọ́nà àbáláyé

5. Iwájú súẹ́tà

6. Ẹ̀rọ ìhunṣọ ìgbàlódé tí kọ̀ǹpútà ń darí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́