ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 12/8 ojú ìwé 29-30
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Omi
  • Ìkìlọ̀ Nípa Ife Ìmukọfí ní Ọ́fíìsì
  • Àwọn Ọmọdé Fẹ́ Ìgbádùn Pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́
  • Ewu Tí Ìbàyíkájẹ́ Ń Fi Wu Àwọn Awakọ̀
  • Ohun Amáyédẹrùn fún Àwọn Màlúù
  • Ipa Tí Tẹlifíṣọ̀n Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọdé Ilẹ̀ Sípéènì
  • Ìtàn Ìwáṣẹ̀ Ilẹ̀ China Sún Sẹ́yìn Sí I
  • Àwọn Òórùn Yíyanilẹ́nu
  • Oòrùn Ń Ba Ara Jẹ́ Níbòòji
  • Ìwàásù Àkànṣe Lórílẹ̀-èdè Bulgaria Kẹ́sẹ Járí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
    Jí!—2001
Jí!—1998
g98 12/8 ojú ìwé 29-30

Wíwo Ayé

Ìṣòro Omi

Ìwé ìròyìn èdè Faransé náà, L’Express sọ pé: “Bí a kò bá wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn omi, ìdá méjì nínú mẹ́ta lára ìran ènìyàn ni àìsí omi yóò máa pọ́n lójú kí ó tó di ọdún 2025.” Ìwé ìròyìn Le Figaro sọ pé: “Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, ìdá mẹ́rin olùgbé ayé ni kì í rí omi mímu pọn.” Láti yanjú ìṣòro omi yìí, Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì, àti Àṣà Ìbílẹ̀ Lábẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe ìpàdé àgbáyé kan ní Paris, ní March 1998. Àwọn aṣojú tí iye wọ́n lé ní igba tó wá síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, títí kan ààrẹ ilẹ̀ Faransé, jíròrò àwọn ọ̀nà tí a lè gbà rí i dájú pé ìpèsè omi kò dín kù lágbàáyé. Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro pàtàkì tí wọ́n jíròrò ni pé a sábà máa ń fi omi ṣòfò nítorí àìsí ọ̀nà ìbomirinko tó dára tó àti àwọn páìpù omi tí ń jò. Ààrẹ ilẹ̀ Faransé, Jacques Chirac, tẹnu mọ́ ọn pé, omi jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ohun tí ẹ̀dá jogún, nítorí náà, a ní láti bójú tó ìlò rẹ̀ jákèjádò ayé.

Ìkìlọ̀ Nípa Ife Ìmukọfí ní Ọ́fíìsì

Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Àwọn adárútúrútú tíntìntín—tí àwọn bakitéríà bíbanilẹ́rù bí E. coli wà lára wọn—ti ń pọ̀ sí i nítorí pé àwọn ènìyàn kì í fara balẹ̀ fọ àwọn ife wọn tàbí kí wọ́n fi omiyòrò apakòkòrò fọ ibi ìfọ-nǹkan àti ibi ìgbọ́únjẹ wọn ní ọ̀pọ̀ jù lọ ọ́fíìsì.” Àwọn olùwádìí náà, Charles Gerba àti Ralph Meer, ṣàyẹ̀wò àwọn ife ìmukọfí àti àwọn ohun tí a fi ń ṣe kọfí ní ọ́fíìsì méjìlá. Nǹkan bí ìpín ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ife àti ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn kànǹkàn tí a rí ní ibi ìfọ-nǹkan ní àwọn ọ́fíìsì náà ló ní bakitéríà coliform, àti lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bakitéríà E. coli tó lè ṣe jàǹbá. Gerba sọ pé: “Èyí sábà máa ń jẹ́ àmì pé wọn kò ṣe ìmọ́tótó.” Ìròyìn náà parí ọ̀rọ̀ sí pé: “A gbọ́dọ̀ máa fi omi gbígbóná, tó ní ọṣẹ nínú fọ àwọn ife ìmukọfí, kí a wá fi omiyòrò apakòkòrò fọ̀ ọ́, àyàfi tí a ba lo ẹ̀rọ ìfabọ́. A gbọ́dọ̀ máa fọ àwọn aṣọ ìnuǹkan àti kànǹkàn déédéé.”

Àwọn Ọmọdé Fẹ́ Ìgbádùn Pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́

Báwo ni o ṣe lè jẹ́ ìyá rere lójú àwọn ọmọ rẹ? Níbi ìwádìí kan tí Àjọ Whirlpool ṣe láàárín ẹgbẹ̀rún ọmọdé ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́fà sí ọdún mẹ́tàdínlógún, ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn fẹ́ràn ṣíṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, lójoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ìyá wọn, ní pàtàkì, “wíwulẹ̀ wà pa pọ̀.” Ohun tí àwọn ọmọdé náà fẹ́ràn jù láti máa ṣe pẹ̀lú Mọ́mì ni “jíjẹun pọ̀.” Ohun kejì ni “jíjọ jáde lọ jẹun” àti “jíjọ lọ rajà.” Èyí tó ṣìkẹta ni “jíjọ jókòó sọ̀rọ̀.” Ọ̀nà tí àwọn ọmọdé náà fẹ́ràn jù lọ láti máa gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ìyá wọn rọrùn pẹ̀lú. Ìpín àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn sọ pé, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn sábà máa ń “dì mọ́” ìyá àwọn, “àwọn óò sì fẹnu kò ó lẹ́nu.” Ọ̀nà tí wọ́n tún yàn láàyò tẹ̀ lé ìyẹn ni wíwí pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ yín” àti “Ẹ ṣeun.”

Ewu Tí Ìbàyíkájẹ́ Ń Fi Wu Àwọn Awakọ̀

Ìwé ìròyìn The Times ti London sọ pé: “Bí awakọ̀ kan bá kó sínú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀, èéfín abàyíkájẹ́ tí yóò fà símú yóò tó ìlọ́po mẹ́ta ti ẹni tí ń gun kẹ̀kẹ́ tàbí ẹni tí ń fẹsẹ̀ rìn àti nǹkan bí ìlọ́po méjì ti èrò ọkọ̀.” Ìwádìí kan tí Àjọ Elétò Àyíká ní Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe fi hàn pé àwọn awakọ̀ tí wọ́n kó sáàárín sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ láàárín òpópónà ń fa “ọ̀pọ̀ èéfín tí ó ní èròjà onímájèlé” sínú. Alágbàwí ọ̀ràn àyíká Andrew Davis sọ pé, ní ìlòdì sí bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti rò, àwọn awakọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lè nílò agọ̀ ìdáàbòboni gan-an ju àwọn tí ń gun kẹ̀kẹ́ ní etí títì lọ.

Ohun Amáyédẹrùn fún Àwọn Màlúù

Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti Kánádà sọ pé, àwọn tìmùtìmù tí a kó rọ́bà inú táyà tí a gé wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú wọn tí ń dé àwọn abà tí a ti ń fún wàrà màlúù. Wọ́n ronú pé àwọn tìmùtìmù tí ó ki ní sẹ̀ǹtímítà márùn-ún náà yóò lè jẹ́ kí àwọn màlúù náà pẹ́ láyé láti máa pèsè wàrà púpọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti sọ, “àwọn màlúù tí a ń fún wàrà wọn máa ń lo èyí tó pọ̀ jù láyé wọn lórí kọnkéré,” èyí tí ń jẹ́ kí wọ́n “dégbò lẹ́sẹ̀, kí ẹsẹ̀ wọn sì bàjẹ́.” Yàtọ̀ sí pé àwọn tìmùtìmù náà ń dín ìṣòro ẹsẹ̀ tí àwọn ẹran náà ń ní kù, ó tún ń jẹ́ kí tìmùtìmù dín ìrora kù bí orúnkún wọn ṣe ń lulẹ̀ kòbàtà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ sinmi. Ẹnì kan tí ń ṣe tìmùtìmù náà sọ pé, ìgbésẹ̀ náà jẹ́ láti jẹ́ kí àwọn màlúù náà ní irú ìmọ̀lára kan náà tí wọn óò ní bí wọ́n bá sùn sínú pápá.

Ipa Tí Tẹlifíṣọ̀n Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọdé Ilẹ̀ Sípéènì

Àjọ Akọ̀ròyìn Europa ròyìn pé, Carlos María Bru, láti Ìgbìmọ̀ Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ní ilẹ̀ Sípéènì, sọ pé, nígbà tí ọmọdé kan tí a lè mú bí àpẹẹrẹ ní ilẹ̀ Sípéènì, tí ń wo tẹlifíṣọ̀n déédéé bá fi máa di ọmọ ọdún mẹ́wàá, ó lè ti rí ẹgbàárùn-ún [10,000] ìpànìyàn àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) ìwà ìfínràn. Láfikún sí i, Ọ̀jọ̀gbọ́n Luis Miguel Martínez sọ pé, ó lé ní ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ọmọdé ilẹ̀ Sípéènì, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin sí méjìlá, tí ń fi nǹkan bí wákàtí méjì ààbọ̀ wo tẹlifíṣọ̀n lójúmọ́, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá mẹ́rin wọn tí ń fi ohun tí ó lé ní wákàtí mẹ́rin wo tẹlifíṣọ̀n lójúmọ́. Ìròyìn náà sọ pé, ní ìpíndọ́gba, “àwọn ọmọdé ń fi òjìlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún dín mẹ́ta [937] wákàtí wo tẹlifíṣọ̀n lọ́dún, ìyẹn ni pé, wọ́n ń lò ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún wákàtí tí wọ́n ń lò ní ilé ẹ̀kọ́ lọ́dọọdún lọ.” Bí Ricardo Pérez-Aznar, láti Ẹ̀ka Ìṣọfúnni Sáyẹ́ǹsì ti Yunifásítì Complutensian, ṣe wí, ìwà ipa orí tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ọ̀kan lára àpapọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láwùjọ ẹ̀dá tó lè dá kún ìwà ipá tí ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ.

Ìtàn Ìwáṣẹ̀ Ilẹ̀ China Sún Sẹ́yìn Sí I

Tipẹ́tipẹ́ ni a ti ń rò pé ọdún tí ó pẹ́ jù lọ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú ìtàn àwọn ará China ni ọdún 841 ṣááju Sànmánì Tiwa, ọdún àkọ́kọ́ nínú ìṣàkóso Gong He ti àwọn aláṣẹ Zhou Ìwọ̀ Oòrùn. Àmọ́, ìwé ìròyìn China Today sọ pé, láìpẹ́ yìí ni wọ́n ṣàwárí àkọsílẹ̀ tí ó pẹ́ ju ìyẹn lọ tí ó sọ nípa ìmúṣókùnkùn oòrùn nínú. Àkọsílẹ̀ náà so ìmúṣókùnkùn oòrùn yìí mọ́ ọdún àkọ́kọ́ Ọba Yi ti àwọn aláṣẹ Zhou. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn òpìtàn ti sọ pé ìmúṣókùnkùn oòrùn yìí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 899 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ohun tí ó lé ní ìdajì ọ̀rúndún sún ìtàn ìwáṣẹ̀ ilẹ̀ China tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sẹ́yìn sí i. Ìwé Outline of the History of the Chinese People sọ pé: “Ohunkóhun kò tí ì ta ko ìṣọ̀kan àkọsílẹ̀ yìí títí wá dé ọ̀rúndún ogún.” Ó pe àkọsílẹ̀ yìí ní “ọ̀kan lára ìtìlẹ́yìn tí àwọn ará China ṣe nínú ìtàn ọ̀làjú gbogbo ìran ènìyàn.”

Àwọn Òórùn Yíyanilẹ́nu

Ó ti pẹ́ tí àwọn tí ń ṣe ọtí wáìnì ti mọ ìjẹ́pàtàkì òórùn nínú mímọ́ ìyàtọ̀ tó wà láàárín wáìnì kan sí òmíràn. Nísinsìnyí, pẹ̀lú góńgó ṣíṣe àwọn ọtí wáìnì tó tún dára jù, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń pín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kẹ́míkà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó lè fi kún òórùn aláìlẹ́gbẹ́ tí ọtí wáìnì ní sí ìsọ̀rí. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń gba ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn tí imú wọn ń gbóòórùn dáadáa. Ìgbìmọ̀ àwọn agbóòórùn-nǹkan ti fi òórùn àwọn èròjà wáìnì kan wé ti àlùbọ́sà, oyin, lílì, tábà, ṣokoléètì, àti ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ. “Ìbọ̀sẹ̀ bíbu, ẹyin bíbàjẹ́ àti rọ́bà sísun” wà lára àwọn ohun yíyanilẹ́nu mìíràn tí wọ́n fi òórùn wọn wé ọtí. Ìwúkàrà kan tí a ń lò nínú ọtí wáìnì ní òórùn kan tí a lè fi wé onírúurú nǹkan. Olùṣèwádìí Jane Robichaud sọ pé: “Ó sinmi lé bí òórùn náà bá ṣe rùn sí ẹnì kan, ní ti bóyá ó ń fi kún òórùn dídùn wáìnì náà tàbí ó ń rùn òórùn arínilára bí kúbùsù ìbora ẹṣin.”

Oòrùn Ń Ba Ara Jẹ́ Níbòòji

Ìwádìí kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwádìí Ìṣègùn Queensland ti Ọsirélíà ṣe sọ pé, ó lè ṣẹlẹ̀ pé wíwá ibòòji lábẹ́ igi tàbí agbòòrùn kan tí a gà sí etíkun kò ní dáàbò boni pátápátá lọ́wọ́ ìtànṣán ultraviolet. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ròyìn rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn The Canberra Times, ẹnì kan tí ó wà ní ibòòji tí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ṣí sílẹ̀ ṣì ń fara gba ìtànṣán ultraviolet tí ó wà láyìíká. Ọ̀mọ̀wé Peter Parsons, onímọ̀ nípa ìṣesí èròjà oníkẹ́míkà, tí ó tún kópa nínú ìwádìí náà, kìlọ̀ pé: “Bí ó bá jẹ́ ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí méjìlá ni àkókò tí ó pọ̀ jù lọ tí a dámọ̀ràn láti fi ṣíra payá ní tààràtà sí oòrùn ọ̀sán gangan ní gbogbo orí ilẹ̀ àwọn olú ìlú Ọsirélíà, nígbà náà, ìpele ìjóni [ìtànṣán ultraviolet B] tí ń mú kí oòrùn bani lára jẹ́ láàárín àkókò tí kò pé wákàtí kan, yóò ba àwọn tí wọ́n dúró tàbí tí wọ́n dùbúlẹ̀ sí ibòòji lára jẹ́.” Kódà, ìtànṣán ultraviolet máa ń pọ̀ gan-an nígbà òtútù àti ní àwọn ọjọ́ tí ojú ọjọ́ ṣókùnkùn pàápàá. Ọ̀mọ̀wé Parsons sọ pé lákòótán, “bí ojú ọjọ́ bá ti ṣe kedere tó ni ewu náà ṣe ń pọ̀ tó.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́